EFCC: Á sọ iye èèyàn ta rán lẹ́wọ̀n di ìlọ́po méjì ní 2019

Ibrahim Magu, alaga ajọ EFCC

Oríṣun àwòrán, @officialEFCC

Adele alaga fun ajọ EFCC, Ibrahim Magu ti n leri, leka, to si n fi ọwọ sọya pe, mariwo lasan lawọn ọmọ Naijiria ri, nidi iye eeyan ti ajọ EFCC ran lọ sẹwọn lọdun 2018.

Magu wa kede pe egungun si n bọ lẹyin rẹ ninu ọdun 2019, tori ọpọ eeyan to jẹ oniwa ibajẹ si lawọn yoo ri daju pe o da asọ ẹwọn bora.

Gẹgẹ bi agbẹnusọ fun ajọ EFCC, Tony Orilade, to gbẹnu Magu sọrọ ti wi, ajọ naa ti n se afikun aayan ri lati ri daju pe oun sọiye eeyan ti yoo lọ swọn ni 2019 di ilọpo meji awọn eeyan ti ajọ naa ran lẹwọn lọdun to kọja.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò, Ìgunnukó: Àwọn Tápà gbà pé ẹni tó bá ń sin Ìgunnukó kò ní ráùn ohun rere

"Eeyan okoolelọọdunrun o din mẹjọ (312) pere la ni ko lọ naju ni ọgba ẹwọn lọdun 2018, am ni 2019 ta wa yii, ajọ EFCC yoo ri daju pe a sọ iye awọn taa ju sẹwọn di okoolelẹgbẹta ati mẹrin (624).

Magu, ẹni to kede bẹẹ lasiko to n bawọn osisẹ ajọ naa sọrọ nigba to n rin yika inu ọọfisi ajọ EFCC, o tun fi kun pe, ajọ EFCC ti gba idajọ mẹta ninu ọdun tuntun taa bẹrẹ yii, eyi to ni o jẹ ibẹrẹ to dara.

Awọn osisẹ EFCC

Oríṣun àwòrán, @officialEFCC

Nigba to n gbosuba fun adajọ agba lorilẹede yii, Walter Onnoghen fun aseyọri rẹ lọdun to kọja, Magu ko sai yan pe ẹka eto idajọ ni kọkọrọ ti EFCC lo lati bori ọpọ ẹjọ to wa niwaju rẹ.