Hushpuppi: Ó di ẹlẹ́wọ̀n tó ní nọ́ńbà l‘Amẹrika, orúkọ̀ rẹ̀ wà lórí ayélujára

Hushpuppi in Jail: Ramon Olorunwa Abbas dey Federal Bureau of Prisons wey be Prison in Chicago, Illinois USA

Oríṣun àwòrán, Hushpuppy/SCREENSHOT/BOP.GOV

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Iroyin tuntun ti ileeṣẹ ọgba ẹwọn l'orilẹ-ede Amẹrika, fi sita nipa ọmọ orilẹ-ede Naijiria, Hushpuppi ni pe, o ti wa ni ọgba ẹwọn nilu Chicago, Illinois.

Ọwọ ọlọpaa ilu Dubai tẹ Ramoni Olorunwa Abbas, ti inagijẹ rẹ n jẹ Hushpuppi, laipẹ yii, fun ẹsun lilu jibiti lori ayelujara.

Lẹyin naa ni wọn fi ranṣẹ si orilẹ-ede Amẹrika.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Alẹ ọjọ Aje si ni ileeṣẹ ọgba ẹwọn fi orukọ Hushpuppi si ori itakun agbaye wọn.

Koda, wọn ti fun Hushpuppi ni nọmba idanimọ l'ọgba ẹwọn, 54313-424, eyi ti yoo fun awọn eeyan l'anfaani lati ka nipa rẹ lori itakun agbaye naa.

Awọn nkan miran nipa rẹ to tun wa nibẹ ni, orukọ, ọjọ ori, ati ẹya rẹ.

Ọsẹ bi i melo kan si ni ileeṣẹ eto idajọ ilẹ Amerika yoo gbe ẹni ọdun mẹtadinlogoji ọhun lọ si ilu Los Angeles, lati jẹjọ lori ẹsun lilu jibiti.

Hushpuppi arrest video: Federal Bureau of Prisons - Prison in Chicago, Illinois USA

Oríṣun àwòrán, BBC/SCREENSHOT/BOP.GOV

Bi ọwọ ọlọpaa ṣe tẹ Hushpuppi, ati Lekan Ponle AKA Woodberry, ti wọn si gbe wọn lọ si orilẹ-ede Amẹrika, fa ariyanjiyan lori ayelujara.

Eeyan mẹwa miran ni awọn ọlọpaa ilu Dubai, ko pọ mọ Hushpuppi ati Woodberry, ninu akanṣe iṣẹ kan ti wọn pe ni 'Fox Hunt 2'.

Ẹsun lilu jibiti, kiko owo pamọ lọna aitọ, jija banki lole, fifi ara ẹni pe ẹlomiran, ni wọn fi kan wọn.

Lasiko ti awọn ọlọpaa mu Hushpuppi, ọwọ wọn tẹ awọn iwe akọsilẹ nipa jibiti kan, ti owo rẹ to ojilenirinwo din maarun miliọnu Dọla, t'oun n murasilẹ fun.

Ẹsun iluni ni jibiti ori ayelujara ni wọn fi kan an

Oríṣun àwòrán, Hushpuppi Instagram

Bakan naa ni wọn tun gba awọn nkan yii lọwọ rẹ:

  • Owo to le ni $40.9 miliọnu
  • Ọkọ ayọkẹlẹ bọginni mẹtala
  • Ẹrọ ayara bi aṣa mọkanlelogun
  • Ẹrọ ibanisọrọ alagbeka mẹtadinlaadọta, ati awọn nkan miran
  • Iye eeyan ti wọn lo ti lu ni jibiti ku diẹ ko pe miliọnu meji (1,926,400).

Hushpuppi: APC ní kìí ṣe ojú lásán ni afurasí gbájúẹ̀ náà fi sún mọ́ olóṣèlú

Yoruba ni fi ọrẹ rẹ han mi, ki n le sọ iru eeyan to jẹ nitori agutan to ba n ba aja rin, yoo jẹ igbẹ.

Eyi lo mu ki igbakeji akọwe alukoro fẹgbẹ oselu APC, Yekeen Nabena se fi atẹjade kan sita pe ki ajọ EFCC tete bẹrẹ lori ọrọ Hushpuppi.

Nabena ni ajọsepọ awọn asaaju kan ninu ẹgbẹ oselu alatako, PDP pẹlu ilumọọka afurasi gbajuẹ, Ramon Olorunwa Abass, Hushpuppi mu ifura lọwọ.

Hushpuppi, Dino Melaye ati eeyan meji mii

Oríṣun àwòrán, @APCUKingdom

Nabena salaye pe ẹsun gbigbe owo ilu lọ sẹyin odi ti wọn fi n kan awọn eekan PDP naa ls silu Dubai lati ipasẹ Hushpuppi lo yẹ ki wọn tanna wadi rẹ.

O fikun pe, saaju eto idibo gbogbo gboo to kọja ni awọn asaaju ẹgbẹ PDP ti sọ Dubai di ibiti wọn n lọ loore koore, bẹẹ si ni bi Hushpuppi se sunmọ awọn oloselu naa kii se oju lasan.

Hushpuppi, Dino Melaye ati eeyan mii

Oríṣun àwòrán, @APCUKingdom

"Ni ọpọ igba ni ilumọọka afurasi gbajuẹ naa ti ya aworan pẹlu awọn eekan oloselu ninu ẹgbẹ PDP naa nilu Dubai nibi awọn ipade to waye saaju eto idibo 2019, ko si yẹ ka foju fo iru ajọsepọ to wa laarin wọn ati iru isẹ ti Hushpuppi n se fun wọn."

Bẹẹ ba gbagbe, laipẹ yii ni ọwọ awọn ọlọpaa Dubai tẹ Hushpuppi ati awọn akẹgbẹ rẹ kan ti wọn n lu awọn eeyan ni gbajuẹ lori ẹrọ ayelujara, to si ti farahan nile ẹjọ lorilẹ ede Amerika.

Hushpuppi

Oríṣun àwòrán, INSTAGRAM/HUSHPUPPI

Amọ aarẹ ana fun ile asofin agba ilẹ wa, Senatọ Bukola Saraki ti foju lai wo ikede ẹgbẹ oselu APC naa.

Akọwe iroyin fun Saraki, Yusuph Olaniyonu, ninu atẹjade kan to fisita salaye pe Bukola Saraki ko mọ Hushpuppi ri, bẹẹ ni ko ni ajọsepọ kankan pẹlu rẹ.

Saraki wa n naka aleebu si ẹgbẹ oselu APC pe oselu ẹtanu ati ibanilorukọ jẹ ni wọn n se pẹlu iwa lilu jibiti lori ayelujara, to si ni aimọye igba ni oun ti pe akiyesi ijọba si ipa ti ọrọ aje ilẹ wa to n se ojojo yoo ni lori awọn mẹkunnu.

Ẹ wo bí Hushpuppi ṣe farahàn nílé ẹjọ́ l'Amẹrika fún ìgbà àkọ́kọ́ láti jẹ́jọ́

Hushpuppi

Oríṣun àwòrán, HUSHPUPPI/INSTAGRAM

Saaju la ti mu iroyin wa fun yin pe Raymond Abass, ti gbogbo eeyan mọ si Hushpuppi, ti farahan nile ẹjọ nilẹ Amẹrika.

O n jẹjọ lori ẹsun pe o lẹdi apo pọ lati ko obitibiti miliọnu owo Dọla pamọ lọna aitọ.

Ileeṣẹ eto idajọ nilẹ Amẹrika si sọ lọjọ Ẹti pe oun yoo taari ọmọ orilẹ-ede Naijiria naa silu Los Angeles, lati lọ jẹjọ nibẹ.

Hushpuppi

Oríṣun àwòrán, INSTAGRAM/HUSHPUPPI

Ṣaaju ni ileesẹ ọtẹlẹmuyẹ ilẹ Amẹrika, FBI. sọ pe Ramoni Abbas Igbalode, ti gbogbo eeyan mọ si Hushpuppi gbiyanju lati ji miliọnu mẹrinlelọgọfa Dọla lati ara Premier League.

Inu atẹjade kan ti ajọ FBI fi sita lori ayelujara wọn lọjọ Ẹti ni wọn ti kede rẹ.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post

Ninu atẹjade naa, FBI sọ pe ẹsun kiko owo pamọ lọna aitọ, ni wọn fi kan an.

Wọn ni obitibiti miliọnu Dọla ni wọn sọ pe o ji lara awọn ileeṣẹ nipaṣẹ emeeli, ati awọn ọna miran.

Awọn eeyan to wa l'Amerika ti juwe iru igbẹjọ ti ileẹjọ a ṣe fun Hushpuppi a

Àkọlé fídíò, Yetunde Bakare dárà lórí ètò Ṣé o láyà, ẹ ràn án lọ́wọ́ nínú ìbéèrè tó ṣì

Nkan miran ti FBI tun sọ

Lara jibiti ti Hushpuppi ati awọn isọmọgbe rẹ tun gbiyanju lati ṣe ni jiji ọgọrun un miliọnu Euro (to jẹ miliọnu mẹrinlelọgọfa Dọla), lati ara ẹgbẹ agbabọọlu kan ninu idije Premier League.

Ṣugbọn ajọ naa ko sọ orukọ ẹgbẹ agbabọọlu to jẹ.

FBI sọ pe Abbas jẹ ọkan lara awọn olori ẹgbẹ onijibi ori ayelujara, to pa ẹka kaakiri agbaye, ati kiko owo pamọ lọna aitọ.

Wọn tun sọ ninu atẹjade naa pe Hushpuppi, ati awọn miran tun ja oníbàráà ileeṣẹ amofin kan nilu New York, lole $922,857 loṣu Kẹwa, ọdun 2019.

Wọn ni: "Hushpuppi ati awọn yooku rẹ lo ọgbọn ẹwẹ lati tan ẹka kan nilee amofin naa,

Wọn ni pe ki wọn o san owo kan ti ọkan lara awọn oníbàráà wọn fẹ ẹ fi ra ile si aṣunwọn banki kan ti oun ati awọn yooku rẹ n mojuto".

Àkọlé fídíò, Nikesuliat: Ọ̀dọ́mọdébìnrin akéwì tó n fi ẹ̀ṣà kìlọ̀ ìwá lásìkò yìí

Atẹjade naa tun sọ pe Hushpuppi lẹdi apo pọ mọ awọn kan lati ko $14.7, ti wọn ji lati ori ayelujara pamọ.

Banki kan ni wọn ja lole nilẹ okeere l'oṣu Keji, ọdun 2019.

Niṣe lo pin owo naa kelekele sinu asunwọn banki kaakiri agbaye.

Hushpuppi

Oríṣun àwòrán, INSTAGRAM/HUSHPUPPI

O si tun sowọpọ mọ ẹnikan to ni asunwọn meji nilẹ Yuroopu, pẹlu ireti pe ẹni kọọkan wọn yoo gba miliọnu marun un Pọun ($5.6 million), lara owo jibiti naa.

Hushpuppi ati awọn iyoku rẹ le lọ si ẹwọn to to ogun ọdun nilẹ Amẹrika, ti wọn ba fi le sọ pe wọn jẹbi awọn ẹsun naa nile ẹjọ.

Ileeṣẹ ọlọpaa nilu Dubai lo kọkọ mu Ramoni Igbalode(Hushpuppi), Olalekan Jacob Ponle (Woodberry), ati awọn miran.

Àkọlé fídíò, 'Èmi gan máa ń béèrè lọ́wọ́ ara mi pé ta ni Wole Soyinka gangan'

Lẹyin naa ni wọn fa wọn le ajọ FBI nilẹ Amẹrika lọwọ, lati lọ koju igbẹjọ lori ẹsun wọn fi kan wọn.

Ṣaaju ni ijọba United Arab Emirates kede pe oun ti fi afurasi gbajuẹ naa, ranṣẹ si ileesẹ ọtẹlẹmuyẹ ilẹ Amẹrika, FBI.

Ileeṣẹ ọlọpaa Dubai lo fi ikede ọrọ yii sita ninu atẹjade kan to fi si oju opo Twitter rẹ.

Labẹ iṣẹ iwadii akanṣe ọtẹlẹmuyẹ ti wọn pe ni ''Fox Hunt 2'', wọn mu awọn ọdaran kan to n pa awọn eeyan lẹkun jaye loju opo ayelujara, ti wọn si n lu awọn eeyan ni jibiti.

Ajọsepọ awọn ikọ ọlọpaa kogberegbe mẹfa lati ọdọ awọn ọlọpaa Dubai, lo tu asiri awọn ọdaran yii, bi wọn ti ṣe n gbero lati ji owo awọn eeyan kaakiri agbaye.

Aworan Olalekan Jacob Ponle ti awọn eeyan mọ si Woodberry

Oríṣun àwòrán, mrwoodberry/TWITTER

Àkọlé àwòrán, Olalekan Jacob Ponle ti awọn eeyan mọ si Woodberry ati Hushpuppi lọwọ awọn ọlọpaa Dubai tẹ

Oludari ileesẹ ọtẹlẹmuye FBI Christopher Wray wa kan sara si awọn ọlọpaa ilẹ Dubai, fun iṣẹ ribiribi ti wọn ṣe lati mu Raymond Igbalode Abbas, ti awọn eeyan mọ si "Hushpuppi" ati Olalekan Jacob Ponle, ti inagijẹ rẹ n jẹ "Woodberry".

Bẹẹ naa ni ọgbẹni Wray fẹmi imoore rẹ han si ileeṣẹ ọlọpaa Dubai, bi wọn ti se gba lati fi awọn ọdaran yii ranṣẹ si ọdọ awọn, ki wọn ba le kawọ pẹyin rojọ ẹṣẹ wọn.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Adari ikọ ọtẹlẹmuyẹ Dubai, ọgagun Jamal Salem Al Jallaf ni, awọn ri ẹri pe awọn ọdaran yii n gbimọran ọtẹ lati lu awọn eeyan ni gbajuẹ, ti iye owo rẹ to miliọnu lọna irinwo le marundinlogoji dọla.

Wọn tun sọ pe, awọn ri ogoji miliọnu dọla le diẹ gba lọwọ wọn pẹlu ọkọ ayọkẹlẹ mẹtala, ti iye owo wọn le ni miliọnu mẹfa dọla.

Bakan naa ni wọn tun gba ẹrọ kọmputa mọkanlelogun, foonu mẹtadinlaadọta ati awọn ẹrọ iko nkan pamọ si 'memory stick' ati 'hard drive', ti o kun fun adirẹsi awọn eeyan ti wọn fẹ lu ni jibiti.

Àkọlé fídíò, Oríṣí ìjìyà ní àwọn bíi Gómìnà El Rufai àti Fayemi ń bèèrè f'àwọn afipábánilòpọ̀