Seyi Makinde: ₦60m ní mo gbé kalẹ̀ fún ìtọ́jú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ìmọ̀ òfin fún ọdún kan

Seyi Makinde

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde

Àkọlé àwòrán, ‘Ẹnikọ̀ọ̀kan nínú àwọn 120 ọmọ ìpínlẹ̀ Ọyọ tó ń kẹ́ẹ̀kọ́ ìmọ̀ òfin yóò gba N500,000’

Gomina Ipinlẹ Ọyọ, Seyi Makinde ti buwọlu owo to to ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta naira (₦500,000) bii owo iranwọ eto ẹkọ, fun akẹẹkọ kọọkan to wa lati ipinlẹ Ọyọ, ti wọn n kọ ẹkọ imọ nipa ofin ni ileewe imọ ofin(Law School).

Gomina Seyi Makinde lo sọ eyi lasiko to n gba awọn ọmọ ile-iwe imọ ofin naa lalejo ni ilu Ibadan.

Agbẹnusọ fun gomina feto iroyin, Ọgbẹni Taiwo Adisa lo ni gomina naa fi ọgọta miliọnu Naira silẹ lati fi tọju awọn ọmọ alaini lati ipinlẹ Ọyọ to n kẹkọ gboye imọ ofin ni saa ọdun 2019/2020.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Gomina Makinde ni oun gbe igbesẹ naa lati le se koriya fun awọn akẹkọ imọ ofin, ki wọn lee tẹra mọ iwe wọn fun aseyori to lamilaaka.

Seyi Makinde ni owo naa wa fun iranwọ, to si gba awọn akẹẹkọ imọ ofin naa ni imọran, lati ma se na owo ọhun ni inakuna.

Ọdún 2012 ni awọn akẹ́ẹ̀kọ́ ilé ìwé ìmọ̀ òfin tó wà láti ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ti gba N100,000 kẹ́hìn gẹ́gẹ́ bí owó ìrànwọ́.