Revolution Now: Iléejọ́ ní àjọ DSS kò láṣẹ láti ti Sowore mọ́lé ju ọjọ́ 45 lọ

Omoyele Sowore

Oríṣun àwòrán, @YeleSowore

Ileẹjọ giga ijọba apapọ to wa nilu Abuja ti pasẹ fun ajọ ọtẹlẹmuyẹ ilẹ wa pe ko gbọdọ fi asaaju ikọ to n se iwọde Revolution Now, Omoyele Sowore, si ahamọ kọja ọjọ marundinlaadọta lọ.

Omoyele Sowore ni awọn osisẹ ajọ ọtẹlẹmuyẹ mu si ahamọ wọn lọjọ Satide to kọja saaju iwọde ẹgbẹ Revolution Now to waye lọjọ Aje, ti wọn si tun gba ile ẹjọ lọ pe awọn fẹ gba asẹ lati fi asaaju ikọ oluwọde naa si ahamọ fun aadọrun ọjọ, tii se osu mẹta gbako.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Amọ lasiko to n gbe idajọ rẹ kalẹ lori ẹjọ kanmọ n kia ti ajọ ọtẹlẹmuyẹ naa pe, Adajọ Taiwo Taiwo salaye pe ajọ agbofinro naa lee pada wa beere afikun ọjọ to fẹ fi fi Sowore si ahamọ rẹ, lẹyin asẹ ọjọ marundinlaadọta ti oun pa fun.

Adajọ Taiwo ni oun fun ajọ DSS lasẹ lati fi Sowore si ahamọ ko fi pari iwadi rẹ to n se ni nitori ajọ naa nilo akoko si lati fi ẹnu iwadi rẹ jona.

Awọn agbẹjọro to wa nile ẹjọ

Nibi igbẹjọ naa ni ajọ DSS ti se afihan awọn fidio gẹgẹ bii ẹri to n se afihan pe Sowore lọ se ipade pẹlu olori ikọ Biafra tijọba ti fofin de, Nnamdi Kanu, ati eyi to fi n parọwa si awọn ọmọ ẹgbẹ Shiite lati dara pọ mọ ikọ Revolution Now, ki wọn le doju ijọba ilẹ wa bolẹ.

Adajọ Taiwo ti wa sun igbẹjọ naa di ọjọ Kọkanlelogun osu Kẹsan ọdun 2019.