Èyí ni bí àwọn ọmọ̀dé 20 ṣe kú sínú kànga ní Kano

Máni gbàgbé ni ọjọ́ kọkàndínlógún, oṣù Kẹrin ọdún 2018 jẹ́ fún ìdílé Bashir Hotoro. Lọ́jọ́ nàá, ọmọ wọn obìnrin, tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́jọ, Zulaiha Bashir, lọ pọn omi ní inú kànga kan tó wà nítòsí ilé wọn, láti fi wẹ̀, ṣùgbọ́n tí kò padà sílé nítorí pé ó jábọ́ sínú kànga.
Gẹ́gẹ́ bí ilé iṣẹ́ paná-paná ní ìpínlẹ̀ Kano ṣe sọ, ọmọdébìnrin ọ̀hún ni ẹnì kẹrìnlélọ́gbọ́n tí ìròyìn rẹ̀ tẹ àwọn lọ́wọ́ pé ó kú nípa kíkó sí kànga tàbí inú odò.
Ṣùgbọ́n, ohun tó n kọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ lóminú ni pé, ọdún yìí kò ti dé ìlàjì, tí nkan tó tó bẹ̀ ti ṣẹlẹ̀.
Ìyá ọmọ náà, Mallama Haddaniya Bashir, tó bá BBC Pidgin sọ̀rọ̀ ní , òun kò le gbàgbé ìṣẹ̀lẹ̀ na títí láí.
"Èmi àti Zulaiha la jọ wà lábẹ́ igi tó wà nínú ọgbà ilé wa lọ́jọ́ nà, ló bá sọ pé ooru n mú òun, ni mo bá ní kó lọ pọn omi kó fi wẹ̀. Bẹ̀ ẹ́ ló bá gbé ike omi tó sì lọ
Omi àkọ́kọ́ ló n fà jáde nínú kànga, nígbà tí ìfami fa òun fúnra rẹ̀ sínú kànga nà. Kó sì tó dí pé àwọn ènìyàn dóòlà rẹ̀, ó ti kú.

"Bíó tilẹ̀ jẹ́ wí pé a gbà pè àsìkò rẹ̀ ló tó gẹ́gẹ́ bíi musulumi, ṣùgbọ́n ìrú èyí kò bá má ṣẹlẹ̀ kání a ní omi ẹ̀rọ̀ nínú ilé wa tàbí nítòsí. Ìjọba maa n gbé omi wá fún wa tẹ́lẹ̀, ṣùgbọ́n, wọ́n ti dáwọ́ rẹ̀ dúró."
Abílékọ Bashir tún sọ pé kí ìjọba wá nkan ṣe sí bí àwọn ènìyàn ṣe n gbẹ́ kànga lọ́nà tó wù wọ́n.
Alhaji Aminu Kura tún ni òbí míì tó pàdánù ọmọ rẹ̀ Farook, tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́ta lọ́dún márùn ún sẹ́yìn.
Ó sọ fún BBC pé ìjọba pẹ̀lú ìfọwọ́sowọ́pọ̀ àwọn olórí agbègbè, gbọdọ̀ maa mójútó bí àwọ̀n ènìyàn ṣe n gbẹ́ kànga ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìlànà ètò ààbò.

Àmọ́ nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, agbẹnusọ fún gómìnà ìpínlẹ̀ Kano, Dókítà Abdullahi Ganduje, Aminu Yassar, sọ pé "ohun tó ṣẹlẹ̀ kò ní nkankan ṣe pẹ̀lú pé ìyà omi n jẹ ìpínlẹ̀ naa.
Ó ní kànga ti wà fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún, ó sì ní bí wọ́n ṣe n gbẹ́ ẹ, tí wọ́n sì ti lo ọ̀pọ̀ ọdún tí ẹnikẹ́ni kò sì kú sínú wọn.
Àti pé títẹ̀lé ìlànà ètò ààbò ni ọ̀nà àbáyọ̀."













