Tiwa Savage tọwọ́ bọ'wé àdéhùn pẹ̀lú UMG fún òkìkí orin rẹ̀

Oríṣun àwòrán, Universal Music Group
Lónìí, ajọ awọn onigbọwọ orin to ga ju lagbaye (Universal Music Group) ti kede ajọṣepọ nla laarin wọn ati gbajugbaja olorin, Tiwa Savage.
Ilumọọka olorin nni, Tiwa Savage ni iroyin sọ pe oun ni obinrin akọkọ to ti gba ami ẹyẹ MTV EMA fun olorin ilẹ Afirika to dara ju.
Bakan naa, o ti ba awọn gbajugba olorin to lokiki kọrin kaakiri agbaye.
Tiwa jẹ ọkan lara awọn obinrin ilẹ Afirika to ni ọpọlọpọ ololufẹ orin rẹ to fẹrẹẹ́ to miliọnu meje lori itakun ayelujara.

Oríṣun àwòrán, Universal Music Group
Tiwa ni "afojusun mi to ga ju ni lati fi ilẹ Afirika yangan, nitori naa, inu mi dun gidi gan si ajọṣepọ yii mo si dupẹ lọwọ ẹbi tuntun ti mo wọ yii, UMG.
Tiwa ti di olorin to gbayii gan loke okun. Ninu oṣu kejila dun to kọja olorin Chris Martin yan an lati jọ kọrin pọ pẹlu gbajugbaja olorin Beyonce, Ed Sheeran ati Jay Z ni ilu Johannesburgh, South Africa niwaju ero to to miliọnu lọna aadọrin nigba ti wọn ṣe ayẹyẹ iranti ọjọ ibi oloogbe Nelson Mandella
O ti wa di ọ̀kan lara awọn agba akọrin Afrobeat l'Afirika pẹlu eyi to ti fun ara rẹ niyi lẹnu iṣẹ to yan laayo ati nilẹ Afirika gẹgẹ bi olorin, oniṣowo, akọni ati iyaleele.
Adam Granite to n bojuto ẹka idagbasoke katakara fun ajọ UMG, ni "a n foju sọna lati ni ajọṣepọ pẹlu Tiwa ati ikọ rẹ lati ran iṣẹ orin kikọ rẹ lọwọ ki o le tan ka gbogbo agbaye tori a rii pe Tiwa ni afojusun to dara".
Universal Music Group jẹ aṣaaju ninu oniruuru iṣẹ to rọ mọ orin kikọ. Latorii gbigbe orin sita, ṣiṣe alagbata orin kaakiri orilẹede to le lọgọta. Oriṣiriṣi ẹya orin ni wọn ma fi yan olorin ti wn yoo si baa gbe orin sita titi ti wọn yoo fi ṣe agbata rẹ kaakiri agbaye ati lati jẹ ki awọn to fẹran orin wọn tun ni iriri ọtun nipa wọn.














