Seyi Makinde: Ibùdó ìlera tó wà ní Idí Iroko-Adewole tí bàjẹ́ pátápátá

Àkọlé fídíò, Seyi Makinde; Ilé iwosan kan ṣoṣo tó wà ní Idí-Iroko /Adewole tí bàjẹ́ pátápátá.

Awọn oṣiṣẹ ile iwosan Idí Iroko-Adewole ni ijọba ibilẹ Oluyole nipinlẹ Oyo ti kesi ijọba Gomina Seyi Makinde, lati ṣe atunṣe si ibudo ilera naa.

Nigba ti Akọrọyin BBC Yoruba ṣe abẹwọ si ibudo ilera naa, awọn orule to wa nibẹ ti wo, ko si oogun fun awọn alaboyun, bẹẹ si ni ko si omi fun wọn.

Nọọsi to ba wa sọrọ nibẹ sọ pe iṣẹ ọfẹ ni awọn n ṣe lati ọdun 2014, ijọba ko gba osisẹ eleto ilera sisẹ, wọn ko si san owo oṣu fun awọn.

Wọn salaye pe, ti ojo ba rọ, n ṣe ni awọn maa n bẹ Ọlọrun ki ile ma da wo le awọn lori.

Nitori naa ni wọn ṣe ke si ijọba lati dakun si ju aanu wo awọn eniyan lagbegbe naa nitori ile iwosan ti wọn niyẹn.

Apapọ ẹgbẹ awọn Alaga Ijọba ibilẹ lorilẹede Naijiria lo kọ ibudo ilera naa lọdun 2014.