Eid-el Kabir: Saudi ṣàtúnṣe lílẹ òkò mọ́ Asitani láti dẹ́kun títẹra-ẹni-pa

Oríṣun àwòrán, Twitter/Nigeria Hajj Comm
Awọn alaṣẹ orilẹede Saudi Arabia ti ṣe atunṣe lilẹ oko mọ Asitani mẹta ni Muna lọkọ keji tawọn oniṣẹ Haji ba goke Arafat.
Wọn ti ṣagbekalẹ ẹrọ kan eleyi ti yoo dena titẹ ara ẹni nibi ti wọn ti ju oko mọ Asitani bẹrẹ lati ọdun 2019.
Aṣoju ajọ to n ri si eto Haji ni Naijiria, Dokita Tanko Aliyu lo fọrọ naa lede niluu Muna.
Igbesẹ yii wa lara itọpinpin lati rii wi pe eto jiju oko mọ Asitani ti yoo waye lọjọ kẹwaa Oṣu kẹjọ lọ ni irọwọ rọsẹ.
Bakan naa, atunṣe yii waye nitori ọpọ ẹmi lo ti sun nigba tawọn oniṣẹ Haji n lẹ oko mọ Asitani fu ọpọlọpọ ọdun.
Dokita Aliyu rọ awọn ọmọ Naijiria ti wọn ni Haji lati ran ara wọn leti iṣepataki titẹle atunṣe tuntun nigba ti asiko ba to lati lẹ oko mọ Asitani lọjọ kẹwaa oṣu kẹjọ.
O ṣalaye pe ni isọri isọri lawọn to n ṣiṣẹ Haji yoo maa lọ sibi ti wọn yoo ti lẹko mọ Asitani lati le dena titẹ ara ẹni pa.









