Ibadan Death: Àwọn ará àdúgbò Akinyele ké sita lórí iṣékúpani tó ń wáyé ní ìlú Ibadan

Àkọlé fídíò, Ibadan Death: Àwọn ará àdúgbò Akinyele ké sita lórí iṣékúpani tó ń wáyé ní ìlú Ibadan.

Awọn ara adugbo Akinyele ni ilu Ibadan ti kesi ijọba lati pese aabo fun wọn lẹyin ti awọn kan tun sa obinrin kan ni ada pa ni aarọ kutu Ọjọru

Awọn ara adugbọ to sọrọ ni arabinrin Olufisayo Fagbemi ji laarọ kutu bi aagọ marun un lati fọ aṣọ ni iwaju ile, ki wọn to ba a ninu agbara ẹjẹ.

Lẹyin ti wọn sa a ni ada ni iwaju ori ni Ọjọru.

Awọn ara adugbo wi pe ẹni karun un ni yii laarin oṣu kan ti wọn ti da ẹmi wọn legbodo lagbegbe yii.

Bẹẹ ni wọn kesi ijọba lati ṣeranwọ fun wọn, ki oju awọn aṣebi yii tete han sita.