Busola Dakolo: Ẹ̀sùn tí mo fi kan pásítọ̀ ìjọ COZA ṣì dúró digbí

busola dakolo

Oríṣun àwòrán, Busola dakolo

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Busola Dakolo sọ fun BBC lọsan Ọjọru pe oun ko tọwọ bọ iwe kankan to tako ẹsun ifipabanilopọ to fi kan Pasitọ agba ijọ Commonwealth of Zian Assembly, Biodun Fatoyinbo.

Ṣaaju ni iwe iroyin UK Guardian fi iroyin sita pe awọn fi ọrọ wa Busola lẹnu wo, o si sọ fun awọn pe awọn ọlọpaa to di ihamọra nkan ijagun fi ipa mu oun tibọn-tibọn lati fi ọwọ si iwe kan ti wọn kọ oriṣiriṣi nkan to le jẹ ẹri pe irọ ni gbogbo ẹsun to fi kan Fatoyinbo si.

Iwe iroyin UK Guardian jabọ pe Dakolo ṣalaye pe ọlọpaa kan gbe ibọn dani, ti ikeji si ni ki oun tọwọ bọ iwe ti wọn lo wa lati ọdọ ọga agba ọlọpaa.

''Ọkan ninu wọn mu ibọn dani ti mo si ri wi pe ẹni keji mu iwe kan lọwọ. Wọn sọ fun mi pe lati ọdọ ọga agba ọlọpaa ni Abuja lawọn ti wa, ti wọn si ni mo ni lati buwọ lu iwe tawọn mu wa.''

Nile Busola Dakolo ati ọkọ rẹ Timi nilu Eko ni wọn ni iṣẹlẹ yi ti waye.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Arabinrin Dakolo sọ pe ọsẹ bi i meji sẹyin ni oun ṣe ifọrọwanilẹnuwo naa pẹlu UK Guardian.

O fi idi rẹ mulẹ lori Instagram pe irọ ni iroyin to n lọ kaakiri igboro pe oun fi ọwọ si iwe naa. O sọ pe ẹjọ ti oun pe sọdọ awọn ọlọpaa ṣi n tẹsiwaju.

Skip Instagram post
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of Instagram post