Access Bank: Ilé ìfowópamọ́ Access ti gbà láti dá owó àwọn oníbàráà wọ́n padà

Access Bank: Ilé ifowopamọ Access ti gba láti dá owó àwọn oníbara wọ́n padà

Oríṣun àwòrán, Access bank

Lẹ́yìn awuyewuye to waye lori ayélujára ní àna nipa owó ti ilé ìfowópàmọ Access bank náà yọ lọ́nà àìtọ́ gẹ́gẹ́ bi (Stamp Duty) ń yọ lori

àwọn oníbàrá wọn, ilé ìfowopamọ́ náà ti gbà láti dá owó oṣù kejì àti kẹrin padà.

Bakan náà lo ni, àwọn yóò dá eyi ti wọ́n yọ lọ́jọ́ Sátidé àti ọjọ́ àìkú pada fun àwọn oníbara ti ọ̀rọ̀ náà kan.

Nínú àtẹ̀jáde tí ilé ìfowópamọ́ ọ̀hún fi síta lọ́jọ́ Àìkú, sàlàyé pé ó ye òun yékéyéke pé àsìkò yìí kò rọgbọ fún àwọn oníbara òun rárá.

Àtẹjáde náà lọ báyìí: "A ti wòye lóri bi àwọn alábara wà ṣe fi ẹdùn ọkàn wọ́n hàn lori àwọn ìkànnì orí ayélujara lóríṣiríṣi lọ́jọ́ sátide àti ọjọ́ Àìkú nípa owó tí a ń yọ "Stamp Duty".

A ti gbọ́ ẹdùn ọkàn yín a sì ti ṣetan láti dá awọn owó náà padà

Ilé ifowopamọ Access ti gba láti dá owó àwọn alábara wọ́n padà

Oríṣun àwòrán, AccessBank

Sáájú ni ilé ìfowópamọ́ náà ti fi àtẹjáde kan sọ́wọ́ pé àwọn kò yọ "Stamp Duty" lórí kátàkárà tó wáyé láàrín ọjọ́ kini oṣù keji àti ọgbọ̀n ọjọ́, oṣù kẹrin ọdun yìí tẹ́lẹ̀.

Iwé ofin Naijiria ọdun 2019 lóri ìṣúna ti paa lásẹ pé ki ilé ìfowópama máa yọ ààdọ́ta nairia gẹ́gk bi "Satamp duty lórí gbogbo ẹgbẹ̀run mẹwàá náírà ti ó ba wọ àpò ikówósi nílé ìfowwópamọ́.