Drug Trafficking: Obìnrin méjìlá ló wà lára àwn olóògùn olóró náà

Awọn osisẹ ajọ NDLEA meji

Oríṣun àwòrán, NDLEA

Ọwọ palaba awọn eeyan to le ni aadọjọ to n gbe oogun oloro ti segi bayii, ti wọn si ti wa ni ahamọ ajọ to n dena ilokulo oogun oloro.

Ajọ NDLEA nipinlẹ Ondo lo kede bẹẹ nibi ipade akọroyin kan to se nilu Akure lọjọ Ẹti.

Oludari ajọ NDLEA nipinlẹ naa, Haruna Gagara ni wọn se ipade akọroyin ọhun lati fi sami ayajọ gbigbogun ti ilokulo oogun ati gbigbe oogun oloro fun tọdun yii ni.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Gagara fikun pe ọwọ tẹ awọn aadọjọ agboogun oloro naa laarin osu kinni si osu kẹfa ọdun 2020.

O ni ninu aadọjọ awọn oloogun oloro naa, mejila ninu wọn lo jẹ obinrin.

Laarin akoko ti wọn mu awọn eeyan naa, iwọn oogun oloro to to kilo ẹgbẹrun lọna mẹjọ o din diẹ, ni wọn ka mọ wọn lọwọ.

Oogun oloro

Oríṣun àwòrán, NDLEA

Ninu wọn ni iwọn ẹgbẹrun meje o le diẹ kilo Igbo mimu wa, ti iyoku si jẹ oogun oloro Cocaine.

Gagara tẹsiwaju pe lọjọ Ẹti nikan, apo igbo marundinlaadọrin ni wsn ri gba ni agbegbe Agunla-Ogbese.

O wa rọ awọn eeyan ti ọrs gbigbogun ti ilokulo oogun oloro kan lati maa gbe igbesẹ to yẹ nidi didẹkun asa buburu yii.

Oogun oloro

Oríṣun àwòrán, NDLEA

To si tun bẹbẹ fun agbekalẹ awọn eto ilanilọye fawọn ọdọ lati dena mimu oogun oloro ati gbigbe rẹ.

Gagara tun mẹnuba pe aisi ọkọ ayọkẹlẹ lati rin pẹlu owona wa lara isoro to n koju ajọ naa lati sisẹ rẹ deede.