Lagos-Ibadan Rail: Amaechi ní ojú irin Ìjú Àgbàdo gbọdọ̀ se rìn láìpẹ́

Minisita fun Eto Irina, Rotimi Amaechi ti pasẹ fun awọn osisẹ to n la oju irin Eko silu Ibadan, CCECC lati ri daju wi pe, wọn pari ọna reluwe naa laarin ọsẹ meji.
Amaechi pa asẹ yii ni Ọjọbo lasiko to n wọ ọkọ reluwe lori oju irin Ibadan si Eko ti wọn n se lọwọ, eyi ti yoo gba Abeokuta, Ibadan ati Eko.
O wa rọ ile isẹ ilẹ China to n se oju ọna naa lati mura si isẹ, ki oju irin naa le see gba fun awọn osisẹ to n sisẹ ni agbeegbe iju ni ilu Eko ati Agbado ni ipinlẹ Ogun.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Minisita fun eto irina naa fikun wi pe, oun n pada bọ fun ayẹwo oju irin naa ni Ọjọ Kẹrinla, Osu Kini, ọdun 2019, lati ri daju pe won ti pari ọna naa.
Lori ọna oju irin ti Itakpe si Warri, Amaechi ni, o di Osu Karun ọdun yii ki wọn to pari oju irin naa, lati bẹrẹ si ni gbe awọn eniyan.









