Security: Ìpínlẹ̀ 9 yóò lo ẹ̀rọ ayàwòrán díróònù láti paná ìpèníjà ààbò

ẹ̀rọ ayàwòrán díróònù

Ẹ̀rọ ayàwòrán díróònù tó ń fò lójú ọ̀run

Oríṣun àwòrán, @CTAflash

Awọn ipinlẹ kọọkan to wa ni ilẹ Yoruba yoo bẹrẹ si ni lo ẹrọ ofurufuru ayaworan igbalode, taa mọ si Drone, lati ma a fi sọ agbeegbe wọn lọna ati gbogun ti eto aabo to denukọlẹ lorilẹede Naijiria.

Iwadii ti ile-isẹ iroyin Punch gbe jade sọ wi pe, ipinlẹ Eko, Osun, Ogun ati Ondo wa lara awọn ipinlẹ mẹsan, ti ko ni i pẹ ma a lo ẹrọ igbalode yii.

Lara awọn ipinlẹ naa ti yoo tun ni ipin ninu lilo ẹrọ Diroonu naa ni Kaduna, Anambra, Ebonyi, Benue ati Enugu.

Amọ iwadii naa fikun wi pe, ohun to n fa ifasẹyin diẹ nipa lilo ẹrọ diroonu ni iwadii finnifinni lati ọdọ ijọba apapọ, lori iwulo ohun elo naa ni awọn agbegbe to beere fun ‘drone’.

Awọn Fulani to n da ẹran

Ti a ko ba gbagbe, laipẹ yii ni Aarẹ Buhari se adehun pẹlu awọn ọba ni iwọ-oorun orilẹede Naijiria wi pe, oun yoo sa ipa oun lati ri wi pe awọn ipinlẹ yii tete ri ẹrọ drone gba, lati gbogun ti eto aabo to mẹhẹ.