Coronavirus: Ìjọba Osun ní àìlo ìbòmú aráàlú ló mú kí Corovirus peléke si

Oríṣun àwòrán, Facebook/Omipidan Ismail
Ijọba ipinlẹ Osun ti gbe igbesẹ lati fi titẹle awọn ilana aabo lasiko Covid -19 mulẹ, to si pọn idanilẹkọ ni dandan fawọn to ba tasẹ agẹrẹ sofin yii.
Ninu ọrọ ti Ismail Omipidan, agbẹnusọ fun Gomina Gboyega Oyetola fi sita loju opo Facebook rẹ, o ni awọn eeyan kan ti ọwọ tẹ lo ti n gba idanilẹkọ nipa didaabo bo ara wọn lasiko Covid 19.
O ni igbimọ amuṣẹya ipinlẹ Osun se idanilẹkọ yii, ki wọn baa le dẹkun itankalẹ arun Covid-19.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Arúfin ni Seyi Makinde pẹ̀lú bó ṣe gbà kí wọ́n sin Ajimobi sí GRA - Amòfin
- Àwọn ògo Ibadan márùn ún tí ikú mú lọ lọ́dún 2020
- Mo ti lùgbàdì àrùn Coronavirus - Akeredolu figbe ta
- Ṣé ó leè jẹ́ ilẹ̀ tí Makinde kò jẹ́ kí Florence Ajimobi gbà ló ń bi nínú?
- Akinyele tún gbàlejò àwọn mùjẹ̀mùjẹ̀, tìyá-tọmọ̀ fara gbọgbẹ́
- Ẹ pèsè ẹlẹ́rìí púpọ̀ bí bẹ́ẹ̀ kọ́, Sotitobire yóò jẹ́rìí fúnrarẹ̀ o! - Ilé ẹjọ́ ìpínlẹ̀ Ondo
- Ilé ìwòsàn kan rèé tó ń fi àtùpà gbẹ̀bí aláboyún
Ninu awọn aworan to fi kin iroyin naa lẹyin, a ri ti awọn eeyan kan joko si inu gbagede kan ti o si jọ pe wọn se idanilẹkọ fun wọn.
Idanilẹkọ gẹgẹ bi o ti se sọ wa ni ibamu pẹlu ilana ti ajọ to n gbogun ti aisan lorileede Naijiria, NCDC gbe kalẹ.

Oríṣun àwòrán, Facebook/Omipidan Ismail
Lọpọ awọn ipinlẹ ni Naijiria, awọn eeyan ko kọbi ara si ilana ti ijọba gbe kalẹ lẹyin ti wọn dẹwọ isede.
Laipẹ yii ni Kọmisana feto ilera ipinlẹ Osun, ati akẹgbẹ rẹ nilu Eko sọ pe, bi awọn eeyan ko ba sọra ijọba yoo gbe ofin konile o gbele miran kalẹ.
Isamotu Rafiu Olasunkanmi, Kọmisana ilera ni Osun ni awọn ara ilu kii fẹ lo ibomu ati pe, iye awọn to n ko arun Covid-19 n peleke si ni.
Àwọn ìjọba ìbílẹ̀ méjìdínlógún yìí kò tíì lè bọ́ lọ́wọ́ ìséde - Ìjọba àpapọ̀

Oríṣun àwòrán, @BAshirAhmad
Saaju la ti mu iroyin wa fun yin pe ijọba apapọ ti ni o ṣee ṣe ki oun ṣi gbe ofin isede le awọn ijọba ibilẹ mejidinlogun kan ni Naijiria.
Awọn ijọba ibilẹ yii ni wọn ni o n pese ida ọgọta awọn to lugbadi Covid19 ni ipele isede yii lorilẹede Naijiria.

Oríṣun àwòrán, @BAshirAhmad
Alaga igbimọ amuṣẹya aarẹ lori kikoju Covid19, Boss Mustapha fi eyi han lẹyin to dari awọn ọmọ igbimọ to ku lati lọ jabọ fun aarẹ Muhammadu Buhari lori ibi ti ọrọ de duro ni ile aarẹ lọjọ aje.
Mustapha ni ofin ti wọn yoo gbe kalẹ lawọn ijọba ibilẹ ọhun ni wọn pe ni "isede pato".
Wọn ni orilẹede Naijiria ko tilẹ tii goke rara nipa awọn to n lugbadi arun ọhun torinaa o rọ awọn tọrọ kan ki wọn maa tẹle ofin bo ṣe yẹ.
Bakan naa o ṣalaye ohun to wa nibi bi awọn to tara arun Coronavirus ku ko fi pọ.
O ni ida ọgọrin awọn to n ko o lọjọ ori wọn wa laarin ọdun mọkanlelọgbọn si ogoji eyi to ṣapejuwe bi awọn ti ara wọn ṣi ji pepe laarin gbogbo ọmọ Naijiria.
Bi a ba wo akọsilẹ to wa lati. ajọ NCDC, mọkanla ninu awọn ijọba ibilẹ mejidinlogun ta n wi yii ti wọn ti n ko arun Coronavirus ju si lo wa ni ipinlẹ Eko.
Akọsilẹ naa ṣe alakalẹ pe lara awọn ijọba ibilẹ ọhun Lagos Mainland ni Eko, Abuja Municipal Area Council l'Abuja, Mushin Eti-Osa ni Eko ati ijọba ibilẹ Tarauni ni Kano.













