Ondo: Àwọn afurasí mẹ́rin ti wà ní àhámọ́ lórí ikú ọkùnrin kan ní Igbokoda - Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ondo

Awọn ọlọpaa nilu Ondo

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ariwo kilode, kilode, kilode lawọn eeyan agbegbe Zion ni ilu Igbọkọda ni ipinlẹ Ondo nigba ti awọn ọlọpaa wa wu oku arakunrin kan nibẹ

Awọn eeyan agbegbe naa nfunra pe o ṣeeṣe ko jẹ ọmọ ẹgbẹ okunkun ni arakunrin naa ati pe o ṣeeṣe ko jẹ pe lasiko wahala awọn ẹgbẹ okunkun kan ti wọn gbe ina woju ara wọn lopin ọsẹ to kọja ni ilu naa ni wọn ṣeku pa arakunrin ọhun.

Gẹgẹ bi iroyin agbegbe naa ṣe sọ, eeyan kan ku ti eeyan kan si fi ara ṣeṣe lasiko itakangọn awọn ẹlẹgbẹ okunkun naa.

Amọṣa nigba to n ba BBC News Yoruba sọrọ lori oku ti wọn lọ wu ninu saree naa, alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Ondo, DSP Teo-Leo Ikoro ni ọrs ko ri bẹẹ rara.

Amọṣa o ni lootọ lawọn wu oku naa ati pe iwadii n lọ lati mọ bi iku arakunrin naa ṣe ri.

Àkọlé fídíò, Ìtàn Olaniyi Balogun, ọ̀jọ̀gbọ́n tó fi Nàìjíríà sílẹ̀ lọ gba iṣẹ̀ àgbẹ̀ l'Ámẹ́ríkà

O ni ko ileeṣẹ ọlọpaa ko tii lee fi iroyin ti awọn eeyan kan n gbe kiri pe awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun lo da ẹmi oloogbe ọhun legbodo mulẹ.

Ikoro ṣalaye pe "Iwadii ṣi n lọ lọwọ lori iṣẹlẹ naa, bo tilẹ jẹ pe a ko tii le fidi rẹ mulẹ pe ọmọ ẹgbẹ okunkun ni ọkunrin naa tabi awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun lo ṣekupaa."

O tẹsiwaju pe "A ti mu awọn afurasi mẹrin kan lori ẹsun ipaniyan, ṣugbọn kii sẹ nitori pe wọn wa ninu ẹgb ẹ okunkun."

Ikoro pari ọrọ rẹ pe ko nnkan to jọ ija tabi ikọlu tawi ọwọ awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun ni ibi ti wọn ti ṣekupa oloogbe naa.