Daily Trust: A kò mọ̀ ohùn tó mú Iléeṣẹ́ ológun tí ọọfisi wà ní Maiduguri àti Abuja

ami ile ise ologun Naijiria

Oríṣun àwòrán, @nigeriaarmy

Àkọlé àwòrán, Ileeṣẹ ologun orileede Naijiria ti ti ile iroyin Daily Trust pa ni ilu Maiduguri ati ilu Abuja.
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ile iṣẹ ọmoogun Naijiria ti ni Daily Trust fi gbogbo aṣiri bi awọn ṣe n gbogun ti Boko Haram lede ni awọn ṣe ti ọọfisi wọn pa.

Ninu atẹjade ti wọn fi si ori itakun ibanisọrọ Facebook wọn, ile iṣẹ ọmọogun naa ni aṣiri ti ile iṣẹ iroyin naa fi lede mu ki awọn ikọ agbesunmọmi Boko Haram mọ gbogbo irinsi wọn, eleyi ti o le fa ikọlu si orilẹ-ede naa.

Wọn fikun wi pe awọn ko ṣe ikọlu si ile iṣẹ iroyin naa lati pa wọn le nu mọ, amọ lati ṣe iwadii bi wọn ṣe ri awọn iroyin ti ko yẹ ko jade sita naa.

Àkọlé fídíò, Alao Akala:Èmi àti Ajimọbi kò ṣe ìlérí kankan fún ara wa

Ijọba ti pasẹ ki wọn si Daily Trust

Lẹyin awuye wuye to ṣẹlẹ lori bi ileeṣe Ologun Naijiria ṣe ti ile iṣẹ iwe iroyin Daily Trust pa ni ìjọba Naijiria paṣẹ fawọn ọmọ ogun lati ṣi Daily Trust padà.

Agbẹnusọ fun Aarẹ Mohammadu Buhari, Garba Shehu lo fi eyi lede lori ikanni twitter ẹ pé:

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 1

Bakan naa lo fi idi eyi mulẹ pe, ni kete tijọba fi àṣẹ yii sita ni wọn ti ṣi ile iṣẹ Daily Trust pada.

Díẹ̀ lára èrò àwọn eniyan Naijiria ni pé:

Loju àwọn kan, wahala ni eleyii maa bi ninu ijọba to ba faaye gba awọn ologun lati maa ṣe ohun to wu wọn nigba to wu wọn.

Skip X post, 2
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 2

Awọn bii Lade, àti Ijai gbà pe eyi n fihan pe nkan ko fararọ ninu ijọba ni bayii

Skip X post, 3
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 3

Àkọlé fídíò, Kwara yóò gbàlejò BBC Yoruba

Opọlọpọ lo gba pe ominira ọrọ yẹ ko jẹ ẹ̀tọ́ àwọn eniyan ati pe ko si ijọba to yẹ ko kọja ariwisi ki wọn le tubọ huwa akin sii.

Skip X post, 4
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 4

Ọmọogun Naijiria

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Awọn ọmọogun jẹwọ idi ti wọn ko fi lee pa ina Boko haram

Awọn miran n sọrọ si aarẹ Buhari pé o yẹ ko ṣe ohun to yẹ gẹgẹ bii ọgagun to mọ nipa iṣakoso ati pe o yẹ ki wọn fiya to tọ jẹ awọn ọmọ ogun to ṣe eyi

Skip X post, 5
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 5

Skip X post, 6

End of X post, 6

Awọn miran fi lede pe, ọmọ ẹbi kan naa ni Daily Trust ati APC fun idi eyi...

Skip X post, 7
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 7

Loju Garba Shehu, ijọba Buhari paṣẹ yii ki agbara òfin lè fi di mimuṣẹ ni

Skip X post, 8
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 8

Kí ló ṣelẹ̀ sẹ́yìn?

Ileeṣẹ ologun orileede Naijiria ti ti ile iroyin Daily Trust pa nilu Maiduguri ati ilu Abuja.

Koda wọn ko awọn akoroyin meji lọ ni ileeṣẹ naa to wa ni Maiduguri.

Ẹka Ile iṣe iwe iroyin Daily Trust to wa ni ilu Maiduguri la kọkọ gbo pe wọn yabo ti wọn gbe Uthman Abubakar to jẹ olootu iwe iroyin naa lagbegbe ohun pẹlu akoroyin rẹ kan Ibrahim Sawab lọ.

Aworan Akoroyin

Oríṣun àwòrán, @FACEBOOK/UTHMAN ABUBAKAR/IBRAHIM SAWAB

Àkọlé àwòrán, Awọn oṣojumikoro ni awọn mejeeji ni awọn ọmọogun gbe lo nigba ti wọn wa si ile iṣẹ iroyin naa

Ileeṣẹ iroyin ko ti sọrọ nipa ohun to fa iṣẹlẹ yi titi di bi a ti ṣe nkoroyin yi.

Loju opo Twitter iwe Iroyin Daily Trust ni wọn fi ọrọ yi si lọjọ aiku ti wọn si ni ko si ẹni to mọ ibi ti wọn gbe awọn akoroyin naa lọ.

ile iṣẹ
Àkọlé àwòrán, Wọn ti paṣẹ ki wọn ṣi Daily Trust pada
Skip X post, 9
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 9

Ninu ọrọ ti iwe iroyin naa kọ, wọn ni awọn fura si wi pe igbesẹ awọn ọmọogun Naijiria yi ko sẹyin iroyin kan ti awọn gbe jade lọjọ aiku nipa iṣẹ awọn ologun lagbegbe ila oorun ariwa Naijiria.

Wọn ni bakannaa ni wọn n bere Hamza Idris ti orukọ rẹ wa lori iroyin naa.

Aworan iroyin ti Daily Trust gbe jade

Oríṣun àwòrán, @Daily Trust

Iléesẹ́ ológun Nàíjíríà ti Daily Trust pa ní Maiduguri àti Abuja

Aworan iroyin ti Daily Trust gbe jade

Oríṣun àwòrán, @Daily Trust

Ko pe si igba ti wọn yabo ileeṣẹ iroyin naa ni Maiduguri, ni awọn ọmọogun tun ṣigun lọ si ile iṣẹ iroyin naa ni Abuja lọjọ aiku kanna ti wọn si ko awọn Komputa awọn akoroyin nibẹ.

Lọwọlọwọ bi a ti ṣe nkọroyin yi, agbo pe wọn ti da awọn oṣiṣẹ ile iroyin naa sita kuro ni ọfisi wọn to wa ni adugbo Jabi nilu Abuja.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Akoroyin kan pẹlu ileeṣẹ Daily Trust sọ fun BBC pe awọn akegbe oun nileeṣẹ iroyin naa l'Abuja wa ni ibẹrubojo lẹyin ti awọn ologun ya bo ileeṣẹ wọn.

''Wọn fẹ dunkoko mọ wa ni,eyi si lodi sofin to fayegba wiwi tẹnu ẹni.''

O ni awọn gbiyanju lati ba awọn ileeṣẹ ologun sọrọ ṣugbọn awọn ko laanfaani lati ri wọn ba sọrọ.

Aworan awọn ọmọogun to yabo ile iroyin Daily Trust

Oríṣun àwòrán, @Daily Trust

Lẹnu ọjọ mẹta yi, ileeṣẹ ologun Naijiria n ba awọn to ba sọrọ nipa ija rẹ pẹlu Boko Haram fa wahala.

Bi a ko ba gbagbe, ileeṣẹ ologun lọdun tokọja bẹnu àtẹ́ lu ìwádìí Amnesty International pe wọn fẹ tu Naijiria ka pẹlu abajade iwadii wọn pe o le ni ẹgbẹrun mẹta eeyan ti wọn ti lugbadi iku lataari aawọ laarin awọn agbe ati darandaran ni Naijiria.

Ileeṣẹ ologun ninu atẹjade kan lati ọdọ ọgagun Sani Usman to jẹ agbẹnusọ wọn ni niṣe ni ajọ naa n gbero lati tu Naijiria ka.

Koda wọn pe fun titi fun titi oriko ajọ naa jakejado Naijiria.

Àkọlé fídíò, Ìwà ipá nínú ìdílé máa ń bí ìgè àti àdùbí ni tó lè já sí ikú