Ibadan: Olóòlù kò ni kọ́ja agboolé rẹ̀ fún ọdún eégún ìlú Ibadan tọdún yìí
Ọdọọdún ni ayẹyẹ ọdún eégún máa n wáye nílu Ibadan tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ elégún oníruurú si má n yọjú lásìkò ayẹyẹ yìí.
Sùgbọ́n látì ìgbà tí ààrùn Coronavirus ti bẹ̀rẹ̀ ni ìjọba ìpínlẹ̀ Oyo ti paa lásẹ pé kò ni sí ipejọpọ̀ elérò, yálà fún ayẹyẹ, iṣílé, ìkọ́mọ jáde àti ìgbéyàwọ.
Èyí kò yọ ẹlẹsìn mùsùlùmí, onígbàgba àti àwọn ẹlẹ́sìn àbáláyé silẹ̀ pẹ̀lú.
Òpin oṣù kaarun ni ayẹyẹ ọdún eégun máa ń bẹ̀rẹ̀ ní ìlú Ibadan sùgbọ́n ìjọba ti kéde pé kò ni sí ààyè fún ayẹyẹ eégún kankan láti wọde nílùú Ibadan lọ́dún yìí, èyí ni láti dẹ́kun ìpéjọpọ̀ elérò púpọ̀ tí ó si lé mú kí ààrùn coronavirus túbọ̀ tànkalẹ̀ síi.
Olubadan tilẹ Ibadan, Ọba Saliu Akanmu Adetunji, Aje Ogungunniso kinni tún paṣẹ fun awọn egungun nilẹ Ibadan lati ṣe etutu ọdun egungun ninu ile wọn, ki wọn si maa ṣe adura fun opin arun Covid-19.
Bí o ṣe wá ku dẹ̀dẹ̀ tí àyẹyẹ eegun kan pàtàkì nílùú Ibadan egúngún oloolu yóò wáyé, BBC bá olóye Ojegboyega Adepoju to jẹ́ aláàgbàá agúngù àti akọ̀wé gbogbo eléégún nílẹ̀ Ibadan, ó sì tún jẹ́ ìgbákeji ààrẹ gbogbo ẹlẹsin ibílẹ̀ ni ìpínlẹ̀ Oyo sọrọ láti mọ igbẹ́sẹ̀ wọ́n nípa àṣe olubadan àti ìjọba.
Adepoju sàlàyé pé, níwọ̀n ìgbà ti àwọn mùsùlùmí àti onígbàgbọ́ kò lọ sí ilé ìjọsìn lásìkò ọdún wọ́n, kò sí bí ọ̀bọ ṣe sorí ti ìnàkí kò ṣe nítori náà àṣẹ ìjọba ni yóò múlẹ̀.
Nípa ti eégún olóòlù, kò sí ǹka tó fi yàtọ̀ si àwọn eégún tó kù ní Ibadan, nítorí náà, kò ni sí ààyè fún láti jáde.
Láti ìgbà tí ọdún eégú ti bẹ̀rẹ̀ ní ọjọ́kọkanlélọ́gbọ̀n, oṣù karùn-ún ọdún yìí ní gbogbo elégún ti ń ṣe ọdún wọ́n ni ààrín agbo ilé wọ́n.
"Èmi gan ṣẹ̀ṣẹ̀ gbé eégún tè mi ni àná ni ààrín agboolé sì ni mó ti gbée, nítori náà gbogbo ẹlẹsìn ìbílẹ̀ ló n gbàdúrà kí ààrùn yìí kúrò nilùú, sùgbọ́n lásìkò yìí, kí gbogbo elégún sàdúrà nígbàlẹ̀ wọ́n."
Nínú ọ̀rọ̀ tirẹ̀ bàbá eégún olóòlù fúnra rẹ Ifasuyi Omotosho Kazeem sọ pé àṣẹ ìjọba àti ti Olúbadan ni abẹ́ gé, èyí lòdì sí ọ̀rọ̀ rẹ̀ to ti bá BBC Yoruba sọ tẹ́lẹ̀ pé ti eégún olóólù kò bá jáde, ǹkan le bàjẹ́ nílùú Ibadan.
Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ sí BBC , Ifasuyi ní kò sí ǹkan ti yóò ṣẹlẹ̀ ti eégún òun kò bá jáde nítorí gbogbo etùtù tó yẹ ni àwọ́n ti ṣe nígbàlẹ̀, bákan náà ni eégún ọ̀hún kò ni kọ́ja agboolé.
''A ti ṣe gbogbo ètùtu tó yẹ́, asì ti sàdúra tí yóò kó ààrùn Coronavirus kúrò nílùú.''