APC news in Ondo State: Yahaya Bello ni alága ìgbìmọ ìdìbò abẹ́lé gónìnà ìpińlẹ̀ Ondo

Egbẹ́ òṣèlú APC nípìnlẹ̀ Ondo ti yan Gómìnà Kogi Yahaya Bello gẹ́gẹ́ bi alága ìgbìmọ̀ ìdìbò abẹ́lé fún àwọn olùdíje fun ipo gómìnà nípìnlẹ̀ Ondo.
Èyí jẹyọ nínú àtẹ̀jáde kan ti àkọlé rẹ̀ ni "Gómìnà Yahaya Bello gẹ́gẹ́ bi alága ìdìbò abẹ́lé ìpínnlẹ̀ Ondo" tí ìgbákejì akọ̀wé ìpolongo apapọ̀ ẹgbẹ́ buwọ́lù, Yekini Nabena nílùú Abuja lọ́jọ́rú.
Nínú àtẹ̀jáde náà ni wọ́n ti kọọ́ wí pé, ṣaájú ìdìbò abẹ́lé ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress ti yóò wáye ni ìpińlẹ̀ Ondo ní ogúnjọ oṣù kèje, ọdún 2020, lábẹ́ gómìnà ìpínlẹ̀ Yobe Mai Mala Buni tó ń jẹ́ adelé alága ètò àti ìpètù sááwọ̀ ẹgbẹ́.
Gómìnà ìpińlẹ̀ Kogi, Yahaya Bello ni yóò jẹ́ alága ìgbìmọ̀ ìdìbò abẹ́lé, nígbà ti Emperor Chris Baywood Ibe yóò jẹ́ alága ìgbìmọ̀ to ń pètù sí ààwọ̀ ìdìbò abẹ́lé.
"Àwọn ọmọ ìgbìmọ̀ ìdìbò abẹ́lé ìpińlẹ̀ Ondo"
1. H.E. Yahaya Bello - Alága
2. Olorogun o'tega Emerhor OON - Akọ̀wé
3. Alwan Hassan - Ọmọ ẹgbẹ́
4. Chief Samuel Sambo - Ọmọ ẹgbẹ́
5. Hajiya Binta Salihu - Ọmọ ẹgbẹ́
6. Mr. Emma Andy - Ọmọ ẹgbẹ́
7. Dr. Adebayo Adelabu - Ọmọ ẹgbẹ́
8. Abdullahi Aliyu - Ọmọ ẹgbẹ́
9. Mrs. Margret Ngozi Igwe - Ọmọ ẹgbẹ́
Àtẹ̀jáde ọ̀hún náà tún dárúkọ àwọn ọmọ ìgbìmọ̀ tí yóò pẹ̀tù sááwọ̀ to bá súyọ lẹ́yìn ìdìbò abẹ́lé
1. Emperor Chris Baywood Ibe - Alága
2. Arch. Abdulmimuni Okara - Akọ̀wé
3. Mr. Festus Fientes - Ọmọ ẹgbẹ́
4. Mr. Okon Owoefiak - Ọmọ ẹgbẹ́
5. Mr. ABBA Isah - Ọmọ ẹgbẹ́
6. Alh. Umar Duhu -Ọmọ ẹgbẹ́
7. Hon. Sani El-katuzu - Ọmọ ẹgbẹ́
8. Mrs. Osuere Eunice - Ọmọ ẹgbẹ́
9. Emeka Agaba - Ọmọ ẹgbẹ́
O ní adelé alága APC yóò maa ṣàfilọ́lẹ̀ àwọn ọmọ ìgbìmọ̀ méjèèjì ní olú ilé ]ẹgbẹ́ ni ilú Abuja ní aago mẹta ọ̀sán ọjọ́ Ẹti, ọjọ́ kẹtàdinlógun, oṣù keje, ọdun 2020
Mi ò tíì gba ìwé ìfitónilétí pé wọ́n fẹ́ yọ mí nípò- Igbákejì gómìnà ìpínlẹ̀ Ondo

Oríṣun àwòrán, @RotimiAkeredolu
Igbakeji gomina ipinlẹ Ondo, Agboola Ajayi ti sọ pe oun ko tii gba iwe ifitonileti pe ile igbimọ aṣofin ipinlẹ ọhun fẹ yọ oun nipo.
Ajayi lo fi ọrọ naa lede nigba to ba BBC Yoruba sọrọ lori aago.
O ni "Wọn ko tii fun mi ni iwe ifitonileti kankan o, mi o tii gba iwe kankan."
Ṣaaju ni iroyin kan ti kọkọ jade pe akọwe ile naa, Adeyelu Bode sọ pe ile ọhun ti fun Agboola Ajayi ni iwe ifitonileti naa.
Iroyin naa ṣalaye pe lara ẹsun ti awọn aṣofin naa fi kan igbakeji gomina ọhun ni iwa aṣemaṣe lẹnu iṣẹ, ṣiṣowo ilu baṣubaṣu, aṣilo ipo, eyii to lee da oju ijọba bolẹ, atawọn ẹsun miran.

Oríṣun àwòrán, Olowu Idowu Henry
Ṣugbọn igbakeji gomina naa fidi rẹ mulẹ fun BBC Yoruba pe ọrọ ko ri bẹ nitori ohun ko tii ri iwe kankan gba.
Wahala bẹ silẹ laarin gomina ipinlẹ Ondo, Rotimi Akeredolu ati igbakeji rẹ lẹyin ti Ajayi fi ẹgbẹ oṣelu APC silẹ lọ darapọ mọ ẹgbẹ PDP.
- Àṣírí tú! Ẹ̀rọ ayàwòrán ara ọlọ́pàá fihàn pé ìgbà ogún ni George Floyd pariwo, kó tó kú
- Iléesẹ́ rẹ́kọ́ọ̀dù tí mo ti bẹ̀bẹ̀ láti kọrin, padà di tèmi lónìí - Ebenezer Obey
- Ọ̀pá epo NNPC bú gbàmú ní Benin, òṣìṣẹ́ méje kàgbákò ikú òjijì
- Ọ̀fọ̀ ńlá ṣẹ̀ ní Ivory Coast, Olóòtú ìjọba, Amadou Gon Coulibaly jáde láye
Ko pẹ to gbe igbesẹ yii ti awuyeweuye iyọnipo naa bẹrẹ, ti mẹrinla lara awọn aṣofin ile si gbe igbesẹ lati yọ igbakeji gomina ọhun nipo, ṣugbọn mẹsan an lara wọn ni wọn ko ni lọwọ sii.
Ki lo ti ṣẹlẹ sẹyin?
Ondo Crisis: Ẹ̀ṣùn kan ṣoṣo tí ilé aṣòfin fi le yọ igbákejì gómìnà ní tó bá tàpá ṣófin ilẹ̀ wa

Oríṣun àwòrán, Ondo Assembly
Ile asofin ipinlẹ Ondo ti bẹrẹ igbesẹ lati yọ igbakeji gomina ipinlẹ naa, Agboola Ajayi nipo rẹ.
Kii ṣe iroyin tuntun mọ pe aarin Gomina Ipinlẹ Ondo, Oluwarotimi Akeredolu ati Igbakeji rẹ, ko dan mọran mọ.
Eyi ko si sẹyin bi igbakeji rẹ se kuro ni ẹgbẹ oṣelu APC lọ si PDP, lati dije du ipo Gomina ninu eto idibo ti yoo waye ni Oṣu Kẹwa, ọdun yii.
Awọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Akeredolu, aya àti ẹbí rẹ̀ ló ń ṣèjọba ni mo ṣe fipò sílẹ̀ - Akọ̀wé ìjọba tẹ́lẹ̀ l‘Ondo
- Àlàyé rèé lórí ìdí tí Magu àti awọn alága EFCC míràn ṣe bá ìtìjú kúrò nípò
- Àwọn ẹlẹ́sìn ìbílẹ̀ ń bèèrè owó lọ́wọ́ àwọn Alfa lórí ìsìnkú ẹni tó pokùnso
- Hushpuppi di gbajúmọ̀ ẹlẹ́wọ̀n tó ní nọ́ńbà l‘Amẹrika, orúkọ̀ rẹ̀ wà lórí ayélujára
- Nǹkan tí ojú rí rè é bí pápákọ̀ òfurufú ṣe di ṣíṣí padà ní Nàìjíríà
- Ṣé lóòtọ́ ni Lateef Adedimeji àti Adebimpe Oyebade ṣe ìgbéyàwó?
Lọwọ-lọwọ bayii, awọn aṣofin mẹrinla ninu mẹtalelogun ti buwọlu yiyọ Igbakeji Gomina ipinlẹ Ondo, Agboola Ajayi ni ipo.
Sugbọn ki igbesẹ yii to lee waye, ofin wa ti awọn asofin naa gbọdọ tẹle, nitori wọn ko le dede yọ Igbakeji Gomina ni ipo.
Labẹ ofin orilẹede Naijiria, ẹsun kan ti Ile Igbimọ Aṣofin Ipinlẹ le fi kan Igbakeji Gomina lati yọ ni ipo, ni ti tapa si ofin orilẹede Naijiria.
Nibayii, ẹ jẹ ka wọ awọn igbesẹ ti Ile Aṣofin Ipinlẹ Ondo gbọdọ tẹle lati yọ Agboola Ajayi ni ipo, gẹgẹ bi ofin Naijiria se laa kalẹ.
Igbesẹ Kinni:
- Ohun akọkọ ni lati fi iwe ẹsun wiwu iwa aitọ ranṣẹ si Igbakeji Gomina
- Ida mẹta awọn aṣofin lo gbọdọ bu ọwọ lu iwe ẹsun yii, ti olori Ile Aṣofin si gbọdọ fi ọwọ si.
Igbesẹ Keji:
- Abẹnugan Ile Aṣofin gbọdọ fi iwe ẹsun ranṣẹ si Igbakeji Gomina laarin ọjọ meje, yoo si fi ranṣẹ si awọn ọmọ Ile Aṣofin pẹlu.
Igbesẹ Kẹta:
- Igbakeji Gomina naa le kọ iwe esi ranṣẹ pada lori ẹsun ti wọn fi kan an, ti o ba wu u.
Igbesẹ Kẹrin:
- Laarin ọjọ mẹrinla ti awọn aṣofin ba ti fun olori ile ni iwe ẹsun, awọn aṣofin yoo dibo lati mọ boya ki wọn ṣe iwadii ẹsun magomago ti wọn fi kan Igbakeji Gomina naa
- Ida meji ninu mẹta awọn aṣofin lo gbọdọ fi ọwọ si igbesẹ yii, ki o to le kẹsẹjari.
Igbesẹ Karun:
- Ti ida meji ninu mẹta awọn aṣofin ko ba buwọlu igbesẹ Kẹrin, wọn yoo da igbesẹ lati yọ Igbakeji Gomina naa duro lẹsẹkẹsẹ
- Amọ, ti ida meji ninu mẹta awọn aṣofin ba buwọlu igbesẹ Kẹrin naa, olori ile Aṣofin, laarin ọjọ meje, yoo kọ lẹta si Adajọ agba nipinlẹ Ondo lati gbe igbimọ kalẹ, ti yoo ṣe iwadii ẹsun ti wọn fi kan Igbakeji Gomina naa
- Amọ, awọn Igbimọ naa ko gbọdọ jẹ oloṣelu, oṣiṣẹ ijọba tabi aṣofin.
Igbesẹ Kẹfa:
- Igbimọ yii gbọdọ fi esi iwadii rẹ sita laarin oṣu mẹta ti wọn ba gbe kalẹ, ti yoo fi iwadii rẹ ṣọwọ si Ile asofin Ipinlẹ
- Lasiko ti Igbimọ naa ba n ṣe iwadii wọn, Igbakeji Gomina ni anfaani lati ro ẹjọ tako ẹsun ti wọn fi kan an, bẹẹ lo si ni aṣẹ lati gba agbẹjoro ti yoo tako ẹsun naa.
Igbesẹ Keje:
- Ti Igbimọ naa ba kede pe Igbakeji Gomina ko jẹbi ẹsun ti wọn fi kan an, iwadii naa pin si bẹ niyẹn
- Amọ ti Igbimọ naa ba ni Igbakeji Gomina jẹbi ẹsun ti wọn fi kan an, awọn aṣofin yoo gbeyẹwo, ti wọn yoo si dibo lori boya ki wọn gba abajade Igbimọ naa wọle.
Igbesẹ Kẹjọ:
- Ki esi Igbimọ naa to le fi ẹsẹ mulẹ, ida meji ninu mẹta awọn aṣofin ni Ile Igbimọ Aṣofin naa gbọdọ buwọlu
- Ni kete ti wọn ba ti buwọlu naa ni Igbakeji Gomina naa yoo fi ipo rẹ silẹ ni kiakia.
Ilé aṣòfin Ondo bẹ̀rẹ̀ ìgbésẹ̀ láti yọ igbákejì gómìnà nípò

Ile asofin nipinlẹ Ondo ti pasẹ pe ki wọn fun igbakeji gomina nipinlẹ naa, Agboola Ajayi ni iwe ifitonileti pe awọn fẹ rọ ọ loye.
Olori ile, Bamidele Oleyelogun lo pasẹ bẹẹ lasiko ijoko ile to waye lọsan ọjọ Isẹgun.
Bakan naa lo sisọ loju rẹ pe awọn asofin mẹrinla lo fi ọwọ siwe pe ki wọn rọ igbakeji gomina naa loye, ninu asofin mẹrindinlọgbọn to wa nibẹ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ṣé lóòtọ́ ni Lateef Adedimeji àti Adebimpe Oyebade ṣe ìgbéyàwó?
- Kòṣẹlẹ̀rí ni Hajj ọdún 2020, wo ìyàtọ̀ tó wà nínú rẹ̀ sí ti tẹ́lẹ̀
- Ẹ̀yin ẹlẹ́gbẹ́ òkùnkùn tẹ fẹ́ ṣe àjọ̀dún lónìí, lákọ la ń dúró dè yín - Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá
- Ìjọba Akeredolu kò ní omi àánú lójú, a kò tọ́jú alárùn Coronavirus mọ́ - Dókítá Ondo
- Bí àwọn adarí ìjọba ṣe ń kó Coronavirus, ń kọ wá lóminú - Ìjọba àpapọ̀
Ọrọ iyọnipo igbakeji gomina naa si lo lewaju ijiroro ile asofin naa, to pada wọle lẹyin isisnmi ranpẹ ti wọn lọ fun.
Lasiko ijokoo ile naa, asofin mẹsan lo fọwọsi iwe pe awọn ko fara mọ iyọnipo igbakeji gomina naa.

Oríṣun àwòrán, Ondo state House of Assembly
Lẹyin ti ile se agbeyẹwo abala ofin to yẹ nipa igbesẹ rẹ ọhun lo wa pasẹ pe ki wọn lọ fun igbakeji gomina, Agboola Ajayi ni iwe ifitonileti pe wọn fẹ rọ ọ loye.
Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ lẹyin ijoko ile, Asofin Gbenga Omole, tii se alaga igbimọ ile feto iroyin kede pe ile ko tii gba irufẹ iwe ikede bẹẹ.
Omole ni ọla Ọjọru ni wọn yoo mọ bi ohun gbogbo yoo se lọ lori ọrọ iyọnipo naa.

Ẹwẹ, awọn asofin to jẹ ọmọ ẹgbẹ oselu to kere julọ nile asofin naa, ti kọ lati fi ọwọ si iwe iyọnipo igbakeji gomina.
Awọn asofin naa lo n fi apa janu pe ile ko fun awọn ni aaye lati gbọ aroye awọn.
- Àkójọ́pọ̀ àwòrán rèé lórí bí ìwọlé akẹ́kọ̀ọ́ ṣe lọ sí ní Oyo
- Bí Hushpuppi ṣe tiraka rèé l‘Eko, kí ọlà ‘òjijì’ tó dé
- Akẹ́kọ̀ọ́ wọlé padà, ìjọba Oyo kò pèsè ìbòmú lòdì sí ìlérí rẹ̀
- Ẹ wo bí ọ̀rọ̀ òṣèlú, ẹ̀sìn àti ẹ̀yà ṣe fa ogun abẹ́lé Biafra
- Kàkà k‘éwé àgbọn dẹ̀ lágbo òṣèlú l‘Ondo, akọ̀wé ìjọba tún kọ̀wé fipò sílẹ̀
- Ẹ wo bí ọ̀rọ̀ òṣèlú, ẹ̀sìn àti ẹ̀yà ṣe fa ogun abẹ́lé Biafra
Bẹẹ ba gbagbe, laipẹ yii ni igbakeji gomina nipinlẹ Ondo kuro ninu ẹgbẹ oselu APC, to si dara pọ mọ ẹgbẹ oselu alatako, PDP.
Bi o tilẹ jẹ pe agbẹnusọ fun ijọba ipinlẹ Ondo sọ fun awọn akọroyin pe, wọn ko ni yọ igbakeji gomina naa nipo nitori pe o fi ẹgbẹ oselu APC silẹ.
Amọ aarọ ọjọ Isẹgun ni igbakeji gomina naa lọ sile ẹjọ lati beere pe ki ile ẹjọ da ile asofin ipinlẹ Ondo lọwọ kọ, lati mase yẹ aga mọ oun nidi.
Akeredolu, tó ò bá fa àkóso Ondo lé mi lọ́wọ́ láàrin ọjọ́ 21, o tàpá sófin - Igbákejì gómìnà

Oríṣun àwòrán, @RotimiAkeredolu
Ọrọ ti n ba ọrọ bọ nipinlẹ Ondo lori bi ajọsepọ to wa laarin gomina Rotimi Akeredolu ati igbakeji rẹ.
Idi ni pe igbakeji gomina, Agboola Ajayi ti kede pe ki Akeredolu tete fa akoso ipinlẹ naa le oun lọwọ laarin ọjọ mọkanlelogun nibayii to to wa ni iyasọtọ nitori arun Coronavirus to lugbadi rẹ.
Bẹẹ ba gbagbe, igbakeji gomina naa lo ti kuro ninu ẹgbẹ oselu APC lọ si PDP, ti ọrọ si ti n lọ kaakiri pe o seese ko gbe igba ibo gomina bii oludije fun ẹgbẹ oselu PDP naa.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ọ̀pọ̀ ìgbà ní Hushpuppi àtàwọn èèkàn PDP ti ya fọ́tò ní Dubai, EFCC ẹ wádìí wọn - APC ń lọgun
- Bí àdúrà Fìdáù ọjọ́ mẹ́jọ fún Abiola Ajimobi yóò ṣe lọ lónìí rèé
- Obìnrin kan wọ gàù lẹ́yìn tó kan ìṣó mọ́ ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ ẹni ọdún mẹ́wàá lórí
- Bàbá Aláàfin ìlú Ọ̀yọ́, Elérúwà àti àwọn Ọba Ilẹ̀ Yorùbá míràn tí wọ́n rọ̀ lóyè
- Ìjọba Nàìjíríà ti mú Dókítà Anu tí àwọn kan f'ẹ̀sùn kàn pé ayédèrú iṣẹ́ abẹ ìdí ló n ṣe
Ninu atẹjade kan ti akọwe iroyin igbakeji gomina ọhun, Allen Sowore fisita, Ajayi tọkasi abala ofin ilẹ wa tọdun 1999, ori ọgọsan, ẹsẹ keji, eyi to laa kalẹ pe, o yẹ ki Akeredolu fa akoso ipinlẹ naa le oun lọwọ ni.
O fikun pe "Bi gomina ba wa kọ lati fa akoso le emi igbakeji rẹ lọwọ lasiko to wa ni iyasọtọ yii, a jẹ pe o tapa si ofin ilẹ wa ni, to si foju tẹnbẹlu awọn eeyan ati ofin ilẹ wa to jẹjẹ lati tẹle."
Bakan naa lo ni "ipinnu Akeredolu lati mase jẹ ki isejọba tẹsiwaju lasiko to wa ni iyasọtọ yii nitori arun Coronavirus fihan pe, ẹnu lasan lo fi n gbogun ti arun Covid-19 to n ja rain nilẹ."
Mi ò mọ ohunkóhun nípa "Aketi Whyski" - Akeredolu ké gbàjarì

Oríṣun àwòrán, others
Saaju la ti mu iroyin wa fun yin pe gomina ipinlẹ Ondo, Rotimi Akeredolu ti ke gbajari sita pe, oun ko mọ ohunkohun nipa ọti lile kan ti wọn kọ akọle "Aketi" si lara.
Akeredolu lo sọ bẹẹ ninu atẹjade ti oluranlọwọ pataki rẹ lori ọrọ to n lọ, Ojo Oyewamide fi lede.
Igbeṣẹ yii lo n waye lẹyin ti fidio kan gbode lori ayelujara, eyi to ṣafihan igo ọti ọhun ti wọn kọ orukọ ipinlẹ ipinlẹ Ondo si lara pẹlu orukọ ti ọpọ eeyan mọ gomina ọhun si, iyẹn Aketi.
Akeredolu ni oun ko nilo lati kọ orukọ oun si ara igo ọti kankan ki awọn eeyan ipinlẹ Ondo to dibo fun oun ninu eto idibo sipo gomina to n bọ.
O ni "Awọn to ṣe iru nnkan bayii yii n fẹ ki awọn eeyan ro pe owo ipinlẹ Ondo ni a fi n po ọti"
- Ẹ wo bí Hushpuppi ṣe farahàn nílé ẹjọ́ l'Amẹrika fún ìgbà àkọ́kọ́ láti jẹ́jọ́
- Ìjọba Nàìjíríà ti mú Dókítà Anu tí àwọn kan f'ẹ̀sùn kàn pé ayédèrú iṣẹ́ abẹ ìdí ló n ṣe
- Erépá ní bàbá àti ìyá mi ṣe tí wọ́n fi bí mi, wọn kò fẹ́ra wọn- Funsho Adeolu
- Àjọ NCDC kéde ènìyàn 454 tó tún ṣẹ̀ṣẹ̀ ní Coronavirus ní Nàìjíríà
Atẹjade naa tẹsiwaju pe "Yatọ si eyi, a ṣi n reti ki awọn eeyan to wa nidi igo ọti naa ṣe awọn nnkan miran, ṣugbọn gomina ti gbe igbesẹ lati ṣawari awọn to wa nidi iṣẹlẹ ọhun."
Lẹyin naa lo ni ki awọn eeyan ma ṣe kọbi ara si fidio ọhun.
Ṣé lóòótọ́ ní pé ìyàwó Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ondo tí lugbadi Covid-19?

Oríṣun àwòrán, Twitter/RotimiAkeredolu
Bi iyawo Gomina Rotomi Akeredolu ba ni Covid-19, wọn yoo kede gẹgẹ bi ọkọ wọn naa se sọ faraye.
Esi ree ti agbẹnusọ Gomina ipinlẹ Ondo, Olusegun Ajiboye fọ nigba ti ileesẹ BBC Yoruba beere lọwọ rẹ pe, se lootọ ni arabinrin Betty Anyanwu iyawo Gomina Akeredolu ti lugbadi Covid-19.
Ajiboye sọ pe ''nigba ti Gomina Akeredolu lugbadi Covid-19, wọn kede fun ara wọn, ti iyawo wọn naa ba ni Coronavirus, ko si awo kankan nibẹ, wọn yoo kede rẹ.''

Oríṣun àwòrán, Twitter/RotimiAkeredolu
Lọjọbọ ni iroyin kan gbode pe, iyawo Gomina ti ko arun Covid -19, ti atẹjisẹ kan ti awọn eeyan n pin kaakiri si sọ pe, ki gbogbo awọn eeyan to kopa nibi eto ti iyawo Gomina se ni Idanre ati Odigbo, tara lọ se ayẹwo.
Ninu ahesọ ọrọ to gbode yii, ni wọn ti sọ pe awọn aṣofin mẹfa, ninu awọn to kọwọrin pẹlu Gomina Akeredolu lati lọ gba fọọmu idibo Gomina, ni wọn ti lugbadi Covid-19.
Lọjọbọ yii kan naa ni awọn agbẹnusọ fawọn asofin ti sọ fun BBC Yoruba pe, awọn yoo mọ boya awọn lugbadi Covid-19 laipẹ.
Amọ Olusegun Ajiboye ni iroyin naa ko ri bẹẹ rara.
Bẹẹ ba gbagbe, laipẹ yii Gomina Akeredolu kede ninu fọnran fidio kan pe, ohun ti lugbadi Covid-19.
O ni ohun ko foju apẹrẹ arun naa han ṣugbọn ohun ti bẹrẹ iyasọtọ ati itọju.
Yatọ si Akeredolu, Gomina Ifeanyi Okowa ipinlẹ Delta atiiyawo rẹ naa kede pe awọn lugbadi arun yi.
Kọmisana feto ilera nipinlẹ Ondo naa, Dokita Wahab Adegbenro la tun gbọ pe o ṣalaisi si ibudo ti wọn ti n tọju awọn alarun Coronavirus nilu Akure.

Oríṣun àwòrán, Akeredolu Twitter
Ọjọ́bọ̀ la ó mọ̀ bóyá a ní Coronavirus - Aṣòfin Ondo
Agbẹnusọ awọn asofin nipinlẹ Ondo, Gbenga Omole lo fi idi ọrọ naa mulẹ fun BBC Yoruba.
Omole ni awọn asofin ogun to tẹlẹ Gomina Akeredolu naa ni yoo lọ ṣe ayẹwo fun aarun Coronavirus ni Ọjọ Keji, Osu Keje, ọdun 2020.
Bakan naa ni agbẹnusọ awọn asofin nipinlẹ Ondo naa ni oun ko ya ara oun sọtọ nitori pe oun ko ni arun Coronavirus.
'Kilo de ti ma a fi ya ara mii sọtọ nigba ti mi o ni arun Coronavirus?'

Oríṣun àwòrán, Twitter
Ọgbọnjọ, Oṣu Kẹfa ni Gomina ipinlẹ Ondo kede pe oun ti ko arun Coronavirus, ti oun si ti ya ara oun sọtọ.

Oríṣun àwòrán, Twitter
Amọ, iroyin fi lede wi pe ọpọlọpọ awọn eniyan ni Gomina Akeredolu ti farakan to fi mọ Aarẹ Buhari, awọn lọbalọba ati awọn aṣofin naa.

Oríṣun àwòrán, Twitter
Awọn asofin to ba Gomina ipinlẹ Ondo, Oluwarotimi Akeredolu lọ si Abuja lati lọ gba sabuke lati dije dupo ninu idibo abẹlẹ saaju idibo sipo gomina ni ipinlẹ Ondo.

Oríṣun àwòrán, Twitter
Mo ti lùgbàdì àrùn Coronavirus - Akeredolu figbe ta
Gomina Rotimi Akeredolu ti ipinlẹ Ondo ti kede pe oun ti ni arun Coronavirus.

Oríṣun àwòrán, Rotimi Akeredolu Aketi facebook
Gomina Akeredolu ẹni to kede bẹẹ loju opo Facebook rẹ ninu fidio kan to fisita nibẹ fikun pe laarọ ọjọ Isẹgun ni oun gba esi ayẹwo oun.
Gomina ipinlẹ Ondo ni apẹẹrẹ ami Covid-19 na ko jẹ jade lara oun, ti oun ko si saisan lati fihan pe oun ni arun naa.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Arúfin ni Seyi Makinde pẹ̀lú bó ṣe gbà kí wọ́n sin Ajimobi sí GRA - Amòfin
- Ṣé ó leè jẹ́ ilẹ̀ tí Makinde kò jẹ́ kí Florence Ajimobi gbà ló ń bi nínú?
- Akinyele tún gbàlejò àwọn mùjẹ̀mùjẹ̀, tìyá-tọmọ̀ fara gbọgbẹ́
- Ẹ pèsè ẹlẹ́rìí púpọ̀ bí bẹ́ẹ̀ kọ́, Sotitobire yóò jẹ́rìí fúnrarẹ̀ o! - Ilé ẹjọ́ ìpínlẹ̀ Ondo
- Ilé ìwòsàn kan rèé tó ń fi àtùpà gbẹ̀bí aláboyún
O wa kede pe oun ti ya ara oun sọtọ bayii fun itọju, ti awọn osisẹ eleto ilera fun arun Coronavirus yoo si maa tọju oun nile.
Akeredolu wa rọ gbogbo eeyan lati ri daju pe wọn wa ni alaafia, ki ara wọn si da.
Bẹẹ ba gbagbe, ọsẹ meji sẹyin ree ti gomina Akeredolu lọ silu Abuja lati lọ kede pe oun fẹ dije fun saa keji lori aleefa, ọpọ eeyan si lo di mọ lati ya aworan.















