Ilé ẹjọ́ pàṣẹ kí EFCC gbẹ̀sẹ̀ lé àpò àsùwọ̀n kan tó ní nkan ṣe pẹ̀lú Akinwumi Ambode

Ambode

Oríṣun àwòrán, Google

Ile ẹjọ giga ijọba apapọ to wa ni adugbo Ikoyi nilu Eko ti paṣẹ pe ki owo kan to to biliọnu mẹwa Naira, N9.9bn, to jẹ ti ijọba ipinlẹ Eko.

Onidajọ Chuka Obiozor paṣẹ naa lọjọ Aje lẹyin ti ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ ni Naijiria, EFCC, kọ iwe ẹbẹ si ile ẹjọ pe ko ṣe bẹ ki oun le ri aaye ṣe iwadi iwa jibiti kan.

EFCC sọ fun ile ẹjọ lati ti apo aṣuwọn naa titi ti wọn yoo fi pari iwadii kan ti wọn n ṣe. Iwadii naa ni wọn ni o ṣeesẹ ko yọri si ki wọn o fi oju akọwe agba lọọfisi Olori awọn oṣiṣẹ fun Gomina tẹlẹ, Akinwumi Ambode, Adewale Adesanya ba ile ẹjọ.

Gẹgẹ bi agbẹnusọ ajọ EFCC, Tony Orilade ṣe sọ, owo naa, N9,927,714,443.29, lo jade lati inu apo asuwọn ijọba ipinlẹ Eko, to si wọ apo asuwọn miran nile ifowopamọ FCMB kan ti wọn ṣi ni ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kẹsan, ọdun 2017 lasiko iṣakoso gomina ipinlẹ Eko tẹlẹ, Akinwumi Ambode.

Ninu iwe ti EFCC gbe lọ siwaju ile ẹjọ, o fojuhan bi Adesanya ati awọn kan to ni anfaani si apo asuwọn naa ṣe n gba owo jade ninu apo asuwọn ijọba ti wọn si n da a si apo asuwọn miran.

Agbẹjọro fun EFCC, Mohammed Abbas sọ nile ẹjọ pe "akọsilẹ fihan bi owo nlanla ṣe n wọ apo asuwọn ti Adesanya n mojuto lati inu aka-nti ijọba ipinlẹ Eko."

Abbas fi kun pe wọn ti n gbiyanju lati na owo naa, ati pe wọn ko ni i dẹkun iwa jibiti wọn ti ile ẹjọ ko ba gbẹsẹ le apo asuwọn naa.

Eyi lo mi ki Onidajọ Obiozor gba ẹbẹ EFCC wọle, to si sun igbẹjọ si ọjọ kẹsan, oṣu Kẹsan, ọdun 2019.