Ajimobi's Burial: ìjọba ìpínlè Oyo yẹrí lóri ètò ìsìnkú Abiola Ajimobi tó falẹ̀

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Ijọba ipinlẹ Oyo ti sọ pe kii ṣe ẹbi oun pe wọn ko tii sin oku Abiola Ajimobi to jẹ gomina ana ni ipinlẹ naa.
Agbẹnusọ fun gomina Seyi Makinde, Taiwo Adisalo sọ bẹ ninu atẹjade kan to fi sọwọ si awọn akọroyin.
Adisa sọ ninu atẹjade naa pe irọ nla ni pe ijọba ipinlẹ Oyo lo n fi ọrọ isinkun ọhun falẹ gẹgẹ bi ahesọ ti awọn kan n gbe kiri.
O ni "Iroyin ofege yii ti awọn kan n sọ kiri jẹ ọna lati mọọmọ ba orukọ ijọba ipinlẹ Oyo jẹ ati lati ti ọrọ oṣelu bọ eto isinku oloogbe naa."
Adisa tẹsiwaju pe iroyin ofege ọhun bẹrẹ lati oju opo ikansiraẹni lori itakun agbaye, ko ti de pe awọn ileeṣẹ iroyin abẹle kan bẹrẹ si n pin iroyin naa kiri.
O ni "Ọpọ ileeṣẹ iroyin lo kan si ọfiisi gomina lọjọ Abamẹta lati bere bi ọrọ naa ṣe jẹ."
"A fẹ jẹ ko han si gbogbo eeyan pe gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde ko lọwọ ninu bi eto isinku gomina ana, Abiola Ajimobi ṣe falẹ."
Adisa ni awọn mọlẹbi oloogbe ọhun kan si ijọba lati sin oku rẹ si ori ilẹ kan ni Agodi GRA, ṣugbọn ẹjọ ṣi wa lori ilẹ naa, eyi to jẹ ko ṣoro lati fọwọ si pe ki wọn sin gomina ana ọhun sori ilẹ naa.
O tẹsiwaju pe gomina Seyi Makinde gba ki wọn sin oku naa si ori ilẹ rẹ to wa ni Oluyole Estate, bo tilẹ jẹ pe ko ba ofin to rọ mọ ọrọ ilẹ mu ni ipinlẹ Oyo.
Ṣugbọn ijọba gba ki wọn sin oku na sibẹ ko ma ba si ede aiyede laarin ijọba ati mọlẹbi ologbe ọhun.
Adisa pari ọrọ rẹ pe o lodi si ofin ipinlẹ Oyo lati sin oku si eyikeyi ninu Oluyole Estate tabi Agodi GRA.












