Pátá Jíjí : Agbẹnusọ ọlọ́pàá ní àwọn olè ajípátá ń gbìdánwò ìpànìyàn ni

Oríṣun àwòrán, Tori.ng
Isẹlẹ jiji pata awọn obinrin lo ti di iroyin to n gbalẹ bii ọwara ojo lawujọ wa bayii.
Awọn iroyin kan lo ni, awọn eeyan kan to n lu jibiti, ti wọn n pe ni ọmọ Yahoo, lo n ji pata awọn obinrin lati fi se oogun owo.
Ọpọ awọn afurasi tọwọ ba lori ẹsun yii, ni wọn ti n naju ni agọ ọlọpaa.
Àwọn ìròyìn mìíràn tí ẹ lè nífẹ̀ẹ́ sí:
Nigba to n sọrọ lori isẹlẹ ọtun to gba awujọ wa kan yii, Dolapo Badmos, tó jẹ́ agbẹnusọ iléeṣẹ́ ọlọpàá Ẹkun keji, to wa ni ipínlẹ̀ Eko ní, ó ṣéeṣe kí àwọn olè ajípáta naa jẹ́jọ́ ẹ̀sùn ìpànìyàn, tí ọwọ́ bá tẹ̀ wọ́n.
Badmos ṣàlàyé loju opo ikansiraẹni nstagram rẹ̀ pé, irú ẹ̀sùn náà ṣeéṣe nítorí àwọn olè ajípátá tí ọwọ́ tẹ̀, ní wọn n gbero lati se oògùn owó tí yóò ṣe ikú pa ẹni to ni pata naa.

Oríṣun àwòrán, Dolapo Badmos/Twitter
Bi ọ̀rọ̀ oogun owo ṣe n wọ́pọ̀ si, ni ọwọ n tẹ awọn afunrasi tí wọn ní o ń jí awọ̀tẹ́lẹ̀ awọn obinrin, nibi ti wọ́n ba sá wọn sí.
Ní ọjọ́ kẹta oṣu kinni ọdun 2019, ni ọwọ awọn agbófinró tẹ awọn ọmọdekunrin mejì tí wọ́n fẹ̀sun kan pe, wọn ji pata awọn obinrin mẹ̀wàá ká lórí okùn níbi tí wọ́n sá wọn si nílu Agbarha, nijọba ibilẹ̀ Ukwuani ni Ipinlẹ̀ Delta.
Asiko kan naa ni ọwọ tun tẹ ọmọdekunrin kan ni ilu Benin ni Ipinlẹ̀ Edo, ti wọn fi ẹsun kan pe o lọ ji pata awọn obinrin ka lori okùn.
Ọwọ tẹ afẹsunkan naa lẹyin igba ti Ọba Benin, Ọba Ewuare keji, kilọ̀ fun awọn ọdọ ki wọn ye ti ọwọ bọ sise oogun owo, ti yoo jẹ ki wọn maa ji pata kiri.

Oríṣun àwòrán, Thegeniusmedia.com.ng
Ẹ mà sọ pátá tí ẹ ò lò mọ́ sọnù - Òsèré Mosun Filani
Ọ̀rọ̀ pátá jíjí yìí ti sọ oun tí àwọn obinrin lè ṣe si àwọ̀tẹ́lẹ̀ tí wọn kò bá nílò mọ́ di ọ̀rọ̀ ńlá báyìí.
Òun ló jẹ́ kí gbajúgbajọ̀ òsèré tíátà, Mosun Filani gba àwọn obìnrin ní ìmòràn, pe kí wọ́n máà fi abẹ gé àwọ̀tẹ́lẹ̀ tí wọn kò bá nílò mọ́ wẹlẹwẹlẹ, dípò pe kí wọ́n máa sọ́ si ibi tí àwọn tó lè fi ṣe oogun owó yóò ti ri i.
Oun tó sọ sọrí ayélujára rèé:
"Torí bá kó ọ yọ lọ́wọ́ àwọn ajínigbé, àmọ́ tí pátá rẹ̀ bọ́ sọ́wọ́ àwọn ẹni ibi, o ò jájábọ́ o. Inú balùwẹ̀ ni kí ẹ máà sá pátá yín sí, ẹ má sa sí ẹ̀gbẹ́ fèrèsé.
Ẹ máse sọ pátá tí ẹ kò lò mọ́ sibi kan ṣáá. ẹ gée wẹ́lẹ́wẹ́lẹ́ tàbí kí ẹ fi iná sun ún. Ní 2019 yìí, ayé kò ní ká pátá wa lọ o."













