School resumption in Nigeria: Ibi ọ̀rọ̀ dé dúró rèé lórí ṣíṣí àwọn ilé ìwé padà ní Naijira àti nílẹ̀ Afrika

Oríṣun àwòrán, AFP
Lẹyin oṣu diẹ ti igbele Coronavirus bẹrẹ kaakiri agbaye, awọn ile iwe alakọbẹrẹ ati girama ni Tanzania ti pada bẹrẹ lọjọ Aje, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu kẹfa, ọdun 2020.
Igbesẹ yii lo waye lẹyin ti aarẹ John Magafuli paṣẹ ni nnkan bi oṣẹ diẹ sẹyin pe ki wọn ṣi awọn ile iwe pada.
Ijọba ilẹ naa ti gbe ilana kalẹ lori awọn ohun to yẹ ki awọn ile iwe ṣe lati dabo bo awọn akẹkọọ.
Tanzania ni orilẹ-ede akọkọ ti yoo ṣilẹkun ile iwe rẹ fun awọn ekẹkọ nilẹ Afrika lẹyin igbele Coronavirus.
- Ẹ pèsè ẹlẹ́rìí púpọ̀ bí bẹ́ẹ̀ kọ́, Sotitobire yóò jẹ́rìí fúnrarẹ̀ o! - Ilé ẹjọ́ ìpínlẹ̀ Ondo
- Ògo ilẹ̀ Ibadan míì lọ, Pàràkòyí Olóyè Bode Akindele dágbére fáyé
- Wọ́n rí òkú ọmọ ọdún mẹ́fà tí wọ́n fipá bálopọ̀ nínú mọ́ṣálàáṣí ní Kaduna
- Ẹ dá àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò igbákejì gómìnà ìpínlẹ̀ Ondo padà ní kíá - ọ̀gá àgbà iléeṣẹ́ ọlọ́pàá
Awọn orilẹ-ede miran nilẹ Afrika to ti ṣilẹkun ile iwe rẹ.
Guinea
Ọjọ kẹrin, oṣu karun un, ọdun 2020 ni ilẹ New Guinea ṣilẹkun ile iwe rẹ pada.
Ajọ to n risi eto ilera lagbaye, WHO ti fọwọsowọpọ pẹlu ijọba ilẹ naa fun alakalẹ lori bi abo to peye yoo ṣe wa fun awọn ọmọ ile iwe.
Awọn irinṣẹ to n ṣayẹwo bi ara eeyan ṣe n gbona si, omi ati ọṣẹ fun ọwọ fifọ atawọn ohun miran ti wa ni sẹpẹ lawọn ile iwe ọhun.
- Ìbẹ̀rùbojo gba ọkàn àwọn olùgbé Eko àti Ogun nítorí adágún omi Ọ̀yan tí yóò di ṣíṣí láìpẹ́
- Ṣé ó leè jẹ́ ilẹ̀ tí Makinde kò jẹ́ kí Florence Ajimobi gbà ló ń bi nínú?
- Florence Ajimobi tahùn sí igbákeji gómìnà Oyo lórí ikú ọkọ rẹ̀, "Gbogbo wa làó kú"
- Àjọ NCDC kéde ènìyàn 490 tó tún ṣẹ̀ṣẹ̀ ní Coronavirus ní Nàìjíríà
South Africa
Bo tilẹ jẹ pe awọn obi ni ko yẹ ko ri bẹ, ọjọ kẹjọ oṣu Kẹfa ni ijọba South Africa ṣi awọn ile iwe rẹ pada.

Oríṣun àwòrán, World Health Organisation
Cameroon
Ọjọ kinni oṣu kẹfa ọdun 2020 ni awọn akẹkọ to wa ni ipele ikẹyin ni ile iwe alakọbẹrẹ ati girama pada sẹnu ẹkọ wọn ni Cameroon.
Minisita eto ẹkọ ilẹ naa, Pauline Lyonga ni igbesẹ ọhun jẹ ọna lati jẹ ki awọn ọmọ ile iwe má gbagbe awọn ohun ti wọn ti kọ ṣaaju igbele Coronavirus.
Ivory Coast
Orilẹ-ede Ivory Coast wa lara awọn ilẹ ni Afrika to kọkọ ṣi ile iwe rẹ pada.
Ọjọ karundinlọgbọn, oṣu karun un, ọdun 2020 ni awọn akẹkọọ pada sẹnu ẹkọ wọn.
Senegal
Aarẹ Macky Sall sun ṣiṣi ile iwe siwaju ni Senegal lẹyin ti awọn olukọ kan lugbadi arun Covid-19.
Ṣaaju lo ti kọ sọ pe ọjọ keji ọsu kẹfa ni oun yoo ṣi awọn ile iwe nilẹ naa.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Uganda
Ni ti Aarẹ Yoweri Museveni, o sọ pe oun ko tii ṣetan lati ṣi ile iwe bayii.
O ni ilẹ naa ko ni irinṣẹ ayẹwo to to lati ṣayẹwo Coronavirus, nitori naa, ki ile iwe ṣi wa ni titi pa lọwọ yii.
Naijiria
Ṣaaju ni ipinlẹ kan ṣoṣo to ni oun ko tii ni arun Coronavirus ni Naijiria, Cross Rivers ti pinnu lati ṣi awọn ile iwe rẹ lọjọ kẹrindinlogun, oṣu kẹfa, ọdun 2020, ṣugbọn o wọgi le ipinnu naa lẹyin akitiyan ijọba apapọ.
Ọkan lara awọn igbimọ aṣẹjọba ipinlẹ naa ṣo pe ijọba ipinlẹ ọhun yi ipinnu ṣiṣi ilwe iwe naa pada nitori ijọba apapọ ko faye gba a.
Bakan naa ni awọn ẹgbẹ kan, bi ẹgbẹ awọn dokita sọ pe o lewu lati ṣi awọn ile iwe pada lasiko naa.














