Nollywood: Bàbá Sàlá, Ọmọgé Campus, Ajimajasan àtàwọn òṣèré mí ì jáde láyé ní 2018

Bi o ṣe jẹ pe ilakak lati dun ara ilu ninu lawọn oṣere sinima n le, ọdun 2018 mu ọpọ awọn eekan kan lọ ni lagbo naa lọdun 2018.
Bi o tilẹ pe awọn kan ni aarin wọn dagba, wọn dogbo, amọ iku awọn miran ninu wọn jẹ agbọ-sọ-gbanu.
Eyi ni awọn oṣere sinima ede Yoruba ti wọn ku ni ọdun 2018.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Moses Adejumọ, a.k.a. Baba Sala

Ni irọlẹ, ọjọ aiku ọjọ keje oṣu kẹwa ọdun 2018 ni alagba Moses Adejumọ ti ọpọ eeyan mọ si baba sala jade laye.
Ọmọ ọdun mẹtalelọgọrin, 83 ni ki o to jade laye.

Oríṣun àwòrán, leadership
Ko si eeyan to lee kọ iyan Baba sala kere lagbo orin, itan kikọ, ere itage ati sinima paapaa julọ ka pani lẹrin.
Ni ọjọ aje ọjọ kẹjọ, oṣu kẹwa ni ọmọ rẹ tufọ rẹ faye.
Aishat Abimbọla, a.k.a. Ọmọge Campus

Oríṣun àwòrán, AISHAT ABIMBOLA/FACEBOOK
Ọmọge campus ni ọpọ mọ Aishat Abimbọla si nigba aye rẹ. Inu sinima kan to ṣe pẹlu orukọ yii, si ni inagijẹ naa ti jade fun un.
Lasiko to fi n gba itọju fun aisan jẹjẹrẹ lo jade laye ni orilẹede Canada.
Ẹni ọdun mẹrindinlaadọta ni nigba to jade laye ni ọjọ Iṣẹgun, ọjọ Karundinlogun oṣu Karun ọdun 2018 ni ilu Toronto.
Motunrayọ Adeoye.

Oríṣun àwòrán, Kola Carew Facebook
Ọkan lara awọn agba ọjẹ sinima Yoruba ni Motunrayọ Adeoye, owurọ ọjọ kinni, oṣu kẹfa ọdun 2018 lo faye silẹ lẹyin aisan ọgbẹ inu.
Mama Adeoye, gẹgẹ bi ọpọ ṣe n pee nigba aye rẹ jẹ aburo Alaafin ilu Ọyọ. Ipa ti o ko ninu sinima ‘Igbekun’ ti Kunle Afod ṣe, lo gbe han faye.
Ile rẹ to wa ni adugbo Akobọ Ojurin nilu Ibadan, ni wọn sin si.
Ọla Ọmọnitan, a.k.a. Ajimajaṣan

Ni ọjọ kejidinlogun oṣu kẹwa ọdun 2018 ni alagba Ọla Ọmọnitan ti ọpọ mọ si Ajimajaṣan jade laye.
Ẹni Ọgọrin ọdun ni alagba naa ki o to dagbere laye.
Ṣaaju ọjọ ti o ku ni o ti lọ gba itọju ni ileewosan.
Ere ọlọsọọsẹ ni o mu ki Ajimajaṣan o di gbajugbaja.












