Sri Lanka: Gauria ti di ololufẹ Roshan bẹ́ẹ̀ ọ̀tá ni wọ́n nígbà ogun abẹ́lẹ́ Sri Lanka

- Author, Suneth Perera
- Role, BBC News
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4
Ko sẹni to maa ri awọn ololufẹ meji yii ti wọn n dọwẹkẹ ti ko ni ya lẹnu.
Gauri Malar ati Roshan Jayathilake ni wọn ti di tọkọtaya pẹlu ikoko lọwọ.
Ọrọ ifẹ bi adanwo ni awọn agba maa n sọ nilẹ Yoruba.
Ogun abẹle Sri Lanka ni ololufẹ mejeeji ti jọ jagun lodi sira wọn fun ọdun mẹwaa.
Guri to jẹ ọmọ ọdun mẹrindinlọgbọn jẹ ọmọde ọmọ ogun ilẹ̀ fun awọn Tamil Tigers.
Ijẹgaba awọn eniyan Roshan ni wọn n ja lodi sí ninu ogun abẹle Sri Lanka.
O ni: Mi ko ri awọn eniyan Sinhalese ri tabi ba wọn sọrọ ri.
A ro pe eniyan buruku ni wọn ti wọn fẹ pa wa.
Koda oju ọta ni awa mejeeji fi n wo ara wọn ki ọrọ ifẹ to wọnu ọrọ wọn.
Bẹẹ ọrọ ọja ti ọmọ ba ti wọ ti di òkùtà ni bayii".
Kini o wa ṣokunfa okùn ifẹ wọn tuntun?
Iku ọrẹ mi lo so wa pọ!
Odun 1983 ni ija Sri Lanka bẹrẹ nigba ti awọn ẹka Tamil binu ti wọn si ṣafikun owo tawọn ẹkun Sinhalese n san lapapọ.
Iroyin ni wọn pa omo ogun mẹtala nigba ti wọn dena de wọn eyi to bi iku ogunlọgọ awọn ẹya mejeeji.
Ni eyi ti ọpọ ẹmi ati dukia si sọlu si aigbọra-ẹni-ye naa laarin ẹkun mejeeji.

Oríṣun àwòrán, AFP
Loṣu kinni, ọdun 2009 ni ohun gbogbo yipada fun Gauri nigba ti o gbọ iroyin ikọlu si ọkọ̀ oko ẹgbọn rẹ, Subramaniyam Kannan.
Ikọlu yii lo ṣokunfa iwọde lodi si awọn Tamil ni eyi to gba pe ko ṣeyin wọn ni abule rẹ ni Vishwamadu ni ariwa Sri Lanka.
Pẹlu ibanujẹ ni Gauri wa ẹgbọn rẹ kiri ki ọwọ awọn ọmọ ogun ọlọtẹ too tẹẹ.
Wọn sọ Gauri ọmọ ọdun mẹrindinlogun di ọmọ ogun laarin ọsẹ kan wọn si ran an lọ soju ogun.
O ni: mo ri bi wọn ṣe n yinbọn pa ọpọ eniyan koda, ado oloro ba ọrẹ mi timọtimọ.
Mo gbiyanju lati doola ẹmi rẹ kuro nibẹ ṣugbọn ọrẹ mi kọ̀.
O ni oun ti loogun ipaniyan nitori o san fun oun lati ku ju ki oun wa laaye lọ.
Ọpọ igba ni Gauri ni awọn ko ri aaye wẹ debi jẹun ni asiko yii.
O ni oun gan an fẹ pa ara oun lori gbogbo ogun yii.
Bi ogun ṣe bẹrẹ loju ọkọ iyawo -Roshan
Ọmọ ọdun mẹrinla ni Roshan nigba ti ogun Sri Lanka bẹrẹ lọdun 2004.
Ado oloro lo bọ sinu abule rẹ laisun ọdun Sinhalese ti ẹlẹsin Hindu laarin awọn ọmọ ogun mejeeji.
Lẹyin eyi lo tẹlẹ Baba rẹ ati ẹbi lọ si ẹka eto aabo ara ilu nitori ọpọlọpọ ikọlu to n ṣẹlẹ.
Iroyin ni wọn ti pa o le ni ẹgbẹrun ọgọrun un eniyan ki ogun naa to pari lọdun 2009.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Lọdun 2015 ni ajọ iṣọkan agbaye fẹsun kan ẹkun ọmọ ogun mejeeji pe wọn pa awọn eniyan lọna aitọ, ati pe wọn fipa ba wọn lo pọ.
Wọn tun ni wọn fi agidi mu awọn ọmọde ati agba jagun lọna ti ko yẹ.
Gauri jagun fun igba diẹ ki olori ikọ ogun rẹ to tuu silẹ lataari ilera ara rẹ ti ko pé.
Lẹyin eyi lo fi ara rẹ silẹ fun awọn ọmọ ogun Sri Lanka ti wọn ran lọ fun eto igbe aye ọtun ni awujọ.
Ni abule Udayankatu ti ijọba da silẹ fun eto ọgbin lẹyin ogun ni o ti pade ọkọ rẹ.
Kini o ṣokunfa igbeyawo awọn ọmọ ogun mejeeji?
Roshan ti n ṣiṣẹ ni abule yii ki iṣẹ tó gbe Gauri lọ si abule yii.
Aigbọ ede ti wọn n sọ ni abule yii ko tẹ Roshan lọrun lẹnu iṣẹ rẹ ko to pade Gauri to n tumọ ede wọn fun un lẹnu iṣẹ.

Gauri ni oun gbagbọ pe aaro ile n figba gbogbo sọ Roshan paapaa nitori aigbọ ede wọn yii.
O ni ọpọ igba ni oun maa n se ounjẹ wa fun Roshan nigba ti ifẹ wọn ti n fẹsẹ mulẹ.
Ko pẹ ko jinna ni ọrọ ifẹ wọn wọ̀ daadaa ti Gauri ni oun fẹran Roshan ju bi iya rẹ ṣe fẹran rẹ lọ.
Roshan royin ifẹ ti Gauri ni si oun koda nigba ti oun gba isinmi, ni ṣe ni o n sunkun.
Bawo ni ara ìlú ṣe tẹwọ gba ifẹ awọn ọmọ ogun ọta ara wọn meji yii?
Awọn mejeeji sọrọ lori itako ti wọn jọ ni lati ẹkun onikaluku.
Okan ninu awọn ẹbi Roshan ni: ọpọlọpọ awọn ọmọge lo wa ni Sinhalese... ki ni oju rẹ ṣe ran mọ ti Tamil?

Iya Roshan ko faramọ ajọṣepọ naa rara, bakan naa ni ẹgbọn Gauri to jẹ ọmọ ogun Tamil Tiger tẹlẹ naa fariga.
O ni fifẹ Roshan yoo mu Gauri kuro nitosi abule wọn.
Ko pẹ, ko jinna ni awọn mejeeji fi ọrọ ifẹ didun bori ogun inu ẹbi mejeeji ti wọn si ṣe igbeyawo.
Gauri ni nkan pada rọgbọ ninu ile ni eyi ti inu iya Roshan dun si Senuli Chamalka, ọmọ tuntun ti wọn bi ki iya naa to ku.
O ni ọmọ awọn yii lo tubọ di okun ifẹ wọn mu pẹlu alaafia ni awujọ.
Lọdun 2014 ni wọn ṣe igbeyawo.
Bayii, wọn jọ maa n mu ọmọ wọn lọ sile ijọsin Hindu ati Budhi ni nitori pe ọrọ wọn ti jọ ye ara wọn.
Gauri ni ojoojumọ ninu ẹgbọn oun maa n dun si Roshan nitori iwa irẹlẹ rẹ.
Kọkọrọ kan to le ba eyin aja jẹ:
Ẹru to n ba wọn nisinyi ni ikọlu tuntun to ṣẹlẹ lọjọ Aiku, ọjọ ajinde to kọja.
Eyi to ṣe iku pa o le ni aadọta le ni igba eniyan ati ikọlu ẹsan ti wọn ṣe pada sawọn alakatakiti ẹsin Islam to n fa wahala.

Ẹru ipinya n ba awọn lọkọlaya yii pe ki orilẹ ede Sri Lanka ma tun bẹrẹ ogun mọ.
Gauri ni ẹru iku awọn eniyan lo n ba oun nitori ẹni to ba ti ri ogun ri, ko ni gbadura ogun mọ.






















