Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá: Irọ́ ni kìí ṣe èèsì, ẹ mọ̀ pé ọlọ́pàá ni wọ́n, kẹ tó yìnbọn

Buhari

Oríṣun àwòrán, Alamy

Àkọlé àwòrán, Ileesẹ ologun ati ọlọpaa ti n tako ra lori idi tawọ̀n ologun se yinbọn pa ọlọpa mẹta ati araalu kan lasiko ti wọn gbe gbajumọ ajinigbe kan.
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Aarẹ Muhammadu Buhari ti pa asẹ fun olu-ile isẹ ọmọogun lorilẹede Naijiria lati bere iwadii lori isẹlẹ to mu ẹmi ọlọpaa mẹta lọ.

Oluranlọwọ Aarẹ Muhammadu Buhari lori ọrọ iroyin, Bashir Ahmad lo fi lede lori ẹrọ ikansiraẹni Twitter rẹ.

Aarẹ Buhari ni ibanujẹ lo jẹ fun oun pe ẹmi awọn akọgun to lọ lẹnu isẹ nitori naa lo se pe fun iwadii lẹsẹkẹsẹ lori isẹlẹ naa.

Isẹlẹ naa ni se pẹlu ikọ ọmọogun 93 Battalion ni ilu Takum, ni ipinlẹ Taraba.

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 1

Ileesẹ ologun ati ọlọpaa ti n tako ra lori idi tawọ̀n ologun se yinbọn pa ọlọpa mẹta ati araalu kan lasiko ti wọn gbe gbajumọ ajinigbe kan.

A kò mọ̀ọ́mọ̀ pa ọlọ́pàá mẹ́ta, aráàlú kan, ó ṣèèsì ni, ajínigbé la pè wọ́n - Iléeṣẹ́ ológun

Ileeṣẹ ologun Naijiria ti sọ pe awọn ọmọ ogun oun ko mọọmọ yinbọn pa awọn ọlọpaa ati araalu to ku ní ìpinlẹ Taraba.

Adele Oludari ẹka ibaṣepọ araalu nileeṣẹ ologun Ọgagun Sagir Musa, lasiko to n fesi si atẹjade kan lati ileeṣẹ ọlọpaa pe, salaye pe awọn ọmọogun lo gba ipe lati wa doola ẹnikan ti awọn ajinigbe ji gbe, loju ọna Ibi-Wukari nipinlẹ Taraba.

Musa ṣalaye wi pe, awọn bẹrẹ si ni le ọkọ 'awọn afurasi ajinigbe' naa nitori wọn kọ lati duro ni ibudo ayẹwo mẹta, ti awọn ọmọ ogun ti da wọn duro.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

"Asiko ti awọn ọmọ ogun n le wọn yii ni awọn afurasi naa bẹrẹ si ni yinbọn si awọn ọmọ ogun, eyi to mu ki awọn naa da a pada fun wọn.

Lasiko naa ni ibọn pa ‘afurasi’ mẹrin loju ẹsẹ, ninu eyi ti ọlọpaa mẹta ati araalu kan wa, ti awọn mẹrin miran si fara gba ọgbẹ ibọn, awọn meji mii si di awati."

"Lẹyin eyi ni ọkan lara awọn ọlọpaa to fi ara pa ṣẹṣẹ sọ pe ọlọpaa ni awọn, ati pe, lati olu ileeṣẹ ọlọpaa l'Abuja ni wọn ti ran awọn niṣẹ ikọkọ naa lati lọ gbe balogun ikọ ajinigbe kan."

Awọn ologun ilẹ wa

Oríṣun àwòrán, @HQNigerianArmy

Ileeṣẹ ologun sọ pe, o yẹ ki ileeṣẹ ọlọpaa maa fi to awọn leti to ba fẹ ṣe iru iṣẹ ikọkọ bẹẹ, nitori pe afojusun kan naa ni awọn jọ ni lati fi opin si awọn iwa ọdaran bi ijinigbe, ati awọn ipenija eto aabo miran ni Naijiria, lati le dena iru iṣẹlẹ bẹ ẹ.

Ṣugbọn ileeṣẹ ọlọpaa sọ pe, awọn ọmọ ogun naa tu ogbontagi balogun ajinigbe kan, Alhaji Hamisu silẹ ni ipinlẹ Taraba, to si salọ lẹyin ti wọn yinbọn pa mẹta lara awọn ọlọpaa to n gbe e lọ si olu ileeṣẹ ọlọpaa, ati araalu kan.

Awọn ọlọpaa ilẹ wa

Oríṣun àwòrán, @NPF_NIGERIA

Ileeṣẹ ọlọpaa sọ loju opo Twitter rẹ pe "awọn ọmọ ogun yinbọn laimọye igba mọ awọn ọlọpaa naa, botilẹ jẹ pe o fojuhan pe ọlọpaa ni wọn, ti wọn si wa lẹnu iṣẹ ilu.

Skip X post, 2
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 2

"O ti pẹ ti ileeṣẹ ọlọpaa ti n wa Hamisu fun ijinigbe l'oriṣiriṣi to ti waye lati ọwọ rẹ. Eyi to ṣe kẹyin ni ti oniṣowo epo ti wọn jigbe, ti wọn si gba ọgọrun miliọnu Naira, ki wọn to tu u silẹ."

Ni bayii, ileeṣẹ ọlọpaa sọ pe iwadii ti n lọ lori nkan to fa iṣẹlẹ iṣekupani ọhun.