Osun Police: Ọlọ́pàá gba òògùn ìbílẹ̀, ìbọn, àáké àti àdá lọ́wọ́ egúngún

Oríṣun àwòrán, Others
Ìlúmọ̀ọ́ká egúngún kan ní ìlú Ede, ìpínlẹ̀ Osun ti kó sí panpẹ́ ọlọ́pàá nítorí pé ó ń da ìpayà sílẹ̀ láàrín ìlú.
Ìròyìn sọ pé, awọn ènìyàn n fóri gbárí lásìkò tí eégún náà jáde nílu Ede, tí ọkùnrin kan, Mukaila Ismaila sì fàrapa yánayàna, ti wọn si ti gbe lọ sílé ìwòsàn.
Àwọn tí ọ̀rọ̀ náà sóju wọ́n sàlàyé pé, àwọn tó n tẹ̀lé eégún náà kó onírúurú ǹkan ìjà tó léwu lọ́wọ́, ìdí nìyìí tí wọ́n fi mú ẹjọ́ náà lọ sọ́dọ ọlọ́pàá.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Arúfin ni Seyi Makinde pẹ̀lú bó ṣe gbà kí wọ́n sin Ajimobi sí GRA - Amòfin
- Àwọn ògo Ibadan márùn ún tí ikú mú lọ lọ́dún 2020
- Mo ti lùgbàdì àrùn Coronavirus - Akeredolu figbe ta
- Ṣé ó leè jẹ́ ilẹ̀ tí Makinde kò jẹ́ kí Florence Ajimobi gbà ló ń bi nínú?
- Akinyele tún gbàlejò àwọn mùjẹ̀mùjẹ̀, tìyá-tọmọ̀ fara gbọgbẹ́
- Ẹ pèsè ẹlẹ́rìí púpọ̀ bí bẹ́ẹ̀ kọ́, Sotitobire yóò jẹ́rìí fúnrarẹ̀ o! - Ilé ẹjọ́ ìpínlẹ̀ Ondo
- Ilé ìwòsàn kan rèé tó ń fi àtùpà gbẹ̀bí aláboyún
Lẹ́yìn èyí ni ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá dá àwọn ẹsọ́ aláàbò sí ibi ìṣẹ̀lẹ̀ náà, sùgbọ́n nígbà ti wọ́n dé bẹ̀, àwon ọmọ lẹ́yìn eégún kọjú ìjà sí àwọn ọlọ́pàá pẹ̀lú ìbọ̀n.
Ọwọ́ sìnkún ọlọ́pàá ba èniyàn mẹ́fà nínú wọ́n, to fi mọ eégún ọ̀ún fúnra rẹ̀.

Oríṣun àwòrán, Others
Kọ́mísọ́nà ọlọ́pàá ní ìpińlẹ̀ Osun Undie Adie fìdí ọ̀rọ̀ náà múlẹ̀, nípa bí wọ́n ṣe mú eégún àti àwọn ìsọmọ̀gbè rẹ̀.
Àwọn nǹkan ti wọ́n gbà lọ́wọ́ wọ́n ni òògùn, ìbọ́n ìgbàlodé kan, ìbọ̀n ọdẹ kan, àdá méjì, ààké àti gángan mẹ́rin.
Ọ̀gá ọlọ́pàá náà sàlàyé pé, àti eégún àti àwọn tókù rẹ̀ kò ni lọ láì jìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọ́n.













