Ibadan Murder: Shagbada pa ọ̀rẹ́bìnrin torí kò gbà kó bá a lò pọ̀

Oríṣun àwòrán, Others
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo ti fi oju ẹni ọdun mẹrinlelogun kan han, lẹyin ti wọn fẹsun kan an pe o pa ọrẹbinrin rẹ Happiness Winfred ni ij̣oba ibilẹ Akinyele ni ilu Ibadan.
Afurasi naa, Shagbada Erigga, jẹwọ pe lootọ ni oun hu iwa ọdanran yii nigba ti wọn fi oju rẹ atawọn afurasi mejilelọgbọn miran han.
Ẹni ọgbọn ọdun ni arabinrin Hapiness ti ọrẹkunrin rẹ pa tori ibalopọ.
Nigba ti awọn akọroyin fi ọrọ wa lẹnu wo, afurasi naa ni lootọ ọrẹbinrin oun ni, ṣugbọn wahala bẹ silẹ laarin wọn nitori ko gba ki o ba a lo pọ.
O ni ibi ti wọn ti n ṣe ariyanjiyan lori idi ti ko ṣe gba ki o ba a ni ṣe pọ ni oun ti fun un ni ẹṣẹ mẹta pere, to si gba'bẹ dagbere faye.
Nigba to n jabọ fun awọn akọroyin lori iṣẹlẹ naa, Kọmiṣọna ọlọpaa nipinlẹ Oyo, Joe Nwachukwu Enwowu sọ pe ọwọ tẹ Erigga lẹyin ti wọn fi ọrọ rẹ sun ni ẹka ileeṣẹ ọhun to wa ni agbegbe ̣Ojoo.
O ni ọkunrin kan, Agu Benson lo fi to awọn ọlọpaa leti ni Ogunjọ, Oṣu Kẹfa, ọdun 2020 pe oun ri oku eeyan ninu kanga ile rẹ.
- Egúngún kan rèé tí kò bìkíáfù, ó kọjú ìjà sí ọlọ́pàá pẹ̀lú ohun ìjà olóró
- Àwọn ògo Ibadan márùn ún tí ikú mú lọ lọ́dún 2020
- Bẹ́ ẹ fẹ́, bẹ́ ẹ kọ̀, July ni ẹjọ́ Sotitobire yóò parí - Adájọ́ gbọmú
- Arúfin ni Seyi Makinde pẹ̀lú bó ṣe gbà kí wọ́n sin Ajimobi sí GRA - Amòfin
- Mo ti lùgbàdì àrùn Coronavirus - Akeredolu figbe ta
Kọmiṣọna ọlọpaa naa ṣalaye siwaju sii pe iwadii ati iṣẹ takuntakun ileeṣẹ ọlọpaa lo jẹ ki wọn ri afurasi ọhun mu.
O ni "Happiness Winfred kuro ni ile rẹ lọjọ Aiku, Ọjọ Kọkanlelogun, Oṣu Kẹfa, ọdun 2020,
Ṣugbọn inu kanga ni wọn ti ri oku rẹ ni Ọjọ Karundinlọgbọn. oṣu kan naa ninu ile kan lagbegbe Oritoke, ni Ojoo, ni ilu Ibadan."
"Ni bayii ti ọdanran naa ti jẹwọ, yoo foju bale ẹjọ laipẹ."
Akinyele tún gbàlejò àwọn mùjẹ̀mùjẹ̀, tìyá-tọmọ̀ fara gbọgbẹ́
Isẹlẹ ikọlu miran tun ti waye ni agbegbe Akinyele nilu Ibadan ni idaji ọjọ Aiku.
Lọtẹ yii, arabinrin kan, Adeola Bamidele ati ọmọ rẹ obinrin, Dolapo, ni awọn agbebọn kan kọlu ninu ile wọn.

Oríṣun àwòrán, Others
Deede aago kan oru ni isẹlẹ naa waye , tawọn afurasi ọdaran naa si gba ẹrọ ibaraẹnisọrọ alagbeka meji .
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ẹ pèsè ẹlẹ́rìí púpọ̀ bí bẹ́ẹ̀ kọ́, Sotitobire yóò jẹ́rìí fúnrarẹ̀ o! - Ilé ẹjọ́ ìpínlẹ̀ Ondo
- Ilé ìwòsàn kan rèé tó ń fi àtùpà gbẹ̀bí aláboyún
- Àwọn ìjọba ìbílẹ̀ méjìdínlógún yìí kò tíì lè bọ́ lọ́wọ́ ìséde - Ìjọba àpapọ̀
- Ìrìnà ọkọ̀ akérò àti ọkọ̀ òfurufú bẹ̀rẹ̀ padà jákèjádò Nàìjíríà!
- Òfin ìjọba de ọdún eégún ìlú Ibadan,eégún Olóòlù kò ni kọ́ja agboolé rẹ̀!
- Ṣé ó leè jẹ́ ilẹ̀ tí Makinde kò jẹ́ kí Florence Ajimobi gbà ló ń bi nínú?
Bakan naa ni wọn sa tiya-tọmọ lọgbẹ ni ori, ti awọn mejeeji si wa nile iwosan fun itọju.
Nigba to n salaye bi isẹlẹ naa se waye, arabinrin Adeola, tii se ẹni ọdun marundinlaadọta ni ada ni awọn afurasi ọhun fi sa oun lasiko ti oun n du ẹmi ọmọ oun lọwọ ikọlu, ti oun si ba ara oun ninu agbara ẹjẹ.
Amọ Dolapo, tii se ẹni ọdun mẹtalelogun ko lee sọrọ rara nitori oro ọgbẹ ada ti wọn sa a, eyi to jin wọnu.
Nigba to n fi idi isẹlẹ naa mulẹ fun BBC Yoruba, osisẹ alarena fun ileesẹ ọlọpaa nipinlẹ Ọyọ, Olugbenga Fadeyi salaye pe lootọọ ni ikọlu ọhun waye.
Fadeyi ni ọwọ ti tẹ awọn afurasi kan lori awọn iwa isekupani ati ikọlu to n waye lagbegbe Akinyele naa.
Bakan naa lo fi kun pe lọsan oni ni wọn yoo se afihan awsn afurasi to wa nidi isẹlẹ Akinyele naa ni olu ileesẹ ọlọpaa to wa ni Ẹlẹyẹle nilu Ibadan.
A o ranti pe o ti to obinrin mẹrin ati ọkunrin kan, Mujeeb Tirimisiyu, Barakat Bello, Grace Oshiagwu, Azeezat Shomuyiwa ati Olusayo Fagbemi, ti wọn ti pa ni Akinyele naa.
Ìbánújẹ́ gbọkàn àwọn èèyàn nílé abílékọ ọlọ́mọ mẹ́ta tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ pa ní Ibadan

BBC ṣe abẹwo si ile arabinrin Oluṣayọ Fagbemi, abilekọ ẹni ọdun mejilelogoji ti awọn amokunṣeka kan tun ṣekupa l'owurọ Ọjọru ni agbegbe Ṣaṣa, ijọba ibilẹ Akinyẹle niluu Ibadan.
Oṣojumikoro fi idi ọrọ naa mulẹ fun awọn akọroyin wi pe abọ́ ni arabinrin naa n fọ ni iwaju ile ni idaji ọjọ naa ki awọn olubi ẹda to ṣe ikọlu sii.
Ariwo rẹ ni ọkọ rẹ gbọ ti o si sare si ibi ti aya rẹ ti n fọ abọ sugbọn epa ko ba oro mọ.
Inu agbara ẹjẹ lo ti ba aya rẹ pẹlu apa ibi ti wọn ti fi nnkan ṣaa lori ti wọn si salọ.
Ọkan lara awọn aladugbo ti o ba wa sọrọ, Ọgbẹni Lateef Nurudeen ṣe alaye wi pe ni nnkan bii aago marun un idaji ti wọn maa n lọ kirun n wọn deede gbọ ti ọkọ oloogbe n pariwo "ẹ gba mi o".
Wọn ni bẹẹ naa lo tun n pariwo orukọ iyawo rẹ, ṣugbọn ninu agbara ẹjẹ ni wọn ti ba iyawo naa.

O tẹsiwaju wi pe o fẹẹ to bii iṣẹju mẹwaa ki wọn to ri arabinrin naa gbe kuro ninu agbara ẹjẹ lọ si ile iwosan, ṣugbọn igbiyanju wọn ja si pabo.
Wọn parọwa si ijọba ati awọn agbofinro lati fi oju ṣebi han.

Ọmọ mẹta ni oloogbe fi silẹ saye lọ, mẹji ninu wọn wa laarin ọmọ ọdun mẹrin si mẹfa.
Iroyin si ti fi idi ẹ mulẹ wi pe iya wọn ṣii n pọn abigbẹyin ni.

BBC gbiyanju lati ba ọkọ oloogbe sọrọ, ṣugbọn a ko ri wọn ni ayika ile naa lasiko ti abẹwo si ibe.

Nibayii, ile iṣe ọlọpaa ni ipinlẹ Ọyọ tun ti jẹjẹ lati ṣawari awọn ọdaran ti o fẹ sọ ijọba ibilẹ Akinyẹle di ibi ẹru fun awọn olugbe ipinlẹ Ọyọ.
Ninu atẹjade ti wọn fun lede gbatọwọ alukoro ile iṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ọyọ, Olugbenga Fadeyi ṣe alaye iṣẹ iwadii ti bẹrẹ ni pẹrẹu.

Mùjẹ̀-mùjẹ̀ ní Akinyele tún ti mu ẹ̀jẹ̀ obìnrin míràn lónìí
Kaka ki ewe agbọn dẹ ni adugbo Akinyele nilu Ibadan ti wọn ti n pa awọn eeyan lẹnu ọjọ mẹta yii, ko ko ko lo n le si i.

Idi ni pe wọn tun ti pa obinrin miran,Olusayo Fagbemi, ladugbo Akinyele naa yatọ si Mujeed ti wọn pa nibẹ lọjọ Iṣẹgun.
Nigba to n fidi isẹlẹ naa mulẹ, osisẹ alarina fun ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo, Olugbenga Fadeyi ni aago marun idaji Ọjọru ni wọn pa obinrin naa.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Èyí ni àwọn arẹwà ‘ẹ̀lẹ̀ Daddy’, àfẹ́fẹ́ tí Aláàfin fi ń mí
- Oyè adelé alága APC bọ́ lọ́wọ́ Ajimobi, Buhari fòǹtẹ̀ lu Giadom
- Ọkùnrin kan bá ọmọ oṣù mẹ́ta lòpọ̀, ìfun ọmọ tú jáde!
- APC kò ní olórí tí yòó tọwọ́ bọ̀wé, INEC yarí fún ìbò abẹ́nú l‘Ondo
- Ìhòhò ọmọlúàbí ni mo má a ń bá àwọn ọmọkùnrin mi wí - Elesho
- Ọ̀dàlẹ̀ ni Igbákejì Gómìnà, kìí ṣe pé a dẹ́yẹ si - ìjọba Ondo
"Ni deede aago mẹfa ku ogun isẹju ni idaji Ọjọruni wọn kọlu obinrin kan, Olusayo Fagbemi, ẹni ọdun mejilelogoji, lasiko to n fọ abọ niwaju ile rẹ, to si ni ọgbẹ lori."
Fadeyi tẹsiwaju pe ariwo obinrin naa lo mu ki ọkọ rẹ sare jade lati inu ile, to si ba iyawo rẹ ninu agbara ẹjẹ, ti awọn eeyan to sisẹ laabi naa si ti fẹsẹ fẹ ẹ.
O ni wọn gbe obinrin naa lọ sile iwosan amọ ẹpa ko boro mọ nitori obinrin naa ti jade laye.
Ileesẹ ọlọpaa ni aayan ti n lọ lọwọ lati sawari awọn olubi ẹda naa.
A o ranti pe o ti to obinrin mẹrin ati ọkunrin kan, Mujeeb Tirimisiyu, Barakat Bello, Grace Oshiagwu, Azeezat Shomuyiwa ati Olusayo Fagbemi, ti wọn ti pa ni Akinyele naa, ti awọn ọlọpaa ko si ti mọ awọn eeyan to pa wọn.

Oríṣun àwòrán, Other














