Àwòrán Amosun, Adekunle àti Buhari tó n dá awuyewuye sílẹ̀

Oríṣun àwòrán, @AHMAD BASHIR
Lọjọ́ Aiku ni Gómìnà ìpínlẹ̀ Ogun, Ibikunle Amosun kọwọrin lọ si ọdọ Aarẹ Buhari pẹlu oludije Gomina ayanfẹ rẹ Adekunle Akinlade.
Ipade kan ti waye nile ijọba orile-ede Naijiria nilu Abuja laarin Gomina Ipinlẹ Ogun, Ibikunle Amosun ati Aarẹ orile-ede Naijiria Muhammadu.
Ipade naa kii ṣe akọkọ ti awọn mejeeji yoo jọ ṣe ṣugbọn ohun to ya awọn eeyan lẹnu nipa ipade naa ni pe Gomina Ibikunle Amosun kọwọrin lọ ipade naa pẹlu oludije ipo Gomina lẹgbẹ oṣelu APM, Adekunle Akinlade.
Iyẹn nikan kọ, ati Gomina Amosun Akinlade ati Aarẹ Buhari wọn jijọ ya awọran kan nibi ti wọn ti nawọ soke lati ṣe afihan pe awọn faramọ iṣejọba ọdun mẹrin miran sii fun Aarẹ Buhari.

Oríṣun àwòrán, @Mr Khaleed
Aworan yi ati awọn miiran ti wọn ya nibi ipade naa ti n da awuyewuye loju opo Twitter ti awọn ọmọ ẹgbẹ APC kan si ti ni iru iwa bayi fidi rẹ mule pe Aarẹ Muhammadu Buhari lo n fi ọwọ ararẹ sakoba fun irẹpọ ninu ẹgbẹ.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 2
Bi a ko ba gbagbe, lai pẹ yi ni Gomina Amosun lewaju awọn ọmọ ẹgbẹ APM la ti lọ fun Aarẹ Buhari ni iwe atilẹyin lati ọdọ ẹgbẹ naa gẹgẹ bi oludije ipo Aarẹ ti wọn yan laayo.
Ko daju boya Aarẹ Buhari jan oludije ẹgbẹ yi ni òǹtẹ̀ nibi ipade naa ṣugbọn ko sọ bakan naa pe oun lodi si iwa Amosun ti awọn ọmọ ẹgbẹ APC kan ri gẹgẹ bi iwa to lodi si aṣẹ ẹgbẹ.
Amosun ti sọ nita gbangba pe oun ko nigbe lẹyin oludije ẹgbẹ APC nipo Gomina mii bi kii ṣe Adekunle to jẹ aayo rẹ.
















