Oyo SUBEB: Ayédèrú ní ìròyìn tó ní à ń gba ènìyàn sísẹ́

Olukọ n kọ awọn akẹkọ ni kilaasi

Oríṣun àwòrán, Ministry of information, Oyo

Ajọ to n risi eto ẹkọ ni ipinlẹ Ọyo, Oyo SUBEB ti n se iwadii lori awọn to gbe iroyin ayederu jade pe ijọba ipinlẹ Ọyọ n gba awọn olukọ sisẹ.

Alaga ajọ Oyo SUBEB, Dokita Nureni Aderemi Adeniran lo sọ eyi ninu atẹjade kan ti wọn fi lede ni ipinlẹ naa.

Adeniran ni irọ patapata ni wi pe, awọn n gba eniyan si isẹ ni ipinlẹ naa, nitori naa ki awon araalu mase jẹ ki wọn lu wọn ni jibiti owo, lasiko ti wọn ba n wa isẹ.

Adeniran wa kilọ fun awọn ara ilu wi pe, awon n sa ipa lati mu awọn to gbe iroyin ẹlẹjẹ yii ni ori ẹrọ ayelujara, ki awọn lee fi wọn jofin ijọba.

Alaga ajọ Oyo SUBEB naa wa parọwa si awọn to n wa isẹ lati farabalẹ, ki wọn ma ba a lugbadi awọn onijibiti.