Kano: Gomina Kano yan Emir mẹ́rin bíi Ajimobi tó jẹ́ àna rẹ̀

GANDUJE-SANUSI-AJIMOBI

Oríṣun àwòrán, WIKIPEDIA

Àkọlé àwòrán, Ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Ọba kan ló wà kí gómìnà Abiola Ajimobi tó yan ọba 43 míràn dípò ọba Olúbàdàn kan tó wà tẹ́lẹ̀.

Ijọba ipinlẹ Kano labẹ isejọba Gomina Abdullahi Ganduje ti fi ontẹ lu abadofin to fọwọ si pe ki wọn pin Kano si ọna mẹrin, ki Emir mẹrin le maa jẹ.

Ilu Kano ati isejọba Emir ẹyọkan ti pe igba ọdun ki ijọba to gbe igbesẹ yii, labẹ Emir Muhammadu Sanusi Keji.

Awọn eniyan ni igbesẹ isejọba naa ko sẹyin bi Sanusi se n tako ọpọlọpọ igbesẹ gomina Ganduje, eleyii ti wọn ni o fa igbesẹ naa.

Ijoba ipinle naa lasiko ti wọn n sọrọ ni awọn gbe igbesẹ lati pin ọba ilu naa si mẹrin lati mu ibasepọ to gbooro ati eyi to dan mọran wa laaarin awọn ara ilu ati ọba wọn.

Awọn Emir mẹrin naa yoo wa ni Rano, Gaya, Karaye ati Bichi. Bi o tilẹ jẹ wi pe wọn yoo ma a jabọ ohunkohun to ba n sẹlẹ lagbeegbe wọn fun Emir Sanusi, agbara kan naa ni wọn ni gẹgẹ bi Emir ilu Kano.

Àkọlé fídíò, 'Mo rántí, láyé ìjọba ológun... ohun tójú oníròyìn ń rí'

Emir Sanusi to jẹ gomina apapọ banki Naijiria tẹlẹ, ko i tii sọrọ nipa igbesẹ gomina yii.

Bawo ni igbesẹ gomina Ọyọ ati gomina Kano se jọ ara wọn?

  • Ọdun to kọja ni ọmọkunrin gomina ipinlẹ Ọyọ, Ajimobi fẹ Ọmọbinrin gomina ipinlẹ Kano ti wọn si di ana ara wọn.
  • Amọ ohun to tun pa wọn pọ ni igbesẹ ti ijọba ipinlẹ Kano gbe lati yan Emir mẹrin kun Emir Sanusi lati ma a se isakoso ilu kan.
  • Ti a ko ba gbagbe, ọdun to kọja kan naa ni gomina Ajimobi fi ọba mejilelaadọta jẹ kaakiri ipinlẹ Ọyọ, eleyii to seese ko din agbara Olubadan to jẹ ọba to wa ni ipinlẹ Ọyọ tẹlẹ.
  • Amọ, bi o tilẹ jẹ pe ẹjọ ọba yiyan ni Ọyọ ṣi wa ni ilẹ ẹjọ, Emir Sanusi ko i ti i fesi lori igbesẹ gomina ipinlẹ Kano yii.