Kò sí ǹkan tó ń ṣe Idris agbébọn ní Kano - Ará ilé

Oríṣun àwòrán, @others
Awọn ara ilé Idris to yinbọn fun àwọn eniyan sọ pe ara Idris ya.
Nigba ti akọroyin BBC de ilé ti Idris to yinbọn fun awọn to n fi ẹṣin sare ije n gbe ni Kano ni a gbọ ọrọ kikun nipa rẹ.
Abubakar Yahaya to ni awọn ti jọ n gbe papọ fun ọgbọn ọdun ni aarẹ kankan ko ṣe Idris ni ọpọlọ.
Idris lo binu yinbọn lu eeyan meje lori ẹṣin lataari pe o ni oun ko fẹ ki wọn sare ije ẹṣin kọja ni adugbo oun.
Awọn ara ile rẹ to ku ti BBC ba sọrọ ni irọ ni pe ori rẹ daru ati pe awọn ko mọ pe Idris ni ibọn ninu ile rara.
Bawo ni ọrọ ṣe ṣẹlẹ?
Ọwọ ọlọpaa ti tẹ Idris to yinbọn ni aarin ìlú.
Lalẹ Ọjọru ni awọn eniyan kan n ṣayẹyẹ idije fifi ẹṣin sare ni agbegbe Tudun Maliki nipinlẹ Kano.
Kopẹ, ko jinna ni wọn ni ọkunrin kan da ibọn bolẹ eyi to ṣe eniyan meje lọṣẹ loju ẹsẹ.

Oríṣun àwòrán, Reuters
Ọkunrin naa ni iroyin ni o kọkọ kilọ fawọn to n fẹṣin sare naa ki wọn má gba oju titi adugbo oun kọja.
Iroyin ti a gbọ ni pe, arakunrin Idris ni oun ko fẹ ki wọn gbe ere ije ẹlẹṣin naa de adugbo oun ṣugbon awọn to n sare ko gbọ sii lẹnu.
Wọn ni lo ba wọle lọ gbe ibọn ni o si dabọn bolẹ ti ọrọ naa di pẹntuka ni Kano.
Awọn agbófinró ti mú ọkùnrin agbébọn kan to yìnbọn lu àwọn olùkópa nínú ìdíje eré sísá ẹṣin ni Kano.
Aṣoju awọn ọlọpaa ni ẹkun Kano, Abdullahi Haruna ṣalaye fun akọroyin BBC pe wọn ti ko awọn meje to ṣeṣe lọ si ile iwosan Aminu Kano fun itọju to peye.
Haruna ni awọn ti sọ Idris si gbaga ati pe ẹsun rẹ pọ bẹrẹ lati ibi ti Idris ti ri ibọn to yin atawọn ẹsun miran.
Lati asiko yii ni awọn eniyan Kano ti n bẹru pe ki ọrọ wọn ma lọ dabi ohun to n ṣẹlẹ ni Amerika pẹlu awọn agbebọn ainidi.
Bi ẹ ko ba gbagbe, laipẹ ni ọmọ oloṣelu kan yinbọn fi tu awọn to n ṣajọyọ pe ẹgbẹ wọn bori ninu eto idibo to kọja ka.















