#RevolutionNow: Àwọn olùwọ́de ń fẹ́ kí ìjọba wọ́nà àbáyọ sí ààbò tó mẹ́hẹ

Awọn ọlọpaaa duro si iwaju ọgba fasiti Ibadan
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ko dabi ẹni pe eto iwọde Revolution now seso rere nilu Ibadan, tii se olu ilu ipinlẹ Oyo nitori paro-paro lawọn oju popo da lasiko to yẹki iwọde naa waye.

Ni ẹnu ọna abawọle ọgba fasiti Ibadan, ta gbọ pe awọn oluwọde ọhun yoo ti gbera, se ni awọn agbofinro ji de adugbo naa, ti wn si duro wa wa wa sibẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Koda, aago meje ko tii lu, ti wọn fi gunwa si ibẹ ni aarọ ọjọ Aje, bẹẹ ni eegun awọn oluwọde kankan ko sẹ titi di ọwọ iyalẹta ti akọroyin wa fi iwaju fasiti Ibadan naa silẹ.

Awọn ọlọpaaa duro si iwaju ọgba fasiti Ibadan

Bakan naa si ni ọmọ sori lawọn adugbo miran ti ijadugu ti maa n waye nilu Ibadan.

Ladugbo Iwo road, Challenge, Ọjọọ, Bẹẹrẹ, Mọlete, Ọja ọba, Gate ati Sango, ko si ẹni to kofiri pe iwọde kankan n waye nibẹ bi o tilẹ jẹ pe awọn agbofinro ti gbarodan sawọn agbegbe yii, ti oju wọn ko si srẹrin rara.

Awọn ọlọpaaa duro si iwaju ọgba fasiti Ibadan

Lọwọ bayii, ohun gbogbo n lọ leto-leto nilu Ibadan, ti ọfọn kankan ko si fi iru na igba.

Ọlọpaa mu orin sẹnu lasiko ti awọn oluwọde fẹsẹ fẹ tori afẹfẹ́ alata

Se ni awọn ọlọpaa fi orin sẹnu nilu Eko lasiko ti wọn n wo awọn oluwọde ti wọn n sa asala fun ẹmi wọn lasiko iwọde Revolution Now ti wọn n se.

Awọn ọlọpaa naa, ti wọn ti kọkọ yin afẹfẹ tajutaju, ti ko ran awọn oluwọde naa, lo tun bẹrẹ si ni yin afẹfẹ alata si wọn.

Asiko yii ni awọn oluwọde naa to mọ isẹlẹ yii lọran, ti wọn si yan lai duro gba ọbẹ.

Ọlọpa kan n yin afẹfẹ alata

Bi wọn se n sare lọ kijokijo, lo pa awọn agbofinro yii lẹrin, ti awọn naa si mu orin sẹnu pe awọn rẹyin awọn alagidi.

Ọpọ eeyan to wa ladugbo ti awọn iwọde naa ti n waye lo fara gba ninu afẹfẹ tajutaju naa, ti wọn si n nu omije loju.

Ọrọ di boo lọ, ko ya fun mi nibi iwọde l’Eko

Àwọn ọlọpaa ti fi afẹfẹ taju-taju tu awọn olufẹhonuhan Revolution Now ka nipinlẹ Eko.

Nibi iwọde naa to waye ni agbagbe Surulere/Ojuẹlẹgba ni eyi ti waye.

Ni owurọ kutu ọjọ Aje ni awọn olofẹhonu han naa tu jade sita, lati polongo pe ki ijọba orilẹede Naijiria wa nkan ṣe si eto aabo ati ọrọ aje to mẹhẹ.

Awọn ọlọpaaa yin afẹfẹ taju-taju

Akọroyin BBC jabọ pe 'saaju ki awọn ọlọpaa o to yin afẹfẹ taju-taju si afẹfẹ ni wsn ti kọkọ kilọ fun awọn to n fi ẹhonu han pe ki wọn o tuka.

Ẹ wo bi iwọde naa ṣe n lọ.

Amọ, nigba ti wọn ko gbọran si aṣẹ naa ni "ọkan lara wọn ṣẹwọ si awọn yooku rẹ, loju ẹsẹ naa si ni wsn bẹrẹ si ni yin afẹfẹ oloro naa.

Ọlọpaa mu oluwọde kan

Bakan naa ni akọroyin wa sọ pe awọn ọlọpaa mu diẹ lara awọn to n fi ẹhonu ha, wọn ko wọn sinu ọkọ́, wọn si gbe wọn lọ.