PSquare Peter Okoye sàlàyé bí ààrun Coronavirus ṣe mú-un, ìyàwó rẹ̀ àti ọmọ

Oríṣun àwòrán, Screenshot/
Peter Okoye, ìyàwó rẹ̀, àti ọmọ ló lùgbàdì ààrùn coronavirus fún odidi ọ̀sẹ̀ mẹ́ta, gbájugba olórin náà sàlàyé ọ̀rọ̀ náà lórí fọ́nran Instagram lọ́sàn òní sátíde'
O ní ìdí nìyìí ti ètò orí zoom tó máa n ṣe fi ni ìdíwọ́ díẹ̀ lásìkò tí òun ya ara òun sọ́tọ̀
''O ní kí ènìyàn ni ìgboyà lo fi le borí ààrùn yìí, èyí ni ǹkan tó sọ nínú fọ́nran náà lórí Instagram rẹ.
Fún ọ̀pọ̀ ọ̀sẹ̀ ni mó fi wà ni àtìmọ́lé nínú ilé ara mi lori àkéte sàìsàn. Mó lùgbàdì ààrùn Covid-19 àyẹwò sì fìdí rẹ̀ múlẹ̀. O jẹ́ ǹkan tó nira láti le bọ́ sita gbangba pé ènìyàn ni ààrùn Covid-19"
Peter Okoye ni "mó rò pé àwàdà ni ọ̀rọ̀ ààrun Covid-19 tẹ́lẹ̀ ni, mí ò sì kọbi ara si"
Lẹ́yìn náà ni ìyàwọ mi àti ọmọ mi ni ààrùn náà ti fi mọ́ ẹni to n ba wa dána àti alágbàta ọmọ mi náà.
Sùgbọ́n ìròyìn ayọ ní pé, ní báyìí ní òun àti ẹbí òun láwọ́n ti bọ́ lọ́wọ́ ààrùn Covid-19 lọẹ́yìn ti àwọn gba ìtójú.
"Tí ẹ bá rò pé ìrọ́ ni ọ̀rọ̀ coronavirus, tóri pé kò ti mú èèyàn kankan to súnmọ́ yín ni. Mò ń sọ fun yín pé lóòtọ́ ni Covid-19 wà, èyí ni àlàyé Okoye .
















