Ibadan: Bode Akindele, Richard Akinjide àti àwọn èèkàn míì tó kú lọdún 2020

Aworan awọn eekan ilu Ibadan ti iku mu lọ

Lẹnu lọọlọ yi, iku awọn eekan ilu, paapa julọ awọn to ti gun oke agba ṣebi ẹni fẹ wọpọ.

Yika Naijiria ni iku ti n mu awọn eeyan lọ, ti a si ri atọkasi pe arun Covid 19 to n ja rainrain nilẹ bayii, ni ipa to n ko ninu rẹ.

Nilẹ kaarọ o jiire, paapa nilu Ibadan, n se ni iku n pa awọn eeyan jankanjankan bi ẹni pa adiẹ.

Ọrọ yii fọwọ kan Olubadan ilẹ Ibadan, Ọba Saliu Akanmu Adetunji lẹmi debi pe lọjọ Aje, Olubadan lọgun lori iku ọwọwọ awọn ogo ilẹ Ibadan yii.

Ti iroyin iku Parakoyi Ibadan, Oloye Bode Akindele ta tun ṣẹṣẹ gbọ laipẹ yii, si tun da omi tutu si ọkan awọn eeyan.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Awọn eekan ilu miran naa si ti lọ ki o to kan gbajugbaja olokoowo yii.

Diẹ ninu awọn eekan Ibadan ti iku mu lọ ree:

Oloye Bode Akindele:

Ninu ifọrọwanilẹnuwo kan ti BBC Yoruba ṣe pẹlu aarẹ ẹgbẹ ọmọ Ibadan, Oloye Adeyemi Soladoye, o ni iku Parakoyi Ilẹ Ibadan, Oloye Bode Akindele ni ẹlẹẹkeje iru rẹ ti yoo ṣẹlẹ lati ibẹrẹ ọdun yii.

Bode Akindele jẹ ẹni ti eledua fi ọrọ ta lọrẹ, to si maa n na owo rẹ lati fi ran awọn eeyan lọwọ.

Aworan Seyi Makinde ati Oloye Bode Akindele

Oríṣun àwòrán, Facebook/Seyi Makinde

Gomina Ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde ninu ọrọ ikẹdun iku onisoowo yii sọ pe ''baba to bi mi ma n gbadura pe ki n dabi Oloye Akindele ni, ti mo ba dagba tan''

Makinde sọ pe, Oloye Akindele lẹni to da owo to pọju fun ijọba lati koju ajakalẹ arun Covid 19.

Agbẹjọro agba Richard Akinjide:

Oloye Osuolale Abimbola Richard Akinjide kii ṣe aimọ lagbo awọn ọtọkulu nilẹ Naijiria, paapa ni ẹka imọ nipa ofin.

Agbẹjọro agba yii fi igba kan jẹ minisita feto ẹkọ ni saa iṣejọba alagbada akọkọ, ti o si tun jẹ Minisita feto idajọ ni saa iṣejọba ẹlẹẹkeji ni Naijiria.

Richard Akinjide

Oríṣun àwòrán, Others

Bẹẹ naa lo wa lara awọn to fi ẹgbẹ agbaagba Yoruba, Yoruba Council of Elders lọlẹ ni ọdun 1975.

Ninu awọn to kopa nibi apero atunto ilẹ Naijiria to waye ni 2014, o jẹ ọkan lara awọn agba ọjẹ to kopa nibẹ.

Ọjọ kọkanlelogun oṣu Kẹrin ọdun 2020 ni alagba Richard Akindele dagbere faye pe o digba, lẹni ọdun mọkandinlaadọrun.

Areoye Oyebola:

Olootu agba nigba kan ri fun ileesẹ iroyin Daily Times, alagba Areoye Oyebola kopa ribi ribi lagbo awọn oniroyin ati onkọwe nigba aye rẹ.

Aworan Alagba Oyebola

Oríṣun àwòrán, The Guardian Nigeria

Àkọlé àwòrán, Ilumọọka onkọwe ni Areoye Oyebola nigba aye rẹ

Bi a ba n darukọ awọn to lalẹ gaara fawọn to n bọ lẹyin wọn nipa iroyin oniwadi, Oyebola jẹ ọkan gbogi.

Nigba aye rẹ, iwe mẹrindinlọgbọn ni Oyebola kọ.

O fi aye silẹ lẹni ọdun mẹrinlelọgọrin lọjọ kẹwa oṣu kẹta ọdun 2020 yi kan naa.

Lalekan Ayokunnu Are:

Ọmọwe Olalekan Ayokunnu Are jẹ onimọ ati olukọni pataki nilẹ Naijiria.

Ọmọ agbole Are ni Oke Are ni Ibadan nii se, ọmọwe Lalekan si tun jẹ onimọ nipa ọgbin, ti o si jẹ onisowo pataki lawujọ.

Aworan Lekan Are

Oríṣun àwòrán, Others

Nibi ayẹyẹ isinku rẹ, igbakeji Gomina ipinlẹ Oyo, Rauf Aderemi Olaniyan sapejuwe rẹ gẹgẹ bi awokọse fun oun, ti o si gbadura ki ẹlẹda tẹ si afẹfẹ rere.

Lalekan Are dagbere faye lẹni ọdun marunlelọgọrin.

Sẹnẹtọ Abiola Ajimobi:

Gomina Ajimobi

Oríṣun àwòrán, @AAAjimobi

Àkọlé àwòrán, Gomina Ajimobi

Gomina nigba kan ri ni ipinlẹ Oyo, Abiola Ajimobi, jẹ ẹnikan ti iroyin iku rẹ milu titi.

Arun Covid 19 lo ṣekupa ogbontarigi oloselu yii lẹni aadọrin ọdun.

Ọjọ kẹẹdọgbọn osu kẹfa ọdun 2020 si ni gomina ana naa dagbere faye nile iwosan aladani kan nilu Eko nibi to ti n gba itọju lori arun Coronavirus.

Ògo ilẹ̀ Ibadan míì lọ, Pàràkòyí Olóyè Bode Akindele dágbére fáyé

Aworan Bode Akindele

Oríṣun àwòrán, thisdaylive.com

Àkọlé àwòrán, Oloye Bode Akindele lo si yi fun ijọba ipinlẹ Oyo lowo to pọju lati fi koju arun Covid-19

Saaju la ti mu iroyin wa fun yin pe iku tun ti doro nilẹ Ibadan pẹlu bi iroyin iku Oloye Bode Akindele ṣe gbagboro kan.

Oloye Bode Akindele lasiko aye rẹ jẹ ilumọọka oniṣowo ti o si tun jẹ Parakoyi ti ilu Ibadan.

Ẹni ọdun mẹtadinlaadọrun ni wọn jẹ.

Aarẹ ọmọ ẹgbẹ ilu Ibadan Oloye Adeyemi Soladoye fidi ọrọ yi mulẹ fun ileesẹ BBC Yoruba, to si sọ pe nilu Eko ni agba ọjẹ yi ku si.

Soladoye ṣapejuwe iku Oloye Bode Akindele gẹgẹ bi eyi to fọwọ kan ni lẹmi nitori o jẹ ọkan lara awọn ogo ilẹ Ibadan ti awọn n foju sun.

''Ni nkan to ti n sẹlẹ lati osu kini ọdun yi, Oloye Bode Akindele ni ẹnikeeje ogo ilẹ Ibadan to jẹ Ọlọrun nipe lọdun yi''

Ninu apejuwe to se, o sọ pe Oloye Akindele jẹ jagunjagun aye isin lẹka oko owo.

Àkọlé fídíò, Ẹgbọ́n olóògbé Suga: Wọ́n yìnbọn fún Suga lójú mi, n kò sì lè dá wọn dúró

''Oloye Akindele jẹ akikanju ti a le fi we awọn jagunjagun aye atijọ bi Ogunmọla, Ibikunle, Odẹrinlọ. Awọn ti a n wo mọ Ibadan lara ree laye isin''

Nigba ti BBC beere boya Covid-19 lo sokunfa iku olokoowo yi, Soladoye ni ohun ko le sọ sugbọn o ni arun Covid-19 ko jẹ ki ọpọ awọn agbalagba ko ribi gba itọju to yẹ.

Àkọlé fídíò, Africa Eye: Ọwọ́ tẹ ayédèrú dókítà Abdallah tó ń tà oògùn Coronavirus

Laipẹ yi ni ilumọọka oniṣowo ọmọ ilẹ Ibadan yi da ọgọrun miliọnu naira fun ijọba apapọ ati ti ipinlẹ Oyo lati fi koju arun Covid-19.

Àkọlé fídíò, Láàrín ìdílé ẹlẹ́ni márùn ún yìí, ọmọ kan ṣoṣo ló léè sọ̀rọ̀