Gabon: Àlááfíà ti padà, a ti mú àwọn ológun tó fẹ́ gba ìjọba

Oríṣun àwòrán, Reuters
Ijọba ilẹ Gabon ti ni alaafia ti pada si eto oṣelu orilẹede naa lẹyin ti awọn ologun gbiyanju lati gba ijọba orilẹede naa.
Agbẹnusọ fun ijọba orilẹede naa, Guy-Bertrand Mapangou ti sọ fun BBC pe awọn ti mu awọn ọmọ ogun mẹrin ninu marun to gbe igbeṣe naa,to si ni awọn si n wa ẹni ikarun.
Awọn ọmọ ogun to wa ni ipo kekere naa sọ wi pe awọn gba nitori awọn fẹ da ijọba tiwantiwa pada si orilẹede naa.
‘A gba ìjọba láti dá ìjọba tiwantiwa padà’
Ile iṣẹ ologun ni orilẹede Gabon sọ wi pe awọn ti gba ijọba ti ile Gabon to kun fun ọpọlọpọ ohun alumọni epo rọọbi.
Awọn ọmọ ologun ni agbeegbe Iwọ-oorun ilẹ Afirika naa ni awọn gbe igbese naa lati da eto oselu tiwantiwa pada si orilẹede naa.
Awọn ologun naa ti gba ile isẹ redio ti ijọba ni aago mẹrin owurọ oni ti wọn si polongo ‘Ajọ National Restoration Council’ to ti gba ijọba.

Aarẹ Ali Bongo gba ipo ni ọdun 2009 ti o si ti fi orilẹede naa silẹ lati bi osu meji sẹhin.
iroyin ni Aarẹ Bongo to bẹrẹ aarun rọpa rọsẹ ni Osu Kẹwa, ọdun to kọja, ti o si n gba itọju ni orilẹede Morocco.













