Sowore Revolution Now: Nǹkan tó yẹ kí o mọ̀ nípà Omoyele Sowore tó ń ṣe agbátẹrù ìfẹ̀hónú hàn jákèjádo Nàìjíríà

Oríṣun àwòrán, Omoyele Sowore
Ní kété ti àwọn ọmọ Naijiria jí lónìí, ọjọ karun oṣù kẹjọ ní wọ́n ri pe ìwóde ìfẹhonuhan lóri ètò ìjọba ti kò lọ botitọ tí Omoyele Sowore ń se agbátẹru rẹ wáye ní tootọ lẹ́yìn tí wọ́n ti fí àgbétẹru rẹ̀ si àtìmọlé láti ọjọ sátide to kọja.
Lóòtọ́ọ́ ní ilé iṣẹ́ ọlọpàá ọtẹlẹ̀múyẹ tí mú Sowore sí àhámọ nítori pé wọ́n mí ò ń dún ìkokò mọ aláfíà, àtí ìbágbépọ̀ àrà-ẹni tó ń jọba lórilẹ̀-èdè Nàìjíríà
Since wey dem arrest Sowore, na so many ogbonge Nigerians dey condemn di move, some don say di protest must go on, but who be dis man wey dey dinger Revolution Now across Nigeria?
- Ìwọ́de #RevolutionNow forí ṣánpọ́n ní Ibadan, àgbófinró gbàkóso ojú pópó
- 'Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Ezekwesili kò le ṣẹlẹ̀ sí mi' #BBCNigeria2019
- Ìjọba pàṣán ni ìjọba Buhari yóò jẹ́ fún Nàìjíríà ní sáà kejì- Ṣoworẹ
- Sowore: olùdíje Ààrẹ tó fẹ gbà Nàìjíríà padà fún àwọn ọdọ
- Ó tó gẹ́ẹ́! Àsìkò tó láti fi ìwọ́de gba ara wa sílẹ̀ lọ́wọ́ ebi àti oko ẹrú - Sowore
Lati ìgbà ti wọ́n ti fi Soworẹ sí àhàmọ, ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ Nàìjíríà ló ti bu énu àtẹ́ lu ìgbéṣẹ̀ ìjóba Nàijiria, bẹ́ẹ̀ ni àwọn kan ni dandan ìwọ́de náà gbọdọ wáyé. Sùgbọ́n taa ni Omoyele Sowore ga-an?
Content is not available
View content on FacebookBBC kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó wà ní àwọn ojú òpó tí ó wà ní ìta.End of Facebook post, 1
Omoyele Sowore rèé
- Omoyele Sowore, kìí ṣe màjesìn, ó si ti pẹ nínú ìjìjagbàra, láti June 12 1993 ní ó ti máá ń gbarùkù ti ọ̀rọ̀ orílẹ̀-èdè Nàìjíría
- O jẹ́ ọmọ bíbí ilẹ̀ Ilaje ni ìpínlẹ̀ Ondo.
- A bíi ní ọjọ kẹtadínlogun oṣù keji, ọdun 1971, ó jẹ ajàfẹ́tọ ọmọniyan, pàápàá jùlọ ìjọba awa-ara wa.
- Oun ní olùdásílẹ̀ ilé iṣẹ́ ìròyìn ti a mọ si Sahara Reporter tó bẹ̀rẹ́ ní ọdún 2006 nínú yara kékere kan ni Manhattan ni ilẹ̀ Amerika.
- O gba oyè nínú ààto ilú àti ètò bí aye se rí (Geography and Regional Planning) ní fásìti Eko, 1989 si 1995 sùgbọ́n ó ni ìdáduro ọdún meji nítori ìwà nítori ìwá Aluta.
- O dí ààrẹ awọn akẹ́kọ̀ọ́ Fasiti Eko láàrin 1992 si 1995 tí ó sì dári ìwóde ìfẹ̀honúhàn nla kan lodi si ìjọba ologun lẹ́yìn to ti wọ́n wagile June 12, lọdun 1993 ìdìbo, ààrẹ bákan náà lo koju ija sí ijọba lori ìwà ajẹbanú
- He also get Master's Degree (Public Administration) from Colombia University.
- Bakan naa lo gba ìwé ẹ̀rí ẹlẹ́kẹẹji nínú ìmọ ìsejoba láti Fasiti Colombia
- E become Presidential Candidate of di African Action Congress during di February 2019 Presidential election for Nigeria.
- O jẹ olùdije dupo àarẹ lábẹ̀ àsìá African Action Congress lasiko ìdìbò ọdun 2019 ní Nàìjíríà
Content is not available
View content on FacebookBBC kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó wà ní àwọn ojú òpó tí ó wà ní ìta.End of Facebook post, 2
Sowore jẹ́ ọmọ Naijiria tó ti lo ọdun marundinlogun láti maa gbaruku ti ẹ̀tọ́ ọmọniyan àti ètò ìṣèjọba awa arawa ní Naojiria, bákan náà lo dá isejọba ologun dúro àti gbogbo ìwà àitọ ti àwọn ilé epo rọọbi pẹ̀lú gbogbo ǹkan ti wọ́n se
Ní ọdun 1989, Sowore wode pe "a o ni gbà" láti bẹnu àtẹ lu ìwà àìtọ to wáye ninu ẹyáwo IMF kan to to ọgọfà miliọnu dọla ti ìjọba fẹ lò fún kíkọ ojú ọpá epo, sùgbọ́n àsírí to wà nibẹ ni pé ẹyáwo náà yóò mú àwọn fasiti Nàìjíríà dín láti mẹ́jidinlọgbọ̀n sí marun pere.
Ní ọdun 1992 lásìkò tó wà Fasiti, o sááju àwọn akẹ́ẹ̀kọ́ ẹgbẹ́run mẹ́jì nínú ìwọde ìfẹ́honuhan lodi si ìjọba Naijiria àti àwọn asíwájú tí wọ́n ń wuwa ajẹbanu. Ọlọpàá yìbọn ti wan si pa ènìyàn méje ti wan si ti Sowore móle lori ọ̀rọ̀ náà, sùgbọ́n síbẹ̀ kò dẹyin lẹ́yìn ìfẹhonuhan láti jajagbara fún ètò ẹkọ́ to yanranti lórilẹ̀-èdè Naijiria
Sáaju ni ọdun 2018 Sowore, se agbekalẹ ìpolongo ààrẹ pẹ̀lú "Our Mumu don do" èyí tó fi sàlayé pé ọ̀pọ́ ọ̀dọ́ ni Naijiria ti yọwọ́ kuro nínú ètò ìjọba
Ẹ̀ẹ̀mẹjọ ọtọọtọ ni ó ti wọ ẹwọn lóri ọ̀rọ̀ ìwọde ìfẹ́honuhan ni Naijiria.















