Ogun Flood: Ọ̀pọ́ Dúkìá ló sọnù ní 2019 lásìkò tí ìjọba ṣí dáàmù Ọyan
Awọn ara agbegbe Iṣheri ti ke gbajare si ijọba lati dawọ duro lori igbese wọn lati ṣi daamu Oyan laipẹ.
Awọn to ba BBC Yoruba sọrọ ṣe afihan dukia ati ohun ini wọn to ṣofo ni ọdun 2019 lasiko ti wọn ṣi daamu naa.
Wọn salaye wi pe gbogbo ọna ni omi naa ma n gba ti awọn eniyan a si maa lo ọkọ oju omi kekere lati kọja loju popo.
Wọn fikun wi pe ọpọlọpọ onile lo ti ṣofo ohun ini wọn, ti wọn si ti fi agbegbe naa silẹ lẹyin igbiyanju wọn.
"Ẹẹkan ni ọdun mẹta ni ijọba ma n ṣi i tẹlẹ, ti a si ma n gbaradi fun un, amọ lati ọdun mẹrin sẹyin ni wọn ti n ṣi i lọdọọdun."
Nibayii, wọn rọ ijọba lati ran wọn lọwọ nitori ẹkun omi to ma n waye ni gbogbo igba ti wọn ba ti ṣi daamu naa.