Ọlọ́pàá Eko: A ti fi Tekno sílẹ̀ àmọ́ ìwádìí sì ń lọ lọ́wọ́

Oríṣun àwòrán, Social media
Ileeṣẹ ọlọpaa ti fi ọrọ wa gbajugbaja akọrin takasufe, Augustine Kelechi, ti awọn eniyan mọ si Tekno lẹnu wo, lẹyin to rin kiri igboro ilu Eko ninu ọkọ kan pẹlu awọn obinrin to wa ni ihoho.
Fidio kan, to da bi ẹni pe lati inu ọkọ miran ni ẹni to ya a ti ya aworan naa, ṣafihan ọkunrin kan to joko sinu ọkọ akẹru naa, ti wọn fi gilaasi sẹ ara rẹ, to si n nawo fun awọn obinrin to n jo pẹlu awọtẹlẹ wọn nikan.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- "Mo fẹ́ pa ara mi torí ojú àbùkù tí wọn ń fi wò mí pé mo fi iṣẹ́ abẹ bímọ"
- Fulani kò leè dúró, táa bá lo ohun ta jogún lọ́dọ̀ àwọn bàbá wa - Sunday Igboho
- Ọjà Àgbáláta ní Badagry rèé, níbití ẹran ejò ti dùn ju ẹran adìẹ lọ
- Ọlọ́run yóò ṣe ìdájọ́ nkan tó wà láàrin èmi àti Ireti Ajanaku - Tope Alabi
- A kò jáde ṣe ìwọ́de ìtagbangba mọ́, inú ọkàn wa lá ti máa ṣe ìfẹ̀hónú hàn - Revolution Now
Tekno ti sọ pe fidio naa kii ṣe ipolowo fun ile faaji onihoho kankan.
O sọ pe, oun wa ninu apoti oni gilaasi ọhun ti wọn gbe sinu ọkọ akẹru, ti oun si n lọ lati ibikan si ibomiran lati ya fidio awo orin tuntun.

Oríṣun àwòrán, Tekno/instagram
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, Bala Elkana sọ fun BBC pe, awọn ọlọpaa bẹrẹ iwadii lẹyin ti fidio naa fa awuyewuye lori ayelujara.
Iroyin ti kọkọ jade pe, awọn ọlọpaa ti fi panpẹ gbe Tekno, ṣugbọn Ọgbẹni Elkana sọ pe, awọn kan pe e fun ifọrọwanilẹnuwo ni, ati pe fun ra a rẹ lo wa si agọ ọlọpaa lọjọ Iṣẹgun lati sọ tẹnu rẹ lori ọrọ naa.
Wayi o, Tekno tọrọ aforiji lori ayelujara Instagram, fun ẹnikẹni ti fidio naa ba bi ninu.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post
O ni "A n ya fidio awo orin lọwọ ni diẹ lara awọn ọkọ ayọkẹlẹ ti a n lo bajẹ, a si nilo ọkọ lati ko awọn eniyan lọ si ibomiran ti a ti fẹ lọ ṣiṣẹ, lo jẹ ka lo ọkọ to ni apoti oni gilaasi naa."
Ṣugbọn ko ṣalaye idi to fi n ju owo lu awọn obirnin naa lasiko ti wọn n rinrinajo.
Awọn ọlọpaa sọ pe, awọn ti yọnda Tekno, ṣugbọn iwadii ṣi n tẹsiwaju.












