Abiola Ajimobi: Oríkì mẹ́jọ tí wọ́n fi ń pe Ajimọbi nígbà ayé rẹ̀

Oríṣun àwòrán, @Ajimobi
Oriṣii orukọ inagijẹ ni awọn eeyan fi maa n pe oloogbe Abiola Ajimobi nígba aye rẹ ni eyi to jẹ pe o n fi awọn iṣẹlẹ to ṣẹlẹ nigba naa.
Lọjọ Aiku, Ọjọ Kejidinlọgbọn, Oṣu Kẹfa, ọdun yii ni ara Sénetọ naa yoo wọ kaa ilẹ lọ.
Yoruba gbagbọ pe ile laa wo ki a to sọ ọmọ lorukọ, ohun to ba ṣẹlẹ ninu ẹbi ati lagboole lo maa n bi orukọ abisọ ti ọmọ a jẹ.
Orukọ inagijẹ ti ọmọ n jẹ tumọ si orukọ ti wọn dagba ba ti awọn eeyan fi n pe wọn gẹgẹ bii awomọ tabi to jade nipa ihuwasi tabi ọrọ ẹnu eeyan.
O ṣeeṣẹ ko dabi oruikọ apejẹ tabi orukọ ti o maa so mọ ọmọ lara lataari awọn iṣẹlẹ tabi iṣesi rẹ bo ṣe n dagba.
- A wà nínú igbó tí a ti ń wá àwọn arinrìnàjò mẹ́jọ láti Abuja sí Eko tí wọ́n jígbé lọ- Ọlọ́pàá Ondo
- Yàtọ̀ sí coronavirus, wo ìgbà mẹ́wàá míì táwọn mùsùlùmí kò lè ṣiṣẹ́ Hajj
- Wo bí o ṣe lè fí orúkọ rẹ sílẹ̀ fún iṣẹ́ N Power tuntun ti ọdún 2020
- Iré dé! MTN àti BBC World Service bẹ̀rẹ̀ àjọṣepọ̀ lórí ìròyìn ìṣẹ́jú kan BBC
Awọn orukọ Inagijẹ Ajimọbi:
1) Shehu:
Nigba kan ni Alhaji Abiola Ajimobi sọọ ninu awada lasiko to n pari saa rẹ akọkọ gẹgẹ bii gomina ipinlẹ Oyo pe orukọ tuntun ti awọn
eeyan yoo ma pe oun ni yẹn.
O ni ni kete ti oun ba ti pari iṣẹ ilu gẹgẹ bii gomina ipinlẹ Oyo ni oun yoo di aafa onimọ Keu ti gbogbo eeyan a maa pe ni 'Shehu'
O ṣeleri pe oun yoo maa yoo maa kọ awọn eeyan nipa aye ile aye asan gẹgẹ bii onimọ.
2) Ko ṣẹlẹ ri:
Oloogbe Ajimọbi ni gomina akọkọ ti yoo jẹ lẹẹmeji lati igba ti wọn ti da ipinlẹ Oyo silẹ.
Eyi ko ṣẹyin ọrọ adape ti wọn maa fi n yangan ni Ibadan pe, Ibadan eee sin eeyan ni ẹẹmeji.
Lẹyin to pari saa rẹ akọkọ lo tun dije lẹẹkeji to si tun wọle gẹgẹ bii gomina ipinlẹ Oyo.
Bakan naa ni o tun jẹ gomina ilẹ Yoruba akọkọ to maa fun Baalẹ mọkanlelogun ni Ade Ọba lọjọ kan ṣoṣo.
Eyi ati awọn iṣẹlẹ mii ti oloogbe Ajimọbi ṣe ni wọn fi n pe e ni apejẹ Abiola Ajimobi, Ko ṣẹlẹ ri ti ilẹ Ibadan.
3) Achipelago:
Eyi jẹ orukọ ẹ̀sà ti wọn maa fi n sa Abiola Ajimobi lati kekere nigba to wa nile iwe girama ti Lagelu Grammar School ni Ibadan.
O maa n kopa ninu ọpọlọpọ ere idaraya bii bọọlu alafẹsẹgba, bọọlu ẹlẹyin ori tabili ati ere sisa.
Awọn akẹgbẹ rẹ nile iwe Lagelu fẹran rẹ pupọ lori papa ati ninu awọn ere idaraya to pọ.
4) Pègúnrun:
Eyi tumọ si ọmọ to pa egun / epe run.
Oun ni Gomina akọkọ ti wọn ni o kọkọ bọ lọwọ egun ti awọn kan gbagbọ pe o n tẹle ọọfiisi gomina ni ipinlẹ Oyo.
Ajimọbi lo pa gbogbo egun, epe ati asọtẹlẹ gẹgẹ bi o ṣe rọ mọ igbagbọ awọn kan lati dije dupo gomina ipinlẹ Oyo ni ọpọ igba ti eeyan naa ko si le jẹẹ ju ẹẹkan lọ.
- Wo àwọn èèyaǹ jàǹkàn mérin tí àrùn Coronavirus ti sọ dèrò ọ̀run ní Naijiria
- Wo bí o ṣe lè di aṣojú tó ṣe pàtàkì nínú àjọ ìṣọ̀kan àgbáyé 'UN Goodwill Ambassador'
- Àwọn èèyàn ìpínlẹ́ Ondo kò gbàgbọ́ pé Coronavirus wà lọ jẹ́ kó máa pọ̀ síi - ìjọba
- Wo bí ọwọ́ orílẹ̀-èdè Dubai ṣe tẹ Ramoni Igbalode tí gbogbo ayé ń pè ní Hushpuppi
5) Akanji Ìbẹ̀rù, ọmọ ọlọdun mẹjọ
Eyi naa jẹ ọkan lara orukọ oriki ti Ajimọbi n jẹ funra rẹ gẹgẹ bii Akanji.
Awọn eeyan kan baa fi ibẹru sii pe ọmọ ti ẹru wa lara rẹ ni o jẹ ti wọn ko si le deede gbe ina woju ẹ gẹgẹ bii gomina.
Bakan naa ni wọn tun n yin in ni ọmọ ọlọdun mẹjọ pe ọmọ to lo ọdun mẹjo nipo gẹgẹ bii gomina.
6) Ẹkun ọkọ Florence, ọkọ gbogbo Ibadan:
Ajimọbi ni wọn maa n ki mọ Arabinrin Florence, arẹwa obinrin to fẹ sile gẹgẹ bii aya rere lọọdẹ ọkọ.
Ajimọbi ni ọpọ gba pe ko ri ara gba ọrọ si rara ti kii si fi aaye gba igbakugba rara ni ilu Ibadan.
Koda, awọn kan ni kete ti Abiola ba ti sọrọ sita ni aṣẹ ti gun un ni eyi ti awọn eeyan kan maa n tẹle ohun to ba ti sọ.

Oríṣun àwòrán, @Ajimobi
7) The Builder:
Eyi je orukọ Inagijẹ ti wọn tun fi n pe oloogbe Ajimọbi nipinlẹ Oyo.
Eyi jẹyọ nitori pe o ṣe atunṣe si ọna to pọ to ti bajẹ nigba to wa lori oye, bakan naa lo tun kọ ọna tuntun.
O tun kọ awọn ile iwe ti gbalode ti wọn pe ni Model Schools.
Bakan na lo tun kọ afara oloke ni Mokọla Round About fun a\won ọkọ lati din sunkẹrẹ - fakẹrẹ ọkọ ku.
8) Constituted Authority:
Eyi jẹ orukọ ti awọn eeyan fun un lasiko ti Gomina Ajimọbi lọ si ile iwe giga fasiti ti Ladoke Akintola ni ilu Ogbomọṣọ.
Nigba ti Ajimobi n ba awọn akẹkọọ sọrọ ni o n ba wọn wi pe wọn ko bọwọ fun alaṣẹ ti a yan le wọn lori rara ninu ihuwasi wọn.
O ni: 'Ṣe ọmọ school ni eleyi?.....
This is the Constituted Authority for Oyo state.....
The fact is that i am the Constituted Authority..."













