Coronavirus in South Africa: Ẹ̀kọ́ mẹ́jọ tó yẹ kí ilẹ̀ Afirika kọ́ lára àjàkálẹ̀ ààrùn coronavirus

Left: Doctor in a mask in South Africa. Top right: Someone drinking a cup of tea in South Africa. Bottom right: Two women walking in South Africa

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Se awọn agba bọ wọn ni ẹṣin iwaju ni tẹyin n wo sare.

Gẹgẹ bi orilẹ-ede South Africa ṣe ń lewaju loriṣiriṣi ọna nilẹ Afirika bẹẹ si ni lọwọlọwọ, wọn tun ti ṣe tan lati dari Afirika lọ si ipele to lewu lasiko Coronavirus yii ọna igbogunti Covid 19 ti wọn gunle.

Eyi lawọn koko ẹkọ mẹjọ pataki to lee kọ awọn orilẹ-ede Afirika:

1.Ẹ tọju iyara ijẹun ninu awon ile iwosan ko mọ toni toni.

Ibi to lewu ju nileewosan ni yara ijẹun.

Ni South Africa, ọpọ ile iwosan ni wọn ti fi dandan ti pa tori pe o ti di ibi ijẹsi fun aisan Covid19.

Ọpọ dokita lo n fa awọn oṣiṣẹ ile iwosan leti pe ki wọn ye korajọ mọ ninu yara ijẹun.

Nibẹ, wọn a yọ ibomu-boju wọn silẹ, wọn a maa parọ foonu, wọn a ti gbagbe iṣẹ ti wọn n ṣe ninu wọọdu.

2.Kikanju ṣe ayẹwo - tabi aiṣe e rara lẹyin ileri lati ṣe e.

Lọwọ lọwọ, ofo ni South Africa n mu ninu ṣiṣe ayẹwo o si ti pọwọ lera wọn gan an ni gẹgẹ bi awọn akoroyin ṣe sọ

Won ni eyi si ti ba iwulo gbogbo ilana ti wọn n gba ṣe ayẹwo jẹ tori igbe aisowo ti ijọba n pa.

Se lawọn dokita ni afi dandan ki wọn maa gbe esi ayẹwo jade laarin wakati mẹrinlelogun.

Eyi lee mu ki aisan naa ti rin jina ni titankale mọ awọn mii ti wọn ko le tọpasẹ rẹ tabi ko ti kọja afẹnusọ lara wọn.

Nibayii, Coronavirus ti ran kọja aala ohun tawọn oṣiṣẹ ilera lee kapa ni South Africa.

4.Sisanra ju ati aisan ẹjẹ riru naa ti n ṣakoba

Iwadii kaakiri awọn ileewosan South Africa di han pe ara sisan ju to fi mọ ẹjẹ riru ati itọ ṣuga lara awọn ọdọ to ni arun Coronavirus ni i ṣe pọlu ọpọ to gba ibẹ ku.

Ọpọ ọdọ South Africa to ni aisan ni ko ṣe ayẹwo ohun to n ṣe wọn pato.

Obinrin meji n rin ni South Africa

Oríṣun àwòrán, Getty Images

5.Sisunmọ ibi ti alaisan Covid 19 wa ko tumọ si ohun tawọn eeyan n ro nigba mii.

Fun apẹẹrẹ, ileewosan fun awọn aboyun kan ni Johannesburg di titi pa tori iroyin pe wọn ni oṣiṣẹ wọn kan lọ sunmọ alaisan Coronavirus.

Se ni wọn ran nọọsi mejila lọ sile ki wọn lọ ya ara wọn sọtọ.

Awọn dokita kan bu ẹnu atẹ lu igbesẹ yii pe ibẹru ti koi to lo n ko wọn laya soke nitori naa ilanilọyẹ kikun ṣe pataki nipa ohun to n jẹ sisunmọ alaisan.

6. O ti n ni owo kan oloselu ninu

Awon kan ni pe esu mo si ohun to n sele

Laipe yii ni ijọba South Africa kede pe awọn ile ijọsin lee bẹrẹ isin pada ṣugbọn ki wọn ma ju aadọta lọ.

Igbesẹ yii jẹ imọ awọn oloṣelu kan tara n ta lati dẹ okun isede to wa tẹlẹ.

Awọn oṣiṣẹ eleto ilera ni South Africa

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Hmmmmn, igbesẹ yii ẹwẹ gbe ewu ru sori pupọ nitori pe awọn arugbo ni yoo pọ ju awọn si lo wa ni bebe kiko arun yii ju.

Bi wọn ba wa yan lati pa koko yii ti, o lewu.

Awọn kan tilẹ ni ko yẹ ki ijọba gba awọn to ba ti le ni ọdun marunlelọgọta laaye lati lọ jọsin.

Ṣugbọn ibeere ni pe ṣe wọn yoo gbọ?

6.Ọrọ Covid 19 ti n mu ọwọ kan oṣelu da ni ni South Africa

Ẹgbẹ oṣelu alatako ni South Africa, Democratic Alliance (DA) ti n lo anfani yii lati fa oju awọn araalu mọra lasiko yii nitori naa wọn n kẹnu bọ ọrọ awọn alakalẹ ti ijọba gbe silẹ gẹgẹ bi ofin.

Awuyewuye yii laarin awọn oloṣelu ṣeeṣe ko ta ba ọrọ aje orilẹ-ede naa.

Awọn obinrin meji n mu tii ni South Africa

Oríṣun àwòrán, Getty Images

7.Nibo ni ọrọ ofin ọti mimu ati tita de duro?

Nigba ti South Africa fofin de ọti mimu lasiko isede ti wọn paṣẹ, ọpọ lo ri i bi eyi to le ṣugbọn wọn gba a mọra gẹgẹ bi ọna to tọ lati dinwọ iwa ipa ninu ile ku.

O tun je ki wọn si lee da awọn ibusun ile iwosan si fawọn alaisan Coronavirus nikan.

Ẹwẹ nibayii isede ti su awọn eeyan wọn si ti dẹ okun "ma muti" diẹ.

Ọpọ eeyan kọ lati gbagbọ ninu aridaju imọ sayẹnsi ti ijọba fi n ṣẹlẹri gbogbo ohun ti wọn n sọ nitori naa wọn n sọ pe ọna ati kowo jẹ ni awọn oṣiṣẹ ijọba n lo.

Bakan naa ni isede ọhun tun faaye gba awọn ọdaran to n ko siga wọle labẹlẹ nitori awọn to n mu u koro oju si ofin "ma u siga".

Ọdọkunrin ni South Africa

Oríṣun àwòrán, Getty Images

8.Ẹ ṣe e ni soki lọbẹ oge laarin ọsẹ melo kan.

Iriri awọn dokita kan ni Capetown ti fihan pe awọn irinṣẹ kan wa to jẹ olowo pọọku ti yoo si ṣiṣẹ daradara ju awọn fẹntiletọ jaanran ti awọn alaṣẹ ni ki wọn maa rọ owo ra.

Ọjọgbọn Madhi tẹnumọ ọ pe o ti to ọsẹ mẹfa ti oun ti n sọ pe o yẹ ki wọn ra awọn ohun eelo eemi ṣugbọn pabo lo ja si.

O ni aba yii kan naa lo yẹ fun gbigba oṣiṣẹ eleto ilera eyi to mu ki awọn dokita gba ijọba nimọran pe ki wọn gba awọn akẹkọọ dokita tabi awọn to ti fẹyin ti ju ki wọn lọ maa ko awọn dokita ilẹ okeere wa ati orilẹede bii Cuba.