Colonial vestiges: Bourdilloun, Victoria Island, Lugard Avenue wà lára àdúgbò tí yóò pa orúkọ dà

Oríṣun àwòrán, Other
Ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Eko ke pe Gomina Babajide Sanwo-Olu lati ṣe agbeyẹwo ofin ọdun 2015 to nii ṣe pẹlu orukọ ọna ati agbegbe ni ipinlẹ Eko.
Eyi waye pẹlu erongba lati ṣe ayipada awọn orukọ to nii ṣe pẹlu owo-ẹru ati ikonilẹru laye awọn amunisin.
Igbakeji olori ẹgbẹ oṣelu to pọju nile, Ọgbẹni Noheem Adams lo mu aba naa wa fun gbogbo ile.
Nigba ti o da aba ọhun, aṣofin Adams ranti bi ọlọpaa alawọ funfun kan, Derek Chauvin ṣe pa George Floyd, alawọ dudu to jẹ ọmọ ilẹ Amẹrika.
Wọnyi ni awọn agbegbe ti ijọba oyinbo amunilẹru sọ niluu Eko ati orisun wọn:
Opopona Lugard:
Bi o tilẹ jẹ wi pe ọpọ orukọ agbegbe ati opopona ni ayipada ti ba, ṣugbọn orukọ opopona Lugard ni Ikoyi niluu Eko ko yipada di oni.
Oyinbo ọmọ ilẹ Gẹẹsi, Ọgbẹni Lord Lugard to da apa guusu ati ariwa orilẹ-ede Naijiria papapọ lọdun 1914.
Oun ni Gomina apaṣẹ-waa akọkọ ti o ṣe ijọba orilẹ-ede Naijiria.
Ile kan lo wa ni opopona ọhun ti wọn n pe ni ile Lugard ti o fi di oni niluu Eko.

Oríṣun àwòrán, Other
Opopona Kingsway:
Opopona Kingsway wa laarin gbungbun agbegbe Ikoyi, ọna ọhun lo da Ikoyi si meji.
Agbegbe yii ni awọn oyinbo nikan fi ṣe ibugbe ni Ikoyi laye ijọba amunilẹru ni Naijiria.
Lasiko Gomina Egerton ni ijọba ṣe opopona ọhun niluu Eko.
Ṣugbọn orukọ agbegbe naa ti yi pada bayii si opopona Alfred Rewane.
Wọn yi orukọ opopona ọhun pada ni bi ọgbọn sẹyin din diẹ lẹyin ọpọ rukerudo to ṣẹlẹ lagbo oṣelu ni Naijiria.

Oríṣun àwòrán, Other
Opopona Bourdillon:
Orukọ Gomina apaṣẹ waa, Sir Bernard Henry Bourdillon ni wọn fi sọ ori opopona yii ni Ikoyi.
Ni ọdun 1935 ni Sir Bourdillon di Gomina apaṣẹ waa ni orilẹ-ede Naijiria, o si di ipo naa mu titi di ọdun 1943 ti o fẹyinti ni ipo naa.
Oponopa Bourdillon jẹ opopona gbajugbaja niluu Eko, koda nibẹ ni ile ogbontarigi oloṣelu ti o tun jẹ eekan ninu ẹgbẹ oṣelu APC, Bola Tinubu kọ ile si.

Oríṣun àwòrán, Other
Victoria Island:
Agbegbe awọn ti Eleduwa fi owo jinki ni Victoria Island jẹ nipinlẹ Eko.
Nibẹ si ni oriṣiiriṣii ileeṣẹ ati awọn ọfiisi pọ si niluu Eko.
Agbegbe Victoria Island wa leti alagbalugbu omi okun, eyi to tun mu un rẹwa sii.
Ọbabinrin ilẹ Gẹẹsi, Victoria to jọba ilu oyinbo laarin ọdun 1837 si 1901 ni wọn fi orukọ rẹ sọ Victoria Island.

Oríṣun àwòrán, Other
Race Course:
Race Course ti o ti di Tafawa Balewa Square bayii jẹ papa ti Oba Dosunmu fun awọn oyinbo to ni ijọba akonilẹru ni Naijiria lọdun 1859.
Ibẹ ni wọn maa n lo fun oriṣiiriṣii ere idaraya laye igba naa.

Oríṣun àwòrán, Other
Ọgagun Yakubu Gowon to jẹ olori orilẹ-ede Naijiria lati ọdun 1966 si ọdun 1975 lo paṣẹ pe ki wọn wo o palẹ.
Lẹyin naa ni ijọba Naijiria yi orukọ rẹ pada si Tafawa Balewa Square.
Ibẹ ni wọn lo fun ayẹyẹ ominira Niajiria lọdun 1960.
- Ẹ dá àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò igbákejì gómìnà ìpínlẹ̀ Ondo padà ní kíá - ọ̀gá àgbà iléeṣẹ́ ọlọ́pàá
- Ibi ọ̀rọ̀ dé dúró lórí ṣíṣí àwọn ilé ìwé padà ní Naijira rèé àti nílẹ̀ Afrika
- Ọjọ́ Kẹ̀jọ, oṣù yíì ní ìrìnà ọkọ́ òfúrufú yóò bẹ̀rẹ̀ padà ní Naijiria
- Ẹ̀kọ́ mẹ́jọ tó yẹ kí ilẹ̀ Afirika kọ́ lára àjàkálẹ̀ aàrùn coronavirus













