Dino gba àgọ́ Ọlọ́pàá ré sílé ìwòsàn

Sẹnetọ Dino Melaye tó ṣẹṣẹ yọju si agọ Ọlọpáà lati yọju si ọga agba awn ọlọpaa ti di ero ile iwosan.
Ṣaaju, Sẹ́nétọ̀ Dino Melaye tó ń ṣojú ẹkùn Iwọ̀ Oòrun ìpínlẹ̀ Kogi ti jọ̀wọ́ ara rẹ̀ fún àwọn ọlọ́pàá.

Lonii, ọjọ ẹti, ọjọ kẹrin oṣu kinni ni èyí wáyé gẹgẹ bi iroyin ṣe sọ ọ wi pe awọn akẹgbẹ Melaye kan lo ba a sọrọ.
Akọroyin BBC to ṣe ibẹwo si ile rẹ fabọ jẹ ni pe wọn ti gbe aṣofin naa lọ si ọfiisi awọn ọlọpaa kogberegbe SARS fun ifọrọwanilẹnuwo.

Oríṣun àwòrán, Getty Images, @DinoMelaye
Dino lọ si olu ile iṣẹ ọlọpaa to wa nilu Abuja lati le yọju si ọga agba ọlọpaa ṣugbọn a gbọ pe wọn ni ko lee ri ọga tori o wa ninu ipade.
Laarin awọn akẹgbẹ rẹ lo ti gba ile iṣẹ awọn ọlọpaa kogberegbe lọ.
A n se akojọpọ ẹkunrẹrẹ iroyin yajoyajo lọwọ, a o maa gbe ẹkunrẹrẹ iroyin naa sori atẹ iroyin wa laipẹ. Ẹ jọwọ, ẹ tun oju opo iroyin yi yẹwo, ki ẹ lee ri ẹkunrẹrẹ iroyin ọtun laipẹ.








