NLC: Ìpàdé ọjọ́ Ajé ni yóò sọ bóyá á yansẹ́ lódì

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ẹja pọnbele ni ipade to waye laarin minisita fọ̀rọ̀ osisẹ́ ati ijọba apapọ lọjọ Ẹti, nitori igun mejeeji ko lee fi ẹnu ọrọ jona lori igbesẹ sisan ẹgbẹrun lọna ọgbọn naira gẹgẹ bii owo osu to kere julọ fun osisẹ kan ni orilẹede yii.
Ipade ọhun, to gba wọn to wakati meje gbako, ni wọn tun sun siwaju di ọjọ Aje, ọjọ Keje osu Kinni ọdun 2019.
Nigba to n bawọn akọroyin sọrọ lẹyin ipade naa, aarẹ apapọ fun ẹgbẹ osisẹ NLC, Ayuba Wabba ati akẹẹgbẹ rẹ fun TUC, Kaigama Bobboi, sọ fun awọn akọroyin pe lootọ ni ilọsiwaju wa nipa aawọ to wa nilẹ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Amọ wọn fikun pe ipade miran ti yoo waye lọjọ Aje ni yoo sọ boya ẹgbẹ osisẹ yoo tẹsiwaju pẹlu iyansẹlodi to fẹ gunle lọjọ Isẹgun abi bẹẹ kọ.
Wabba ni "A ti joko jiroro lori ọrọ to nii se pẹlu owo osu, amọ a pinnu nibi ipade naa lati sun ijiroro naa siwaju di ọjọ Aje, ka to lee fi ẹnu ọrọ jona nipa aawọ to wa nilẹ.
O fikun pe ẹgbẹ osisẹ fẹ ri daju pe wọn gbe aba sisan owo osu naa lọ sile asofin apapọ lati buwọlu, ki owo osu to kere julọ naa lee de apo awọn osisẹ kọọkan .

Ninu ọrọ tiẹ, Minisita fọrọ osisẹ, Dokita Chris Ngige salaye pe, oun to mumu julọ laya aarẹ Muhammadu Buhari bayii ni sisan owo osu tuntun fawọn osisẹ ilẹ yii.
O fikun pe ọjọ Aje lawọn yoo fẹnu ọrọ jona lori igbesẹ gbigbe aba sisan owo osu tuntun naa de ile asofin apapọ, pẹlu afikun pe ijọba yoo rọ awọn ijọba ipinlẹ lati wa owo fi san alekun owo osu naa.













