Ajimobi Vs Seyi Makinde: Amòfin ní tí Ajimobi bá jẹ́ mẹ̀kúnnù, ṣé Makinde yóò gbà kí wọ́n sín sí GRA?

Oku Ajimobi n wọ ilẹ lọ

Oríṣun àwòrán, Ajimobi lives on

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Ọrọ ti n ba ọrọ bọ, eegun alare lori igbesẹ ti gomina Seyi Makinde gbe, nipa fifun ẹbi Abiola Ajimobi laaye lati sin oku si ilẹ ijsba GRA, ti ofin ko faaye gba.

Awọn ọmọ Naijiria kan lo fi oju laifi wo igbesẹ naa lori ayelujara, ti wọn si ni igbesẹ arufin gbaa ni Makinde gbe, pẹlu bo se fi ontẹ lu isinku Ajimobi sori ilẹ GRA.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Idi si ree ti BBC Yoruba fi tọ onimọ kan nipa ofin lọ lati beere pe, se gomina Makinde rufin lootọ abi bẹẹ kọ lori gbigba ki wọn sin Ajimobi si GRA.

ABIOLA

Lero ti Amofin Ayodeji Olabiwonninu ni ofin Nigeria Land use act 1978 fun gomina ipinlẹ kọọkan lagbara lati sakoso awọn ilẹ ijọba to wa ni agbegbe rẹ.

O fikun pe, pẹlu ohun gbogbo ti a ri ka ninu iroyin ati ofin ilẹ Naijria, ko yẹ ki Gomina Makinde gba ki wọn sin Ajimobi si GRA Oluyole, to wa ni Ibadan.

Amofin naa ni ''O fihan gbangba pe awọn kan ga ju ofin lọ ati wi pe, ofin orilẹede Naijria ko jọba lori gbogbo eniyan.''

Oku Ajimobi

''Ni ọpọlọpọ agbegbe ni Naijiria, awọn eniyan giga ati ọlọla n jọba lori ofin, ti ko si si ẹni ti yoo mu wọn si.''

Amofin Olabiwonninu wa n beere pe, "ka ni mẹkunu ni Abiola Ajimobi, n jẹ ijọba le gba ki wọn sin oku rẹ si GRA?

Ijiya wo lo tosi ẹni to ba ru ofin to lodi si sinsin oku si ilẹ ijọba GRA?

Nigba to n mẹnu ba iru ijiya to tọ si ẹni to ba rufin yii, Olabiwonninu sọ wi pe, ijiya to rọ mọ riru ofin to de bi wọn ṣe n lo ilẹ ijọba yatọ ni agbegbe kan si omiran.

Olabiwonninu ni, gbogbo ofin to ba ti tọka si pe iwa yii ko lẹtọ, naa lo ma n sọ iru ijiya to tọ si ẹni to ba rufin naa ni agbegbe ọhun.

ABIOLA Ajimobi

Amọ, o ni ohun to ṣe ni laanu ni wi pe, ijọba lo ma n pe eniyan lẹjọ to ba ru ofin to de lilo ilẹ ijọba.

Sugbọn nibayii, "ijọba ipinlẹ Oyo gan an lo rufin, ta ni yoo wa gbe Gomina Seyi Makinde lọ si ile ẹjọ bayii, lẹyin ti wọn fun ẹbi Abiola Ajimobi laaye lati sin oku si GRA, to wa ni ipinlẹ naa?

Ṣé ó leè jẹ́ ilẹ̀ tí Makinde kò jẹ́ kí Florence Ajimobi gbà ló ń bi nínú?

Awọn ẹri dabi ẹni ti n farahan lori idi ti iyawo gomina ipinlẹ Ọyọ nigba kan, Florence Ajimobi, fi tahun si ijọba ipinlẹ Ọyọ lọjọ Aiku lẹyin isinku ọkọ rẹ.

Ọjọ Aiku ni fidio kan gba ori ayelujara, eyi to ṣafihan Florence, nibi to ti n tahun si igbakeji gomina ipinlẹ Ọyọ, Rauf Olaniyan, pe wọn ko ba oun kẹ́dùn iku ọkọ oun.

Gomina Seyi Makinde, oloogbe Abiola Ajimobi ati iyawo rẹ

Oríṣun àwòrán, @AAAjimobi

Olaniyan naa han ninu fidio naa, ti wọn ká silẹ ninu yara igbalejo kan nile Ajimobi lẹyin eto isinku rẹ.

Ninu ikede kan ti Akọwe iroyin fún Gomina Seyi Makinde, fi sita lo ti dabi ẹni pe ijọba gbiyanju lati wẹ ara rẹ mọ.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post

Atẹjade naa sọ pe gbogbo igbiyanju àti igbesẹ oun lati ṣe atilẹyin fun idile Ajimobi, lasiko to fi wa ni i dubulẹ aisan lo jasi pabo. Ati pe iyawo Ajimobi kò tẹle ilana to yẹ lati fi aisan àti ikú ọkọ rẹ to ijọba ipinlẹ Ọyọ l'eti.

Ninu fidio naa, Olaniyan sọ pe gbogbo ipe ti oun pe si ori ẹ̀rọ ibanisọrọ Florence Ajimobi, ni kò gbé.

Iroyin tun sọ pe Makinde pe igbakeji gomina ipinlẹ Eko ni, ki o to o ri nọ́mbà dokita to n tọju rẹ.

"Ọna ile ijọba ni dokita naa wa, lẹyin ti mo ránṣẹ pé e láti ba mi sọrọ l'ori aisan Ajimobi, ki ọkọ rẹ to jẹ ọkan lara awọn to di ipo mu ninu ise jọba Ajimobi, to sọ fún un pe ko pada, ko si yọ́ wọ ilu Eko."

Koda, igba ti gbogbo igbiyanju mi lati ba Florence sọrọ ja si asán, ni mo pé gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-olu, pe mo fa ohun gbogbo le e lọwọ, ati pe ko ba ipinlẹ Ọyọ tọju Ajimobi daada, ko si jẹ ki n mọ ti wọn ba nilo iranlọwọ mi.

"Iroyin tun sọ pe Makinde pe Arabinrin Florence Ajimobi, nigba to gbọ pe ọkọ rẹ kú, sugbọn ko tun gbe ìpè."Ipinlẹ Edo ni gomina wa nigba to gbọ pe Abiola Ajimobi kú.

Ó pe iyawo rẹ, sugbọn ko gbe ipe. Eyi ko si tun di lọwọ lati ṣe nkan to yẹ.

Loju ẹsẹ lo pàṣẹ pe ki wọn o sọ asia orilẹ-ede Naijiria kalẹ, lati bu ọlá fun." Iroyin sọ pe, afi bi Gomina Makinde ṣe gba ipe lati ọdọ agba oloṣelu kan, pe ko yọnda ilẹ bi plot mejidinlaadọta fun idile Ajimobi.

Adugbo ti ijọba ya sọtọ, ni Agodi GRA, ni ilẹ to to pulọọ́ti mejidinlaadọta naa wa.

Koda, iroyin sọ pe awọn agbaagba ninu ẹgbẹ oṣelu APC ati PDP, to fi mọ aarẹ Naijiria nigba kan, lo pé Makinde pe ko yọnda ilẹ naa fun wọn lati sin oku Ajimobi si.

Taiwo Adisa sọ pe "ọrọ ilẹ naa wa nile ẹjọ, oun ko si le tapa si àṣẹ ile ẹjọ.

Koda, gomina Abiola Ajimobi lo gbé ijọba ipinlẹ Ọyọ lọ sile ẹjọ lori ọrọ ilẹ naa."

"Ati pe lootọ ni ofin kò gba ki wọn sin oku si adugbo ti ijọba ya sọtọ, ìyẹn GRA."

Ile Ajimobi to wa ni GRA lagbegbe Ring-Road, nilu Ibadan, ni wọn padà sin in si.

Eyi to tumọ si pe o ṣe e ṣe ki ijọba fun wọn ni àṣẹ láti ṣe bẹẹ. Eyi lo si mu ki ọpọlọpọ máa sọ lori ayelujara pe o ṣee ṣe ko jẹ nkan to n bi iyawo Ajimobi ninu gan-an ni pe Gomina Makinde ko jẹ ko gba ilẹ naa to wa ni Agodi GRA ko di tara rẹ.