774,000 Jobs: Muhammadu Buhari ti paá láṣẹ fún mínísítà fún ètò ìgbanisíṣẹ́ láti tẹ̀síwájú lórí ètò ìṣẹ́ 774,000

Ààrẹ Muhammadu Buhari tí ti paá lásẹ fún mínísítà tó n ri si ọ̀rọ̀ iṣẹ́ àti ìgbanisíṣẹ́ lórílẹ̀- èdè Nàìjíríà láti tẹ̀síwájú lórí ètò ìgbanisíṣẹ́ ènìyàn ẹẹ́dẹ́gbẹ̀rin o lé mẹ́rìnléláàdọ́rin lábẹ́ ètò (SPW) ti àjọ NDE yóò sì máa mójú tó ètò náà.
Keyamo lásìkò tó ń ba ilé iṣẹ́ ìròyìn "The Nation"ní ààrẹ ló pé òun laṣẹ́ kí òun tẹ̀síwájú, àti pé ọ̀rọ̀ àwọn ọmọ ilé ìgbmọ̀ aṣòfin kò láṣẹ láti dá ètò náà dúró.
Sááju ni èdè àìyedè ti wáyé lórí ọ̀rọ̀ yìí, ti àwọn ọmọ ilé ìgbìmọ̀ aṣofin àgbà sì ti ni àwọn ti gbẹ́sẹ̀ lé ètò náà nítori mínísítà kọ̀ láti ṣe ni ìlànà tí àwọn ń fẹ́.
- APC kò ni ṣe ìdìbò nípínlẹ̀ Ondo ti ìgbìmọ̀ bá yọ mi kúrò nínú ìdíje- Segun Abraham
- Ìyàwó mi ló ṣì ń dáná, bu oúnjẹ mi, gé èékáná fún mi - Pásítọ̀ Adeboye
- Sotitobire: Ẹlẹ́rìí mẹ́rìn ló tẹ̀lé Alfa Babatunde wá síwájú ilé ẹjọ́ lonìí
- Ọlọ́pàá kọ́ lo pa olórí àwọn ''One Million Boys'' Ebila n'Ibadan- Ọ̀gá ọlọ́pàá Oyo
Wọ́n ni Keyamo kò fi ọ̀rọ̀ náà tó àwọn léti lórí bi wọ́n ṣe yan ìgbìmọ̀ ti yóò mójútó ètò ìgbanisíṣẹ́ náà nínú oṣù kèje ọdún yìí.
Keyamo ní bayìí, àwọn ìgbìmọ̀ kọ̀ọ̀kàn ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ni àwọn ìpínlẹ̀ wọ́n gẹ́gk bí wan ṣe làá silẹ̀ tẹ́lẹ̀.
Àjọ NDE ni yóò máa dari ètò náà, à ó si ṣíṣẹ́ takuntakun láti rii dájú pé a bá àsìkò tí a pinu fún ètò náà.
Ètò náà yóò gbà ènìyàn ẹgbẹ̀rún kọ̀ọ̀kan láti ìjọba ìbílẹ̀ ẹẹ́dẹ́gbẹ̀rin ó lé mẹ́rìnléláàdọ́rin jákejádò òrílẹ̀-èdè Nàìjíríà.
Bákan náà ni ètò yìí yóò ná ìjọba ni bílíọ́nù méjìléláàdọ́ta náírà gẹ́gẹ́ bí owó oṣù osgún naira fún ẹni kọ̀ọ̀kan
774,000 Jobs: Ètò ìgbani sísẹ́ yìí yóò wà ni ìdádúró náà - Ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àgbà

Oríṣun àwòrán, Others
Ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin Nàìjíríà ti kéde pé ki ìjóba dá iṣẹ́ ológun náìra oṣoosù ti ìjọba apapọ fẹ́ gbà àwọn èniyàn sí lábẹ́ àjọ tó ń gbani síṣẹ́ (NDE) láti mú ìrọ̀rùn bá ará ìlú nítori àarùn Covid-19 tó gba ayé kan.
Sáájú àsìkò yìí ni ààrẹ Muhammadu Buhari ti buwọ́lu gbígba ènìyàn ẹẹ́dẹ́gbẹ̀rin o lé mẹ́rìnléláàdọ́rin ènìyàn lọ́bẹ́ ètò náà.
Lábẹ́ ètò yìí ẹgbẹ̀rún kan ọmọ Nàìjíríà ti yóò gba ẹgbẹ̀run lọ́nà ogún Naira lósoosù fun oṣù mẹ́ta àwọn ènìyàn yìí yóò wá láti ìjọba ìbílẹ̀ kọ̀ọ̀kan ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.
O yẹ ki ètò náà bẹ̀rẹ̀ nínú oṣù kẹwàá ọdún yìí ṣùgbọ́n èdè àìyedè to wáye láàrin mínísítà fún ètò iṣẹ́ Festus Keyamo àti àwọn ọmọ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ní àná ọjọ́ iṣẹ́gun jọ bi ẹni pé ó ti pagidinà ètò náà.
Agbẹnúsọ ilé ìgbìmọ̀ asòfin àgbà Ajibola Bashiru to kéde ìdádúró ètò náà lásìkò to n bá àwọn oníròyìn sọ̀rọ̀ nílùú Abuja, ó sọ pé ilé ìgbìmọ̀ asòfin àgbà pé Festus Keyamo láti yọjú sí ilé aṣòfin láti sàlàyé lóri ọ̀nà ti wọ́n fẹ́ gbà láti gba àwọn ènìyàn sísẹ́ lábẹ́ ètò náà.
Ó ní "bí ǹkan ṣe ń lọ yìí mímú ètò náà wá sí ìmúṣẹ yóò mọ́wọ́ró díẹ̀ títí di ìgbà ti mínísítà bá le sàlàyé ara rẹ̀ lẹ́kunrẹ́rẹ́ fún àwọn ọmọ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àgbà.
Iṣẹ ilẹ gbígbá, fifọ gọ́tà, didari ọkọ̀, ati oju ọna sise, wa lara isẹ tawọn ọdọ yoo ṣe fun oṣu mẹta, ₦20,000 si ni owo oṣu wọn.
774,000 Jobs: Ọmọ Tinubu náà wà lára àwọn tí yóò agbani síṣẹ́

Oríṣun àwòrán, Lawma Lagos
Ijọba apapọ ti yan Alaafin tilu Oyo, ọba Lamidi Olayiwola Adeyemi kẹta ati alaga ẹgbẹ awakọ ero nipinlẹ Eko, Musiliu Akinsanya, MC Oluomo, sinu igbimọ ti yoo mojuto eto igbani sisẹ nipinlẹ Oyo ati Eko.
Lara awọn ti ijọba tun yan ni Oloye ẹgbẹ oṣelu APC, Alhaji Mutiu Are, ati ọmọ asiwaju ẹgbẹ naa, Folasade Tinubu-Ojo, to fi mọ alaga ẹgbẹ ọmọ lẹyin Kristi nipinlẹ Oyo, Benjamin Akanmu.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Baba Suwe bọ́ lọ́wọ́ àìsàn, ó bẹ̀rẹ̀ tíátà padà
- Jàndùkú yabo ilé ìwòsàn ìjọba sáájú ìpàdé akọ̀ròyìn táwọn dókítà pè
- Ojú Shagbada Erigga rèé lẹ́yìn tó pa ọ̀rẹ́bìnrin rẹ̀ l'Akinyele ní Ibadan
- Ìdí tí lílọ Yúrópùù fi di èèwọ̀ fún Nàìjíríà àti àwọn orílẹ̀-èdè adúláwọ̀ míì
- Arúfin ni Seyi Makinde pẹ̀lú bó ṣe gbà kí wọ́n sin Ajimobi sí GRA - Amòfin
Ko tan sibẹ, alaga ẹgbẹ awakọ ero nipinlẹ Oyo tijọba Oyo ti fofin de, Abideen Olajide, ti ọpọ eeyan mọ si Ejiogbe naa wa lara awọn ọmọ igbimọ agbanisisẹ naa.

Oríṣun àwòrán, Lawma Lagos
Igbimọ ẹlẹni ogún ọhun ni yoo mojuto gbigba ọdọ ẹgbẹrun lọna ogún si iṣẹ nipinlẹ Oyo ati Eko, nigba tawọn ọmọ igbimọ mii naa wa kaakiri awọn ipinlẹ yoku yika Naijiria.
Ọjọ Aje ni Minisita fun ọrọ awọn oṣiṣẹ ati igbani sisẹ, Festus Keyamo, ṣe ifilọlẹ igbimọ naa fun ipinlẹ kọọkan lorilẹ-ede Naijiria.
Ẹgbẹrun kan oṣiṣẹ si ni wọn o gba sisẹ ni ijọba ibilẹ kọọkan, eyi tumọ si pe ẹgbẹrun lọna ọrinlelẹẹdẹgbẹrin din mẹfa ni apapọ awọn ọdọ ti ijọba apapọ yoo gba sisẹ.
Iṣẹ ilẹ gbígbá, fifọ gọ́tà, didari ọkọ̀, ati oju ọna sise, ni diẹ lara isẹ ti awọn ọdọ naa yoo ṣe fun oṣu mẹta.
Ẹgbẹrun lọna ogún Naira si ni owo oṣu wọn.
Sugbọn sa, Keyamo sọ lọjọ Iṣẹgun pe awọn oloṣelu kan ti fẹ ẹ gba isakoso eto naa.
Lọjọ Iṣẹgun yii kan naa ni fidio kan jade sori ayelujara, to safihan bi awọn ọmọ ile aṣofin Naijiria ṣe le Minisita naa jade lasiko to farahan niwaju wọn fun ibeere nipa eto igbani sisẹ naa.
Aarẹ Muhammadu Buhari, naa si ti fi ikede sita pe, ki awọn oloṣelu maṣe lo ipo wọn lati fun ẹnikẹni ni isẹ naa.
Ìdí rèé tí ìforúkọsílẹ̀ rẹ kò ṣè wọlé lójú òpó N-Power

Oríṣun àwòrán, @NPOWER_NG TWITTER
Iroyin to gbode nilẹ oni to mọ bayi ni pe pupọ awọn eeyan to forukọ silẹ loju opo igbanisiṣẹ ijọba Naijiria N-Power 2020 ni iforukọsilẹ wọn le ma wọle.
Nitori naa ki o to lọ si oju opo wọn lati bẹrẹ eto iforukọsilẹ,wọn yi lawọn nkan to yẹ ni mimọ ti ko ni jẹ ki o kuna .
Àwọn ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa NPower àti ọ̀nà ti o fi lè forúkọ sílẹ̀
Awọn alakoso N-Power tii se eto igbanisisẹ fawọn ọdọ lorile-ede Naijiria ti fi ikilọ sita pe ọfẹ ni eto igbanisisẹ naa.
Ikilọ yi ko sẹyin bi awọn eeyan kan ti se n gbiyanju lati forukọ silẹ loju opo N-Power saaju ki wọn to sii laago mejila ku isẹju mẹẹdogun alẹ ọjọ Eti tii se ọjọ Kẹrindinlọgbọn, osu Kẹfa.
- Ire déé! MTN àti BBC World Service bẹ̀rẹ̀ àjọṣepọ̀ lórí ìròyìn ìṣẹ́jú kan BBC
- Wo àwọn èèyaǹ jàǹkàn mérin tí àrùn Coronavirus ti sọ dèrò ọ̀run ní Naijiria
- Àwọn èèyàn ìpínlẹ́ Ondo kò gbàgbọ́ pé Coronavirus wà lọ jẹ́ kó máa pọ̀ síi - ìjọba
- Wo bí ọwọ́ orílẹ̀-èdè Dubai ṣe tẹ Ramoni Igbalode tí gbogbo ayé ń pè ní Hushpuppi
Gẹgẹ bi iroyin lati oju opo naa ti se sọ, iforukọsilẹ to ba waye saaju asiko yi jẹ otubantẹ ni yoo ja si fẹni ba se iru rẹ.
Ijọba apapọ Naijiria lo se agbekalẹ eto iranwọ isẹ N-Power labẹ ileesẹ to n risi idagbasoke awujọ ni Naijiria fawọn ọdọ ti ko ba nisẹ lọwọ.
Bi o ti se le forukọsilẹ kopa ninu N-Power 2020 ree
Labẹ eto igbanisisẹ N-Power ipele kẹta to n waye losu Kẹfa, awọn to ba fẹ jẹ anfaani yi yoo lọ si oju opo ayelujara www.npower.fmhds.gov.ng lati forukọ silẹ.
Sugbọn kii se gbogbo eeyan naa lo le kopa.
Lati jẹ anfaani yi, eeyan gbọdọ jẹ ẹni ọdun mejidinlogun si marundinlogoji.
Wo awọn iwe to gbọdọ ni ko to le forukọ silẹ:
•Nọmba idanimọ ile ifowopamọ BVN
•Aworan pelebe
•Oju opo ikansiraẹni e-mail ati nọmba ẹrọ ibanisọrọ ti wọn le fi pe ọ si
•Iwe ẹri ikẹkọ gboye fasiti ati sabuke agunbanirọ NYSC
Kete ti o ba ti de oju opo N-Power, awọn ohun to yẹ ko se ree:
•Fi e-mail rẹ tabi nọmba foonu rẹ si oju aye ti wọn pese.
•Sise bẹẹ yoo mu ki o gbe ọ lọ si ibi ti o ti jẹri pe lootọ iwọ lo ni e-mail
•Bi o ba se eyi tan, o ni lati kọ nọmba idanimọ ile ifowopamọ BVN rẹ ati ọjọ ibi rẹ (dd/mm/yr)
•Abala iroyin nipa rẹ ati oju opo ikansiraẹni:kọ orukọ baba rẹ, orukọ rẹ bo ti se wa lori nọmba BVN rẹ
•Abala iwe ẹri ẹkọ ati eto miran: labala yi, o le kọ ọ sibẹ boya o kawe gboye tabi o lọ si ile ẹkọ rara.Gbogbo eeyan ni eto N-Power wa fun
•Abala Eto N-Tech ati N- Health wa fawọn to kẹkọ gboye ile ẹkọ giga nikan.

Oríṣun àwòrán, @Osinbajo
Awọn to kawe gboye fasiti, ile ẹkọ gbogbonise HND tabi OND lẹka eto ẹkọ imọ ilera, Microbiology, Psychology, Midwifery Public Health tabi eto ẹkọ miran lẹka sayensi lo le kopa nibẹ.
•Awọn to n wasẹ yi ni lati fi ẹda iwe ẹri ikẹkọgboye fasiti wọn ati iwe ẹri agunbanirọ NYSC sọwọ loju opo naa .
•Oju opo Isẹ ati awọn iroyin miran:
Awọn to n wa'sẹ ni lati dahun awọn ibeere kan ti wọn yoo si fi ẹda kaadi idanimọ wọn sọwọ. Iwe ẹri ti ijọba fontẹ lu niwọn yi:
•Iwe irina pasipọti
•Kaadi idanimọ ti ajọ NIMC n fun awọn ara ilu
•Iwe asẹ iwakọ ni Naijiria
•Kaadi idibo ọlọjọ pipẹ,PVC
•Ipele ayẹwo fini fini ka to pari:
•Nibi ni waa ti yẹ gbogbo nkan to kọ daada ti o si fi sọwọ si oju opo naa
•Bi o ba ti fi sọwọ si oju opo naa tan, wọn yoo fi nọmba idanimọ kan ransẹ si ọ,kọ silẹ ki o fi pamọ daada.
Iru awọn eeyan ti N-Power 2020 n wa?
Gẹgẹ bi awọn alasẹ ti se sọ, eto igbanisisẹ yi yoo gba eeyan ẹgbẹrun lọna irinwo sisẹ lẹka orisirisi bi isẹ ọgbin, ilera, eto ẹkọ, ile kikọ, isẹ ọna ati imọ ẹrọ tẹkinọlọji.
Ọdun 2016 ni ijọba bẹrẹ eto naa ti eeyan to to ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta si ti jẹ anfaani nibẹ.















