Presidency: Buhari kò leè ṣàtìlẹyìn fún olùdíje Amosun l'Ogun

Adekunle Akinlade, Aarẹ Buhari ati Gomina Amosun

Oríṣun àwòrán, oGUN STATE GOVERNMENT

Àkọlé àwòrán, Èdèàìyedè ti ń wáyé nípínlẹ̀ Ogùn láàárín Gómìnà Amosun àtàwọn adarí ẹgbẹ́ òṣèlú APC lápapọ̀

Ileeṣẹ aarẹ orilẹ-ede Naijiria ti sọ pe ko si idi kan fun Buhari lati ṣatilẹyin fun oludije ipo gomina n lẹgbẹ oṣelu APM nipinlẹ Ogun, Adekunle Akinlade ti gomina Ibikunle Amosun mu wa baa ni ọjọ aiku.

Olubadamọran fun aarẹ lori ọrọ iroyin, Garba Shehu lo ṣalaye ọrọ yii lori ohun to pe ni omilẹgbẹ ibeere awọn oniroyin lori bi Aarẹ Buhari ṣe gbalejo Adekunle Akinlade ti gomina Amosun mu lọ baa niluu Abuja lẹyin ti o ti kọkọ gbalejo Dapọ Abiọdunti Oloye Oluṣẹgun Ọṣọba mu wa baa ṣaaju.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ohun ti o ru ọpọ loju lori ọrọ naa ni bi aarẹ yoo ṣe ṣatilẹyin fun oludije meji lati ẹgbẹ oṣelu meji ọtọọtọ ni ipinlẹ kan naa.

Ṣugbọn ileeṣẹ aarẹ, lati ẹnu Garba Shehu, ṣalaye pe gbogbo awọn oludije to wa lati abẹ aṣia ẹgbẹ oṣelu APC kaakiri orilẹede Naijiria ni aarẹ Buhari yoo ṣe ipolongo fun.

Ọṣọba, Abiọdun ati Buhari

Oríṣun àwòrán, oGUN STATE GOVERNMENT

Àkọlé àwòrán, Ohun to ru ọpọ loju ni oludije ti kan aarẹ Buhari wa pẹlu ni ipinlẹ Ogun

O ni aarẹ ko lee kọ ipakọ si ẹnikẹni tabi oludije lati awọn ẹgbẹ oṣelu miran ti o ba wa kii; bẹẹni ko lee sọ pe ohun ko fẹ atilẹyin wọn.

"Ti ẹgbẹ oṣelu APC ni Buhari nṣe, ko si edeaiyede kankan nibẹ. Awọn oludije APC ni aarẹ Buhari yoo ṣe ipolongo fun."

Gomina Amosun ati awọn adari ẹgbẹ oṣelu APC n forigbari bayii lori tani yoo dije fun ipo gomina ni ipinlẹ Ogun. Amosun n fẹ ki Adekunle Akinlade dije ṣugbọn Dapọ Abiọdun ni awọn adari ẹgbẹ oṣelu naa n fẹ.

Àkọlé fídíò, Alao Akala:Èmi àti Ajimọbi kò ṣe ìlérí kankan fún ara wa