Ogun Flood: Wákàtí méjìdínlógún ni òjò fi rọ̀ èyí tó mú ẹ̀kún omi lọ́wọ́

Ile to dawo

Ọwọja omiyale, agbara ya sọọbu to n waye nipinlẹ Ogun, ti mu ki ijọba ipinlẹ naa kede pe oun yoo wo ile kile to ba wa loju agbara ati ojusan omi lati dena ijamba ẹkun omi.

Ikilọ ti ijọba fi sita yii ko sẹyin ojo oniwakati mejidinlogun to ṣọsẹ nipinlẹ naa lopin ọsẹ.

Kọmisana feto ayika, Abiodun Abudu Balogun lo fidi ọrọ yii mulẹ, lasiko to n se abẹwọ sawọn agbegbe kan to farakasa isẹlẹ yii lọjọ Aiku ni ilu Abeokuta.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ojo arọrọda yii ṣe akoba fun ọpọ dukia ti ogunlọgọ awọn eeyan si di alainile lori nitori rẹ.

Omi ti omi wọnu rẹ

Abudu Balogun, to kọwọrin pẹlu akẹẹgbẹ rẹ ni ẹka to n seto aato ilu ati idagbasoke, Tunji Odunlami, tun ṣabẹwo si awọn agbegbe bi Ijeja, Ijeun Titun, Gbangba, Odo-Eran, Isale-Oja Kuto, Sokori ati Ago-Ijesa .

O wa sapejuwe iwa dida idọti soju agbara bii ohun to n ṣe n akoba fun sisan omi ni irọwọrọsẹ.

O ni bi kii se pe ijọba la oju ọna fun omi lati gba, akoba to sẹlẹ yii ko ba ju bẹẹ lọ.

''Gẹgẹ bi ijọba, a ṣetan lati gbe igbesẹ ti yoo mu ki awọn ara ilu tẹle ofin to de ayika wa, inu wa dun pe ko si ẹmi kankan to ba iṣẹlẹ yi lọ.

ẹ̀kún omi

Oríṣun àwòrán, Others

Àkọlé àwòrán, Ìpínlẹ̀ Ogun, Eko ti késí aráàlù láti pa òfin ìmọ́tótó mọ́!

A o ri wi pe a ṣe atunṣe lati dena iru isẹlẹ bayii lọjọ iwaju''.

Lọdọọdun ni omiyale agbara ya ṣọọbu ma n ṣe akoba ni ipinlẹ Ogun.

Lọdun yii, iroyin to n jade lati ọdọ ileeṣẹ to n risi bi oju ọjọ ti se ri sọ pe ojo yoo rọ gan, ti yoo si mu ki ipinlẹ Ogun ati awọn ipinlẹ to yika foju ba omiyale.

Ìpínlẹ̀ Ogun, Eko ti gbáradì fún ẹ̀kún omi yalé

Ijọba ipinlẹ Eko ti kesi awọn ara ilu lati sa ipa wọn lórí imọtoto lasiko ojo yii lati dẹkun omiyale-agbara ya sọọbu.

Igbakeji Agbẹnusọ fun gomina ipinlẹ Eko, Gboyega Akosile lo sọ eyi lasiko to n ba BBC Yoruba sọro lori igbese ijọba lati ri wi pe ko si ẹkun omi ni ipinlẹ Eko.

Akosile ni ijọba ati ile isẹ to n risi imọtoto oju agbara ni ipinlẹ Eko ti gbe orisirisi àlakalẹ, lati ri dáju wi pe, omi ri aye koja bi o se yẹ.

Igbakeji Agbẹnusọ fun gomina ipinlẹ Eko ni o ni awọn ti ko gbogbo oju -agbara ni ipinlẹ Eko, nitori naa o da awọn loju wi pe ẹkun omi ko le e waye ni ipinlẹ Eko.

Banki apapọ Naijiria(CBN) yoo ran ipinlẹ Ogun lọwọ lati gbogun ti omiyale

Agbẹnusọ fun ipinlẹ Ogun, Kunle Somori ni ijọba n sa gbogbo ipa wọn lati ri wi pe omiyale ko sẹlẹ ni ipinlẹ Ogun lasiko yii.

Somori ni ijọba ti kesi banki apapọ(CBN) lati ri wi pe wọn ran awọn lọwọ lati la awọn ọna ti omi nla kọja.

Àkọlé fídíò, Omiyale Ile Ife: Dukia sọfọ, awọn eniyan si tun farapa

O fikun wi pe awọn n kaakiri lati se idanilẹkọ ati ilanilọyẹ fun awọn ara ilu lori ibi ti ko yẹ ki wọn kọ ile si ati lori ibi ti ko yẹ ki wọn ma a da ilẹ si ki omiyale ma ba a waye ni ipinlẹ naa.

Ijọba ipinlẹ Ogun wa parọwa si awọn ara ilu lati ri wi pe wọn ko di oju omi lọwọ, ki omi le ma a ri aye lati ma a kọja, nitori irọrun igi ni irọrun ẹyẹ.

Àkọlé fídíò, È gbọ òun ti ojú awọn ara ipinle Ogun rí lọwọ ìṣẹlẹ omiyale