Àṣà Yorùbá: Èèwọ̀ ni kí obìnrin wọ igbó orò

Oríṣun àwòrán, @Khemeticchurch
Ni ilẹ́ Yoruba, oniruuru asa, ise ati igbagbọ lo wa, eyi ti o de awọn obinrin lati mase kopa ninu rẹ.
Ọpọ awọn asa yii ni awọn asaaju wa n lo lati se akoso awujọ wa, ki ohun gbogbo lee tuba-tusẹ nitori ilu ti ko ba si ofin, ẹsẹ ko si nibẹ.
Nigba miran, o si lee jẹ pe awọn orisa lo tako awọn iwa naa lati ọdọ awọn obinrin.
Laye ode oni, awọn asa ati ise aye atijọ naa ni ofin ode oni tako, ti a ko si fi bẹẹ naani wọn mọ.
Bi o tilẹ́ jẹ pe aye ti laju, ti ọpọ awọn asa ati ise yii si ti n lọ sokun igbagbe, sibẹ ọpọ wọn lo ni anfaani, iwulo ati awọn aleebu kọọkan ninu rẹ.
Àwọn asa ati ise ti obinrin ko gbọdọ gunle nilẹ Yoruba:
- Eewọ ni ki obinrin wọ igbo oro - Igbagbọ Yoruba ni pe obinrin ko gbọdọ mọ oro, kii oro ma baa gbe.
- Alaboyun ko gbọdọ ti ọwọ bọ sokoto ọkọ rẹ lati mu owo - Igbagbọ Yoruba ni pe obinrin to ba ni oyun sinu, to ba mu owo ni apo ọkọ rẹ, yoo bi ọmọ ti yoo maa fẹwọ, tabi jale.
- Oloyun ko gbọdọ ba ọkunrin ti kii se ọkọ rẹ lopọ rara.
- Yoruba ni ti ọkunrin kan ba gboju gboya lati gun le alaboyun kan, ti kii se iyawo rẹ, tabi ko jẹ pe oun lo pilẹ oyun naa tẹlẹ, iru ọkunrin bẹẹ yoo tosi ku ni.
- Obinrin to ba n se eela, tabi nkan osu lọwọ ko gbọdọ ni ajọsepọ pẹlu ọkunrin. Oniruuru ipa ni Yoruba gbagbọ pe igbesẹ naa yoo ni lori ẹni to ba se ati awujọ wa.
- Ọmọbinrin to ba jabọ lẹyin iya rẹ yoo ri iku ọkọ ni ẹẹmeje.
- Eyi lo n se ikilọ fun awọn obinrin lati maa pọn ọmọ sẹyin daada, yatọ si pe ọmọ to ba jabọ lee di ero ọrun, tabi ko di alaabọ ara,
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- wọn tun ni gbogbo ọkọ ti iru ọmọbinrin bẹẹ ba fẹ yoo maa ku titi de ori meje.
- Alaboyun ko gbọdọ rin ninu oorun, bibẹẹkọ, aafin ni yoo fi ọmọ inu rẹ bi.
- Eyi jẹ ara ọna lati daabo bo obinrin ati ọmọ inu rẹ lasiko oorun ọsan gangan.

Oríṣun àwòrán, @jide2816
Lootọ ni awọn asa ati ise yii pọ lọ jantirẹrẹ, bo si se wa fawọn obinrin, naa ni tawọn ọkunrin wa, ti gbogbo awujọ ilẹ Yoruba si ni awọn eewọ to n dari wọn, nitori idalu ni iselu.
Sugbọn o yẹ ko ye wa pe awọn ara ijọhun gbọn pupọ, o si ni idi ti wọn se gbe awọn eewọ yii kalẹ lati dari awujọ wa, eyi ti ọpọ wọn wa fun aabo lọwọ ewu.














