Olu Jacobs: Àwọn gbajúmọ̀ òṣèré márùn-ún tí wọn ti pa irọ́ ikú mọ́ sẹ́yìn rèé

Amuludun

Oríṣun àwòrán, Others

Ọwọ kekere kọ ni Yoruba fi n mu aṣa ki wọn pa irọ iku mọ ẹnikan nigba to wa laaye, nitori ẹnikan kii gbọ ọjọ iku rẹ ko dunnu.

Amọ bi iwa naa ṣe jẹ eewọ laarin iran Yoruba, n ṣe lo n gogo si lasiko yii, paapaa lori ẹrọ itakun agbaye.Ikede iku awọn alaaye yii si lo wọpọ laarin awọn amuluudun, gbajumọ ati awọn eekan ilu lorisirisi, to fi mọ awọn oloselu, oloko-owo, akọrin atawọn oṣere tiata.

BBC Yoruba wa ṣe akojọpọ diẹ lara awọn eniyan to ti fara gba iru iṣẹlẹ yii laarin awọn ọmọ Yoruba, ẹ wo o:

Awọn gbajumọ ti wọn kede iku wọn nigba ti wọn wa laaye:

Ayinla Kollington

Ayinla Kolington

Oríṣun àwòrán, Others

Nigba kan ni ariwo gba ilẹ kan pe, Kebe n Kwara, Alhaji Ayinla Kollington ti dagbere faye, amọ aṣẹyinwa aṣẹyinbọ, irọ lo jasi, to si gbe awo orin tuntun jade lori rẹ.

Babatunde Omidina (Baba Suwe)

Baba Suwe

Oríṣun àwòrán, Others

Baba Suwe ṣe aisan to le diẹ, eyi to mu ki awọn eeyan kan maa ro iku roo nigba to si wa ni ààyè, sugbọn iroyin iku gbajumọ oṣere tiata naa ko tii rin jinna, toun gan-an fi pariwo sita pe alaaye ni oun, oun kii ṣe oku.

Gbolagade Majekodunmi (Ogun Majek) :

Ogun Majek

Oríṣun àwòrán, Others

Laipẹ yii ni ariwo ta pe gbajugbaja oṣere tiata kan lede Yoruba, Ogun Majek, ti ọpọ eeyan gbọ tẹlẹ pe o n ṣe aisan, ti jade laye.

Gbajumọ oṣere binrin kan, Foluke Daramola si lo tete ke gbajare sita pe irọ nla ni pe Majek ku, nitori baba naa wa laaye bi o tilẹ jẹ pe o n ṣe aarẹ.

Femi Dosumu (Mega 99) :

Mega 99

Oríṣun àwòrán, Others

Gbajumọ olorin juju ni Mega 99,ti aye si n gbadun rẹ ni ojoojumọ amọ iyalẹnu lo jẹ nigba ti awọn eeyan kan tu ọfọ rẹ lojiji, amọ to jẹ pe irọ lo wa nidii ọrọ naa.

Olu Jacobs:

Olu Jacobs

Oríṣun àwòrán, Others

Ọrọ iku Olu Jacobs lo gba ilẹ kan bayii ti awọn eeyan n gbe kiri loju opo ayelujara amọ to jẹ pe irọ nla to jinna sootọ ni nitori aya rẹ, Joke Jacobs ti kede faraye pe ko ko ko ni ara ọkọ oun le, ko ku rara.